Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye kò fi Ilana Omo Oodua sílẹ̀, èèkàn ṣì ni nínú ìjìjàngbara òmìnira Yorùbá– Ilana Omo Oodua

Oríṣun àwòrán, screenshot
Ẹgbẹ ilana ọmọ Oodua ti ṣalaye pe lootọ ni Ọjọgbọn Banji Akintoye ti kọwe fi ipo silẹ gẹgẹ bi aṣiwaju ẹgbẹ naa ṣugbọn digbi lo ṣi duro ninu ijijagbara fun ominira ilẹ Yoruba.
Atẹjade kan ti ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, eyi ti akọwe agba ẹgbẹ naa, Tunde Amusat fọwọ si ṣalaye peahesọ ọrọti awọn kan n gbe kiri pe Ọjọgbọn Banji Akintoye ti fi ẹgbẹ naa silẹ kori bẹẹ rara.
Ni Ọjọbọ ni iroyin jade pe Baba Banji Akintoye ti kọwe fi ipo silẹ gẹgẹ bi aṣiwaju ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, to n lewaju ijijagbara fun ominira ilẹ Yoruba.
Baba Banji Akintoye jẹ kan lara awọn ohun to ye goorogo lori ipe fun ominira ilẹ Yoruba lati ọdun 2019 to ti bọ si ipo adari ẹgbẹ naa.
Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua sọ pe, “Baba ko fi igba kankan sọ pe awọn n yọwọ kuro ninu ijijagbara ominira ilẹ Yoruba tabi fi ẹgbẹ ilana ọmọ oodua, IOOW silẹ patapata. Oun ṣi ni awokọṣe fun wa ati ọkan lara awọn baba isalẹ ẹgbẹ yii.”








