Mo ṣèsì lo ATM oníbàárà gba owó ni ẹ màrún-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ - Òṣìṣẹ́ Banki tẹ́lẹ̀rí

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Osisẹ banki tẹlẹ ri, Uchenna Emmaunel ti jẹwọ pe oun sesi lo kaadi igbawo ti a mọ si ATM to jẹ ti onibaara banki to n ba sisẹ gba owo ni ẹ marun un ọtọọtọ.

Afurasi tu kẹkẹ ọrọ lọjọ Ẹti lasiko ti ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ondo n safihan rẹ niluu Akurẹ pẹlu awọn afurasi mii.

Ninu Alaye rẹ, o ni oun gba owo jade pẹlu kaadi naa ni igba marun lati ra nnkan ti apapọ rẹ jẹ ẹgbẹrun marundinlogoji naira.

O tẹsiwaju pe POS ti oun lo lati fi gba owo ninu apo owo onibaara ni oun ti da bi ọgbọn si, ti ẹnikẹni ko si le fuura.

O salaye siwaju: " Mo sesi lo kaadi owo onibaara lati fi ra nnkan lati ileeṣẹ kan

"Mo ro pe Kaadi mi ni

"Wọn bi mi pe bawo ni mo se mọ nọmba ati igba owo onibaara naa, mo ni mo lo nọmba temi.

"POS ti a lo fi gba owo naa jade le gba owo jade lai nilo nọmba ti a mọ si Pin kaadi naa."

Ọwọ́ Ọlọ́pàá tẹ àwọn ọrẹ mẹ́ta oníjìbìtì 'One Chance' l'Ogun

Aworan

Oríṣun àwòrán, Police Ogun

Ọwọ Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ awọn ọrẹ mẹta kan ti wọn fọwọsowọpọ lati ma lo mọto fi lu awọn araalu ni jibiti, eyi ti wọn n pe ni 'One Chance' nipinlẹ Ogun.

Ayọmide Akerele, Yinka Ọlanipẹkun ati Ọlatunde Ọlapade ni ọwọ palaba wọn segi ni agbegbe opopona Ṣagamu si Ijẹbu-Ode lasiko ti wọn n ṣiṣẹ buruku wọn

Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla gbe jade lọjọ Aje, Mọnde, jẹ ko di mimọ pe lati inu oṣu kẹfa, ọdun yii l'awọn ti n wa awọn afurasi ọdaran naa, ati pe awọn lo akanti awọn ti wọn lu ni jibiti lati fi tọpinpin wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n sọ b'awọn eeyan naa ṣe n ṣiṣe, o ni wọn yoo lọ si garaaji pẹlu bọọsi wọn lati fi ko ero, igba ti wọn ba de oju ọna ni wọn yoo yọ awọn nnkan ija oloro s'awọn ero, ti wọn yoo si gba gbogbo dukia wọn, to fi mọ kaadi ti wọn fi n gba owo lẹnu ẹrọ, eyi ti a mọ si ATM.

Odutọla l'awọn eeyan yii tiẹ tun maa n dunkooko gidi mọ awọn ti wọn ba fẹẹ ja lole lati fi owo ranṣẹ lati ori foonu wọn sinu apo ifọwọpamọsi awọn.

Siwaju lo ni wọn yoo dunkooko mọ awọn ti wọn ba ja lole lati bura tipatipa wi pe awọn ko nii tu aṣiri, tabi lọ sọ f'awọn ọlọpaa nipa ohun to ṣẹlẹ, bi bẹẹ kọ, wọn yoo ku danu.

Lẹyin eyi lo sọ pe bi wọn ba ti gba gbogbo nnkan ti wọn ba fẹẹ gba tan, wọn yoo ti awọn ero danu, ko to di pe wọn na papa bora.

O ni eyi ni wọn ṣe, ti wọn tun fi gba ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira lọwọ ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Isaac Alabi, ti wọn si ti i danu lori ere lati inu mọto wọn.

Odutọla sọ ọ di mimọ pe nigba ti awọn afurasi ọdaran yii n jẹwọ f'awọn, wọn ni agbegbe Oje Bẹẹrẹ to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ l'awọn ti n wa si ipinlẹ Ogun, t'awọn yoo si ṣiṣẹ niluu Abẹokuta si Ṣagamu, to fi de Ijẹbu-Ode, ṣugbọn to ni ọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ódun ti a wa yii lọwọ palaba wọn segi.

Siwaju sii lo sọ pe awọn ti gba bọọsi ti wọn fi n ṣiṣẹ buruku yii lọwọ wọn, ati pe ọga awọn agba, CP Alamutu Abiọdun Mustapha to jẹ kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti paṣẹ pe ki awọn eeyan yii lo f'oju ba ile-ẹjọ lati foju winna ofin.