Transparency International: Ipò 144 ní Nàíjíríà wà nínú orílẹ̀èdè 180 tí wọ́n ṣe ìwádìí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @anticorruption
Ijọba apapọ ti bu ẹnu atẹ lu abọ iwadi ajọ to n tanna wadi bi iwa ajẹbanu se rẹsẹ walẹ si lagbaye, ti wọn n pe ni Transparency International (TI), to si ni ofo, ọjọ keji ọja ni esi to gbe sita nipà orilẹede Naijiria.
Ni aarọ ọjọbọ ni ajọ TI abọ iwadi rẹ sita nilu Abuja, to si kede pe orilẹede Naijiria tun ti ja walẹ pẹlu ipele meji, ninu iwadi to se lori bi Naijiria se n gbogun tiwa ibajẹ si lọdun to kọja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ó kéré tán ọkùnrin 15 ló ń bámi lòpọ̀ lójúmọ́, mo sì ti ní egbò lójú ara - Adeola tí wọn fi sòwò ẹrú
- Ìbọn kọ́ ni wọn fi pa èèkàn ẹgbẹ́ APC n‘Ibadan, ọ̀bẹ ni wọ́n fi gé iṣan ọrùn, ọrùn ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ - Ọlọ́pàá
- Mo dúpẹ́ pé Ọlọ́run dá mi láre lórí ikú Sugar, tí adájọ́ sì tú mi silẹ̀ - Akinmoyede
- Ìṣọ̀rí Amotekun ta pè ní ‘Irúnmọlẹ̀’ ní yóò máa gun ọ̀kadà kiri láti pèsè ààbò - Àjọ Dawn
Naijiria lo gbe ipo kẹrinlelogoje laarin awọn ọgọsan orilẹede ti wọn se iwadi le lori.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ TI ni bi ilana ofin Naijiria se n se ojusaaju nidi awọn eeyan to n lo ida ofin le lori nipa iwa ijẹkujẹ, lo mu ko ja walẹ lori akaba iwa ijẹkujẹ, to si jẹ pe awọn mẹkunnu lo n jiya iwa ajẹbanu, tawọn olowo si n rọna yọ.
Nigba to n fesi lori ọrọ naa, agbẹjọro agba ati Minisita feto idajọ, Abubakar Malami ni ko si ẹri to daju ti ajọ TI fi gbe ara rẹ lẹsẹ lori esi to gbe jade naa.
- Yaba Left: Àṣírí tú! #7000 sí #10000 ni owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún bẹẹdi ní ilé àwọn aláìsàn ọpọlọ
- Àwọn agbébọn pa olóyè ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Oyo sínu ilé
- Ibà Lassa bàlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Enugu! Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ ọṣẹ́, Ẹ̀mí kan ti nù
- 'Danfo', 'Okada', 'K-leg' àtàwọn ọ̀rọ̀ Nàìjíríà ti wọ́n fi kún Oxford Dictionary lọ́dun 2020
"Ta ba ni ka sọrọ nipa gbigbogun ti iwa ibajẹ, a ti n se ju ti atẹyinwa lọ, ta si tun setan lati se ju bẹẹ lọ yatọ si ohun ti ajọ TI gbe jade. Bẹẹ si ni ko si ohun ti orilẹede yii ko tii se lati sẹ eegun ẹyin iwa ajẹbanu lorilẹede yii"









