Abba Kyari: Ṣé ó tọ́ bí ààrẹ Buhari ṣe fi ìlú lẹ̀ láì gbé ìjọba lè ẹnikẹni lọ́wọ́?

Oríṣun àwòrán, Twitter/MBuhari
Kìí ṣe ohun tuntun mọ pé aṣojú oṣìṣẹ́ nílé ìjọba apapọ Abba Kyari gbé àbádofin kan lọ bá ààrẹ láti búwọlu nibi to ti lọ fún isinmi ni London.
Ṣùgbọ́n bi àwọn ọmọ Naijiria ṣe ri ọ̀rọ̀ yìí àti ojú ti wọ́n fi wò ó ni o gbòde kan báyìí ninu àpéro ti wọ́n ń ṣe lori ọ̀rọ̀ náà lori twitter.
Ọ̀pọ̀ lori ayelujara gbà pé ko tọ́nà láti ṣe eyí niwọ̀n ìgbà ti igbákeji ààrẹ Naijiria ọjọgbọ́n Yemi Osinbajo wà nílùú to si yẹ ki wọ́n gbé ìjọba silẹ̀ fún.
Agbẹjọro takò ìgbésẹ yí
Nígbà tí BBC Yoruba kàn sí agbẹjọro kàn tó fí ìlú Akure ṣé ibùjókòó, o sọ pé kò t'ọna bí ààrẹ Buhari ti ṣé fí Nàìjíríà sílẹ lọ sí ìlú London láì gbé àṣẹ ìjọba kalẹ fún igbákejì ààrẹ.
Morakinyo sọ pe Aarẹ Buhari kuna pẹlu bi ko ti ṣe fi iwe ranṣẹ si ile aṣofin Naijiria nipa irinajo rẹ.
O tẹsiwaju pe koda bi o ba tilẹ wa rinrin ajo lọ si ilẹ okere, abadofin to buwọlu kii ṣe fun awọn eeyan ilẹ miiran bi kii ṣe fun awọn ọmọorileede Naijiria.
''Ko si ipinya to yẹ laarin awọn ẹka ijọba ni Naijiria, eyi laa si n ri labẹ ijọba to wa lode yii''.
Kíní Abadofin náà jẹ ti Abba Kyari fi gbé bàálù lọ bá ààrẹ láti tọ́wọ́ bọ̀ọ́
Abadofin ọhun niṣe pẹ̀lú àwọn ǹkan to niṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wíwa epo Nàìjíríà (Offshoreand Basin Production Sharing Contract)Act
Ààrẹ Buhari lori àtẹjiṣẹ́ twitter rẹ̀ sàpejuwe títọwọ́bọ iwé abádofin náà bi igbésẹ to lààmi laaka fún orilẹ̀-èdè Naijiria
Abadófin náà yóò mú kí pínpín èrè owó epo rọrun láwọn ipin lẹ to ni kanga epo

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmed
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post














