Int'l Anti-Corruption Day: Àwọn kan ní ìwà àjẹbánu ń peléke síi n'íjọba Buhari, àwọn míì ní Buhari ń gbìyànjú

Oríṣun àwòrán, Twitter/Presidency
Oni ni ọjọ Aje, ọjọ kẹsan an, oṣu kejila, ọdun 2019 to jẹ ayajọ igbogun ti iwa ibajẹ ati iwa ajẹbanu kaakiri agbaye.
Ọkan gboogi lara ileri ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe nigba to wọle ipo aarẹ fun saa akọkọ lọdun 2015 ni pe oun yoo gbogun tiwa ajẹbanu ati iwa ibajẹ lorilẹ-ede Naijiria.
Koda, Aarẹ Buhari ṣeleri lati fi ile ẹjọ ti yoo maa ri si ẹjọ iwa ibajẹ ati ajẹbanu nikan silẹ.
Eyi ni agbeyẹwo bi ijọba Aarẹ Buhari ṣe sọ pe wọn ti gbogunti iwa ibajẹ lati ọdun 2015 to ti dori aleefa gẹgẹ bi aarẹ orilẹ-ede Naijiria.
Gomina mẹta ọtọọtọ lo ti dero ẹwọn lori ẹsun ṣiṣe owo ilu kumọkumọ lawọn ipinlẹ ti wọn ti ṣejọba.

