Lagos COVID-19: Ará òkè òkun tó ń wọlé sí Nàíjíríà, Ẹ ṣọ́ra fún gbígba ayédèrú ìwé ẹ̀rí àyẹ̀wò COVID-19

Gomina Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, twitter/Akin abayomi

Ijọba ipinlẹ Eko ti pariwo sita pe awọn eeyan kan ti n ta ayederu iwe ẹri ayẹwo Coronavirus ni ipinlẹ naa.

Kọmiṣọna feto ilera, Ọjọgbọn Akin Abayọmi ṣalaye pe ọpọlọpọ awọn arinrinajo wọle lati oke okun lo jẹ pe iwe ẹri ayẹwo COVID-19 ti wọn n gbe kiri kii ṣe ojulowo.

O ni ijọba ipinlẹ Eko ti n gbe igbesẹ lati rii daju pe ọwọ tẹ awọn eeyan to wa nidi iwa ibajẹ naa.

Àkọlé fídíò, Jude Chukwuka: Wò ó bí òwé Yorùbá ṣe yọ̀ lẹ́nu ọmọ Igbo

Ọjọgbọn Abayọmi ni ọpọ awọn to n wọle lati ilẹ okeere lo ni ajakalẹ aarun naa, bẹẹ ni iye awọn to nii laarin wọn n pọ si ni.

O ni laipẹ ijọba yoo fi panpẹ ofin ko gbogbo awọn to n ra tabi ta ayederu iwe ẹri ayẹwo COVID-19 naa.