Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa adẹ́rínpòṣónú, Peteru tó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, peterucomedy1
Gbajugbaja adẹrinpoṣonu to tun jẹ sọrọsọrọ lori redio, Oluwatobi Owomoyela, ti ọpọ mọ si Peteru ti jade laye.
Ọjọbọ ọṣe yii ni adẹrinpoṣonu naa fi aye silẹ lẹni ọdun marundinlogoji.
Iroyin ni aisan jẹjẹrẹ ‘colon cancer’ lo mu ẹmi oloogbe naa lọ, ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ kaakiri Naijiria lo si ti bẹrẹ si n ṣedaro iku rẹ.
Ṣaaju iku rẹ, Peteru jẹ ọkan lara awọn adẹrinpọsọnu ti irawọ rẹ ṣẹṣẹ n tan, paapaa ni iha Gusu iwọ oorun Naijiria.
Yatọ si pe o n ṣe iṣe adẹrinpoṣonu, o tun jẹ sọrọsọrọ lori redio niluu Ibadan, o tu maa n ṣiṣẹ adari ayẹyẹ.
Ọpọ awọn gbajumọ n ṣedaro Peteru
Ninu atẹjade kan loju opo Instagram rẹ, oṣere tiata Yoruba, Muyiwa Ademola pin iroyin nipa iku oloogbe naa, to si fi fidio kan sibẹ ni iranti rtẹ.
Ademola ni “Iroyin iku rẹ ṣoro fun mi lati gba... bawo ni irufẹ eeyan rere bayii ṣe maa ku?”
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Lẹyin naa lo ni “Ẹ jọwọ ẹ jẹ ka maa ṣe daadaa si ọmọlakeji wa o, nitori a ko mọ ohun ti ẹnikẹni n la kọja.”
“Mo gbọ pe arun jẹjẹrẹ lo pa Peteru. O n la irufẹ nnkan bayẹn kọja o si maa n rẹrin ni gbogbo igba.”
Yatọ si Muyiwa Ademola, ọpọ awọn gbajumọ mii lo ti bẹrẹ si n ṣedaro oloogbe ọhun.
Lara wọn ni Ọmọwe Jaiye Kuti, ti ọpọ mọ si Jayeola ni mo n jẹ, Wolii Agba, Princess Comedian, ati bẹẹ bẹẹ lọ.












