Ọdún 25 lẹ́yìn ìgbéyàwó ni aya mi bímọ ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti bimọ́ síta- Aarẹ Ayandọtun Oyo

Oríṣun àwòrán, @Ayandotun IG
"Ọdún 25 lẹ́yìn ìgbéyàwó ní mó bímọ ibeji pẹ̀lú iranlọwọ imọ ijinle IVF $250,000 nigba naa"
Ọkan lara ọrẹ timọtimọ Alaafin tilu Oyo to waja, Aarẹ Ayandotun Ayanlakin ẹni to jẹ Aarẹ Ọba tilu Oyo ti salaye nipa igbe aye rẹ ati ajọsepọ rẹ pẹlu Alaafin ana.
Aare Ayandotun tun ṣalaye bi oun ati iyawo rẹ ṣe pade ni ilu Eko ni agbegbe Bariga.
O ni lẹba ile iya oun ni awọn ti pade nigba ti oun fẹ ya aworan.
O ni ninu ifọrọwerọ awọn ni oun ti mo pe ọmọ Fiditi ni ilu Oyo ni arabinrin naa ti wa lẹyin naa ni awọn di ọrẹ, ti oun si fi to iya oun leti.
"Ọdun 1972 ni a ṣe igbeyawo, ti a si ni idaduro fun bii Ọdun mẹẹdọgbọn, ki a to bi ibeji ni ilu Amẹrika.
Ilana ibimọ ti igbalode (IVF) ni a lo lati bi ibeji, ti mo si na to ẹgbẹrun lọna ọtalerugba o din mẹwa dọla ($250,000) nigba naa.

Oríṣun àwòrán, Collage
Ìdí rèé tí n kò fi fẹ́ ọ̀pọ̀ ìyàwo bíi Aláàfin - Ààrẹ Ọba Oyo
Ayandotun, ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu iwe iroyin Punch ṣalaye pe fun ọpọlọpọ ọdun ni oun fi ba Alaafin sisẹ, ko to di pe o waja.
O ni ile ẹkọ girama Oranyan Grammar School nilu Oyo ni oun wa nigba to Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi gori itẹ awọn baba nla rẹ.
Koda, o fikun pe oun wa lara awọn onilu to kọkọ fi ilu ki kaabọ sori itẹ ọba naa, ti oun ko si ju ọmọ ogun ọdun lọ.
Nigba to n sọrọ lori ajọsepọ rẹ pẹlu Ọba Adeyemi, Ayandotun ni ọba ti gbogbo aye fẹran ni Alaafin ana naa, ti ko si nifẹ si irọ pipa rara.
'"Bi Alaafin ba ri pe irọ wa ninu ọrọ eeyan kan, ko ni ba onitọhun se mọ laelae."
O fikun pe baba oun ni aarẹ Ayan fun ọba Adeyemi, ti oriade naa si tun fi oun joye Aarẹ Ọba lọna ati maa fọwọkọwọ pẹlu rẹ lori agbelarugẹ asa.
Gbogbo awọn gomina nilẹ Yoruba lo maa n tọ Ọba Adeyemi wa fun imọran - Ayandotun
Nigba ti to n sọrọ nipa iru ẹniti Alaafin Iku Baba Yeye jẹ, Ayandotun ni Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta jẹ Olori laarin awọn Ọba miran nilẹ Yoruba.
O fikun pe awọn gomina lawọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba ni wọn maa n tọ lọ fun imọran, ti wọn si mu gẹgẹ Baba.
Ayandotun ni oye aarẹ Ọba ti Kabiyesi Iku Baba yeye fi oun jẹ ko ṣẹyin awọn igbiyanju oun ninu awọn ẹgbẹ ti oun wa, ti Kabiyesi si jẹ ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa.
O fikun pe oye naa ko le bọ lọwọ oun ti Ọba miran bá jẹ tori wi pe ajẹku ni oye naa.
Nigba to n sọrọ lori yiyan Alaafin titun, aarẹ Ayandotun ni awọn igbimọ Oyomesi ni yoo sọ igba ti Kabiyesi tuntun ma gun ori itẹ.
"$250,000 ni mo fi se IVF fun aya mi, ko to bi ibeji"
Ayandotun Ayalakin, nigba to n sọrọ lori ibeywo rẹ mẹnuba ọpọ ifarada ati ipenija to ni ninu igbeyawo naa, paapaa igbiyanju oun ati aya rẹ lati ni ọmọ laye.
Ayandotun ni o gba oun ati iyawo oun ni ọdun mẹẹdọgbọn lẹyin igbeyawo, ki awọn to rí ọmọ bii.
Ọlọrun dahun adura wa, ti iyawo mi si bi ibeji eyi to mu ayọ ati idunnu ba wa."
Ayandotun fikun pe bo tilẹ jẹ wi pe Ọba Adeyemi ni iyawo pupọ, bẹẹ gẹgẹ ni Baba oun naa ni iyawo meji.
Amọ o ni ko wu oun lati gbe iru igbesẹ naa, lo jẹ ki oun ati iyawo oun fi ara da akoko ipenija naa, ki Ọlọrun to gbọ adura awọn.














