Wo àwọn kókó tó ṣeéṣe kó jẹyọ́ nínú ọ̀rọ̀ Ààrẹ Tinubu sí àwọn Naijiria lálẹ́ lónìí

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti kede pe ohun yoo ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ ni oni, Ọjọ Aje, Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Osu Keje, ọdun 2023
Ninu atẹjade ti wọn fi lede gba ọwọ olubadamọan pataki fun aarẹ lori ọrọ ibanisọrọ, Dele Alake lo ni aarẹ yoo ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ ni aago meje ni aṣalẹ oni.
Ninu atẹjade naa ni wọn ti kesi awọn ileeṣẹ tẹlifisọn ati ileeṣẹ redio lati darapọ ileesẹ amohunmaworan,NTA ati ileeṣẹ redio FRCN lọna ati gbọ ohun ti aarẹ niise fun awọn araalu.
Lati igba ti aarẹ Tinubu si ti kede ayọkuro owo iranwọ naa ni Osu Karun un, ọdun 2023, ni o ti ṣẹlẹri pe oun yoo se awọn eto iranwọ fun awọn araalu.
Ohun to seese ki aarẹ Tinubu sọrọ le lori ree…
Lara awọn ohun to seese ki aarẹ sọrọ le lori ni igbiyanju ijọba lati mu igbeaye rọrun fun awọn araalu lẹyin ti wọn yọ owo iranwọ ori epo bẹntirol to ti mu inira ba ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria.
Bakan naa ni ọwọngogo epo bẹntirol naa ti fa ọwọngogo owo ounjẹ ati ile, eto irina ati awọn nkan miran si tig be owo lori.
Nitorinaa ni igbagbọ wa wi pe Aarẹ Tinubu yoo sọrọ nipa ohun ti awọn eniyan n la kọja ati awon ohun igbayegbadun ti wọn ni fun awọn araalu.
Bakan naa ni o seese ki aarẹ Tinubu sọrọ nipa orilẹede Niger ti awọn ologun ti gba ijọba nibẹ, ati ipa ti yoo ni lorilẹede Naijiria ati awọn eniyan rẹ.
Aarẹ Tinubu seese ko sọrọ nipa ipinlẹ Adamawa nibi ti awọn janduku ti sekọlu si awọn ileeṣẹ itaja ati awọn ibomiran ti awọn araalu wa.
Ọrọ eto aabọ naa yoo wa ninu awọn ohun ti aarẹ Tinubu yoo sọrọ le lori ati ohun ti ijọba ti n se lati mu ki eto aabo gbooro si ni Naijiria.