Diẹ lara Aṣeyori ijọba Buhari lori gbigbogun ti iwa ajẹbanu:
1. Joshua Dariye (PDP) Gomina 1999-2007
Ní inú oṣù kọkanlá, ọdun 2018 ní ilé ẹjọ to ga julọ wọ́n ẹ̀wọn ọdun mejila lẹ́yin to jẹ̀bi ẹ̀sun oníkókó mẹtadinlọ́gbọ̀n ti wọ́n si ni ko lọ ẹwọn ọdun mẹ́rìnla.
Joshua jẹ gomina ìpínlẹ̀ Plateau láti ọdun 1999 si ọdun 2007 to si tun di sẹnatọ tó ń sojú ẹkun aarin gbùngbùn Plateau kí ilé ẹjoọ to dájọ pe ó jẹ̀bi ẹsùn ti àjọ EFCC fi kan an.
Ẹsùn àkọkọ ní pé ó dá ìgbékẹ̀lé ti ará ìlú ni síi ti o si yẹ ko lọ si ẹwọn ọdun mẹwàá nígba ti ẹsún keji ni i ṣe pẹ̀lú owó kọngila fún atunse ayika to jẹ mílíọnu kan lé ọwọ mẹfa (1.162bilion), eyi ni ẹwọn ọdun meji, sùgbọ́n mejeeji le lọ pọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.
Ẹ̀wẹ̀, ilé ẹjọ́ kòtẹmilọrun ni Ẹwọn ọdun mẹwàá ni o tọ si i fún ẹsun
2. Jolly Iyame (PDP) Gomina 1999-2007
Ní ti Jolly Iyame ni tirẹ, ajọ EFCC gbe e lọ si ilé ẹjọ ninu oṣù karun un, ọdun 2018 lori ẹsun oni koko mọkanlélógójì fun dídari owo ilú to to bílíọnù kan ati ọwọ́ mẹ́fa (1.64bilion Naira) si akoto míràn láàrin ọdun mẹ́rin to fi jẹ gómínà.
Wọ́n ran an lọ si ẹwọn ọdun mẹrinla lẹ̀yìn ti àwọn adájọ ẹlẹni mẹta èyi ti adajọ Abdul Aboki, pàdà wá dín ìdájọ rẹ̀ kù sí ọdun mejila.
Lẹ̀yìn èyí ni wọ́n ni ki Iyame san ẹẹdẹ́gbẹ̀ta din diẹ̀ mílíọnu naira gẹ́gẹ́ bi owó ìtanran bo tilẹ jẹ́ pé ẹ̀wọ́n ọdun mẹrinla ni wọ́n kọ́kọ́ ni ki ó lọ.
Jolly Iyame jẹ gomina ìpínlẹ̀ Taraba láti ọdun 1999 si ọdun 2007.
3. Orji Uzor Kalu (APC) Gominna 1999-2007
Ní ọsẹ to kọja yìí ni ilé ẹjọ pàda ṣedájọ Orji Kalu lori ẹsun ìkowó jẹ ti wọ́n ti EFCC fi kan-an.
Gomina ìpínlẹ̀ Abia tẹlẹ̀ ri ni ilé ẹjọ ni ko lọ fi ẹ̀wọ́n ọdun mẹjila jura nibi ìdájọ ti Justice Mohmmmed Idris dari.
Ilé Iṣẹ Slok ni wọ́n fẹ̀sun kan pe ò n lò lati ko òwó àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Abia ti wọ́n ti gba lọwọ ìjọba apapọ
Bakan náà ni wọ́n ko olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, Jones Ude ti wọ́n jo ń lu owó ìlú ní pònpò to si duro bi alabojuto owó lati lọ sẹ́wọ̀n ọdun marun un.
Kalu lú owo ilú to lé ni bílíọnu meje naira (7.2bilion) ni ponpo.
Amọ, awọn ẹjọ iwa ajẹbanu ohun iṣowo ilu kumọkumọ kan wa ti ọpọ gbagọ pe ijọba Buhari ko ri ohun kankan ṣe si wọn.
Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje
Ọpọ fẹsun kan ijọba Buhari pe ko gbe igbesẹ akin lori ọrọ Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje lẹyin ti oriṣiiriṣii fidio ṣafihan bi o ṣe n gba riba lọwọ kọngila lu sita layelujara.
Gomina Ganduje loun ko jẹbi ẹsun iwa ajẹbanu, o ni awọn alatako oun fẹ fi fidio naa ba oun lorukọ jẹ ni.
Aarẹ Buhari sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan Ganduje pe, ko mọwọ, ko mẹsẹ ayafi ti ẹri to daju ba wa loku.
Godswill Akpabio
Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati iwa ajẹbanu, EFCC n ṣawidii lori Gomina ipinlẹ Akwa Ibom tẹlẹ ri, Godswill Akpabio lori ẹṣun pe o dari ọgọrun un biliọnu naira to jẹ owo ipinlẹ naa sapo ara rẹ.
Ṣugbọn Aarẹ Buhari kan lo kii kaabọ sinu ẹgbẹ oṣelu APC funra rẹ, koda, Akpabio wa lara awọn minisita ti Buhari yan sipo nigba to wọle saa keji.
Rotimi Amaechi
Mnisita igbokegbodo ọkọ ni Naijiria bayii, Rotimi Amaechi to jẹ Gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ ri ni oludari ipolongo ibo fun Aarẹ Buhari nigba to dije fun ipo aarẹ fun saa keji.
Ẹka idajọ ti gbe igbimọ kan dide ti Adajọ George Omeregi jẹ olori wọn lati ṣewadi Amaechi lori ẹsun pe o ṣe owo ipinlẹ naa to to naira mẹtadinlọgọrun un biliọnu kumọkumọ.
Amọ, ẹsun naa ko di Buhari lọwọ lati jẹ ki Amaechi tẹsiwaju gẹgẹ bi minisita.
Ero awọn eeyan ṣọọtọọ loju opo Facebook BBC News Yoruba lori agbeyẹwo igbogun ti iwa ajẹbanu ti ijọba Buhari gunle.
Ọpọ lo ni Aarẹ Buhari n gbiyanju lati gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria ṣugbọn omi lo pọ ju ọka lọ.

Ṣugbọn awọn eeyan bi Oludare Paul, Saruni Sola gbagbọ pe Buhari n ṣegbe lẹyin awọn eeyan kan ninu eto igbogun ti iwa ajẹbanu to n ṣe.
Awọn kan tiẹ ni o yẹ ki Buhari ti ṣewadi asiwaju Bola Tinubu, Adams Oshiomole atawọn eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn ti ṣe ijọba sẹyin.

Oríṣun àwòrán, Joshua Adetunji
Bakan naa lawọn eeyan kan gbagbọ pe igba ajẹbanu n buru si ni lati igba ti Buhari ti gori aleefa gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria lọdun 2015.
Wọn ni ko si ayipada rere kankan to ṣee tọka si ninu eto igbogun ti iwa ibajẹ ti ijọba Aarẹ Buhari ti gun le lati ọdun mẹrin sẹyin.
















