Update on UK Visa: Ohun tóo ní láti ṣé rèé láti jẹ anfààní gbígba ìwé ìrinà Visa

Eto gbigba iwe irina UK

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn alaṣẹ eto gibigba iwe irinna nilẹ Gẹẹsi ti bẹrẹ eto pada fawọn arinrinajo lati orileede ti wọn ti ṣaaju wọgile nitori ẹda arun Covid-19, Omicron.

Eleyi n waye lẹyin ọjọ keji ọjọ ti ilẹ Gẹẹsi sọ pe ko si idiwọ kankan fawọn to ba fẹ wa silẹ wọn.

Aṣoju orilẹede Gẹẹsi ni Naijiria l'Abuja lo fi atẹjade sita pe ẹka to n ṣeto iwe irina yoo kan si awọn to ti kọwe irina ni kete ti paali irina wọn ba delẹ.

Wọn si fi ikilọ sita pe ki ẹnikankan ma ṣe wa si ileeṣẹ awọn bi wọn ko ba ni ko wa sibẹ.

Atẹjade naa sọ pe idi tọrọ fi ri bẹẹ ni pe iwe irina ojulowo a maa gba asiko diẹ ki wọn to ṣee tan.

Bẹẹ ni wọn sọ pe awọn gbiyanju lati ṣeto iwe irina awọn ti kii ṣe alabẹwo bi ti awọn akẹkọọ ati awọn to ba fẹ lọ ṣiṣẹ.

Eto gbigba iwe irina UK

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọjọ Karun un oṣu Kejila ni ilẹ Gẹẹsi dawọ ṣiṣe eto iwe irina fun gbogbo awọn orileede ti gbegi dina wọn to fi mọ Naijiria titi ti igbesẹ yi fi yi pada.

Iwe irina taa n sọ yi kan gbogbo awọn eeyan to ba fẹ lọ si ilẹ Gẹẹsi fun:

  • Inaju
  • Ṣiṣe abẹwo si mọlẹbi ati ọrẹ
  • Lilọ sibẹ latilọkopa ninu ipade ọlọjọ diẹ
  • Lilọ lati lọ fun eto ẹkọ ti ko pẹ pupọ bi eyi ti ko kọja oṣu mẹfaa
  • Kikopa ninu eto iwadii tabi eto ẹkọ paṣiparọ
  • Fun idi to ni ṣe pẹlui ilera boya eeyan fẹ lọ gba itọju nibẹ

Iwe irina Visa UK ati ilana tuntun

Eto gbigba iwe irina UK

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • O ko ni lati forukọ silẹ fun ririnajo kankan ki o to le kọwe gbigba Visa tabi ki wọn to gbe igbesẹ lori Visa rẹ
  • Awọn to ba nilati l si ilẹ Gẹẹsi nitori iṣẹlẹ to ṣe pataki ko ni lati gba ọna ẹburu kankan.
  • Awọn to ba fẹ gba Visa ni lati sọ idi ti wọn fi n wa fawọn eleto paapa lasiko ti wọn ba n tẹ ika fun wọn pẹlu ẹrọ kọmputa taa m si biometrics
  • Boo ba ti fi Visa arinrinajo rẹ kalẹ to si ni lati l si il Gẹẹsni ni kiakia o le kan si ọfisi eleto Visa ati ileeṣẹ to n ri si iwọlewọde fun eyikeyi iranwọ to ba nilo.
  • Awọn akẹkọọ to ba fẹ lo Visa Priority Visa le ba ile ẹkọ wọn sọrọ nipa anfaani ti wọn le jẹ to fi mọ eleyi to wa labẹ arun Covid-19
Aworan eleto iwe irina

Oríṣun àwòrán, PA Media

Visa UK ati ileeṣẹ to n ri si wọlewọde,iyipada to de ba eto wọn

Saaju asiko yi, o maa n to ọgbọnjọ lati fi ṣetogbigba Visa ilẹ Gẹẹsi ni Naijiria.

Koda wọn a maa bẹrẹ eto rẹ lati oṣu mẹta sẹyin ko ba le ya.

Ilana gbigba Visa naa a maa gba eeyan to ọjọ mẹrin si mẹfaa

Amọ awọn eto Visa kan le gba eeyan to ọgbọn ọjọ ti awn iwe kan ko ba si nilẹ tabi ti wn ba ni lati ṣe ayẹwo finifini to ba ṣe pe ẹni naa lẹbọ lẹru tabi ti wn ko ba ti fun ni Visa nigba kan ri.