Lagos-Ibadan road accident: Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́tàdínlógún lọ́nà Ibadan

Tanka agbepo jona

Oríṣun àwòrán, @LASEMA

O kere tan, eeyan mẹtadinlogun lo jona raurau ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ loju popo ilu Eko si Ibadan lọjọ Ẹti.

Ọkọ bọọsi Mazda akero kan ni wọn lo kọlu tanka agbepo lori afara Isara loju popo naa.

Ọga ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC, ni ipinlẹ Ogun, Ahmed Umar lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn akọroyin.

Ọgbẹni Umar sọ pe bi ago marun un ìdajì ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.

O ni o nira lati sọ ni pato iye awọn eeyan to fara kaasa ninu ijamba ọkọ naa.

Àkọlé fídíò, Oyetola, Aregbesola àti Tinubu ni ọ̀rọ̀ náà wa láàrin wọn

Umar ṣalaye pe ere asaju lo jẹ kí ọkọ akero ọhun kọlu tanka agbepo eleyii to jẹ ọkọ mejeeji gbana.

Ọga ajọ FRSC ni oun ko le sọ pato ọkọ to jẹbi ninu awọn mejeeji.

Àkọlé fídíò, Oja Odan nibi ti wọn ti dáná sún afurasi meji ti wọn ba ori eeyan lọwọ wọn

Umar ni ọna Ibadan ni ọkọ akero naa mori le nigba ti tanka agbepo n bọ wa sí ilu Eko.

Nọmba ọkọ akero Mazda naa ni ZT 28 KLD nigba ti ko si nọmba lara tanka.

Àkọlé fídíò, Ìjẹ̀bú: Àgbàlàgbà ni mo máa ń ṣe nínú eré tẹ́lẹ̀

Ọgbẹni Umar sọ pe obinrin kan, ọkunrin kan ati ọmọde nikan ni eeyan le damọ ninu awọn to ku nibi iṣẹlẹ naa.

Ọga ajọ FRSC nipinlẹ Ogun ni ijamba ọhún ko ba ti ṣẹlẹ ti awọn awakọ mejeeji ba tẹle ilana ọkọ wiwa loju popo ni.

Umar kẹdun pẹlu awọn ẹbi awọn eeyan to doloogbe ninu ijamba ọkọ naa.