Sunday Igboho fèsì padà fún Akeredolu lórí àtakò rẹ̀ sí Yoruba Nation

Oríṣun àwòrán, Akeredolu/Koiki
Oloye Sunday Igboho ti kede pe awọn ajijagbara to n beere fun Yoruba Nation yoo ṣaṣeyọri, ti Yoruba Nation yoo si duro ni igbẹyingbẹyin.
Igboho lo sọ ọrọ naa lati ẹnu agbẹnusọ rẹ, Olayomi Koiki lati fun gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lesi ọrọ rẹ pe awọn to n pe fun Yoruba Nation n fi akoko ara wọn ṣofo ni.
Gẹgẹ bii ohun ti Igboho sọ, awọn ọmọ Yoruba to n beere idasilẹ orilẹede Yoruba Nation lẹtọ lati ṣe bẹẹ, wọn si lẹtọ lati maa fẹhonuhan lori ibeere wọn.
Ki ni Igboho sọ?
Koiki ni “Ọmọwe Sunday Adeyemo Igboho ti ran mi lati sọ fun gomina ipinlẹ Ondo pe a o tẹsiwaju lati maa fẹhonuhan titi di igba ti ajọ isọkan agbaye yoo fi pin Naijiria, ti a si wa lọtọtọ.”
“Gomina ipinlẹ Ondo ko gbọdọ gba ki ogun kankan wọ ilẹ Yoruba gẹgẹ bii ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ṣe n ṣe ni ilẹ Igbo.”
“A ko ni gba ki awọn agbofinro maa fi ṣikun ofin mu awọn ajijagbara ilẹ Yoruba gẹgẹ bi wọn ṣe n mu awọn ti Biafra lainidi.”
Igboho sọ siwaju si pe ileeṣẹ ọmọ ogun tabi awọn ọlọpaa ko gbọdọ fi ṣikun ofin mu ẹnikẹni to ba n wọde lori ọrọ Yoruba Nation gẹgẹ bii ohun ti Akeredolu sọ.
O ni irufẹ igbeṣe bẹẹ le da ogun silẹ nilẹ Yoruba.
Koiki ni “Sunday Igboho ti ran mi lati kilọ fun awọn agbofinro lati maṣe mu ẹnikẹni to ba n beere fun ominira ilẹ Yoruba.’
“A ko ni gba ki wọn fi ofin mu ẹnikẹni to ba n beere ẹtọ rẹ labẹ ofin, a o tẹsiwaju ninu ifẹhonuhan alalafia wa ti a n ṣe.”
Igboho tun wa fi ọwọ gbaya pe awọn yoo tẹsiwaju lati maa ṣe iwọde lati beere fun idasilẹ orilẹede Yoruba Nation, awọn yoo si gbe iwọde naa lọ si ipinlẹ Ondo laipẹ.
"Wọn paniyan l’Ondo, Akeredolu ko ri nnkankan ṣe si"
Sunday Igboho wa fikun pe abẹ ijọba Akeredolu ni wọn ti ṣekupa ọmọ baba Fasoranti ati Ọba ilu Ifon.
Bẹẹ naa lo ni ilu Owo, ti Akaredolu funra rẹ ti wa, ni awọn agbebọn ti ṣekupa ọpọ eeyan ninu ijọ St Francis ninu oṣu Kẹfa ọdun yii.
O wa sọ pe awọn ko fẹ iru ifẹmiṣofo bayii mọ lawọn ṣe n beere pe Yoruba gbọdọ da duro funra rẹ.
Igboho wa pari ọrọ rẹ pe ki gomina Akeredolu ṣe suuru nitori ẹtọ araalu ni lati beere ẹtọ wọn labẹ ofin.












