ICPC: Kò fẹ́ẹ̀ sí adájọ́ tó gbọ́ ẹ̀hónú ìbò tí wọn kò fi rìbá lọ̀

Oríṣun àwòrán, Twitter
Iwadii Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ati iwa ibajẹ lawujọ, ICPC ti safihan bi awọn agbẹjọro ṣe fi biliọnu mẹsan ati miliọnu lọna irinwo naira (₦9.4bn) san riba fawọn adajọ laarin ọdun 2018 si ọdun 2020.
Iwadii naa fihan wi pe, iwa ibajẹ to wa ni ẹka eto idajọ to wa lorilẹede Naijiria gbinlẹ to bẹẹ to jẹ wi pe, ẹka naa kun fun iwa ibajẹ.
Ajọ ICPC ni o fẹrẹ ma si adajọ to gbọ ẹjọ to niiṣe pẹlu eto idibo tabi awọn oloṣẹlu ti wọn ko fi owo abẹtẹlẹ lọ, ki idajọ naa ba le lọ ni ọna ti yoo tẹ wọn lọrun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ igba tí Primate Ayodele gbé síta fọ́dún 2021
- Ìdí rèé tí ẹ̀mí mi kò fi bọ́ sínú ìdìtẹ̀ gbàjọba tó pa Muritala Muhammed - Obasanjo
- Wọ́n gún ọkùnrin kan lọ́bẹ pa torí ó tako yínyin báńgà sínú Mọ́ṣálásí
- Ìjọba kéde ọjọ́ tuntun fún ṣíṣí afárá Third Mainland Bridge
- Àwọn àṣà tó milẹ̀ lọ́dún 2020 pẹ̀lú ìtàn lórí bí wọ́n ṣe jáde
- Kò bá wù mí kí n padà sí àwọ̀ tí Ọlọ́run dá mi, wàhálà ni ara bíbó - Bobrisky
- Nàíjíríà yóò gbóná janjan lẹ́yìn ìbò ààrẹ 2023 àyàfi... - Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀
- N kò tíì pa ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tì, bí mo tilẹ̀ ti kúrò nílé ọkọ - Mercy Aigbe
Iwadii naa ti wọn pe akọle naa ni 'Nigeria Corruption Index: Report of a pilot survey 2020' fihan pe, awọn ẹka iṣowo aladani ni iwa ibajẹ wọn tun peleke si, lẹyin ẹka eto idajọ.
Ni ẹka idajọ, iwadii naa fihan wi pe, ida mẹsan ninu mẹwaa awọn agbẹjọro ti awọn fi ọrọ wa lẹnu wo, lo fidi rẹ mulẹ pe awọn san biliọnu marun un o din diẹ gẹgẹ bi riba fun awọn adajọ to n gbẹjọ ẹsun idibo awọn oloṣelu.
Bakan naa ni awọn adajọ mejidinlọgọrin ninu mọkanlelẹẹdẹgbẹrún ti ajọ ICPC ba sọrọ ni awọn agbẹjọro fi riba lọ awọn, lati fi jẹ ki idajọ lọ ni ọna ti wọn fẹ.
Ajọ ICPC fikun wi pe, iwadii awọn fihan pe awọn to n gba riba ni ẹka idajọ ko yọ awọn oṣiṣẹ ẹka eto idajọ silẹ, to fi mọ awọn adajọ ati awọn ti wọn fi ẹsun kan, to n fi riba lọ awọn adajọ.
Bakan naa ni iwadii naa ni ẹka idokowo aladani naa le ni ida aadọta ti wọn n kopa ninu iwa magomago ati jẹgudujẹra lorilẹede Naijiria.
Wọn ni ọpọlọpọ awọn ileeṣẹ aladani wọnyii ni wọn n gba awọn iṣẹ akanṣe fun araalu, ti wọn si n da owo si apo ara wọn.
Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ ijọba n san owo to yẹ fun ijọba si awọn apo iṣuna ileeṣẹ aladani, lati le lo o fun ifẹ ara wọn.
Iwadii ti Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ati iwa ibajẹ lawujọ, ICPC se ni diẹ ni ẹka aṣofin lorilẹede Naijiria fi yatọ si ẹka ijọba.
O ni ẹka asofin gba maaki mọkanlelogoji ninu ọgọrun fun iwa jẹgudujẹra, nigba ti ẹka iṣejọba gba maaki mejilelogoji ninu ọgọrun.


















