Christmas greetings: Kò sí ọdún tí ọjà ré tà tó ti Kérésì ọlọ́dọọdún- Alhaja Shakirat
Ọja Keresi kìí ṣe ọja ojoojumọ rara- Arabinrin Thomas.
Gbajugbaja olorin juju ni Naijiria, Ebenezer Fabiyi ti gbogbo eeyan mọ si Obey Commander ti kọ orin pe, ''ninu ọdun to m bẹ laye, ti keresi lo yatọ, to jẹ ọdun alarinrin...''
Nigba ti ikọ BBC jade lọ si ọja lọ wo awọn nkan to n ta warawara lasiko yii ni awọn ọlọja fidi orin yii mulẹ lori bi ọja wọn ṣe n ta lasiko yii.
- Ogun 2023- INEC fi orúkọ Adelanwa rọ́pò Otegbeye fẹ́gbẹ́ òṣèlú ADC
- 'Fóònù tí ìyàwó ń ṣáàjì ló fẹ́ lọ mú kóun àtàwọn mẹ́sàn-án mìíràn tó gan mọ́ná'
- Àìsàn tó ń ṣe ọ ní ohun ṣe pẹlú oorun rẹ - Onímọ
- Mọ̀ síi nípa Bola Ige tó jẹ́ mínístà ètò ìdájọ́ ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣì ń wá ìdájọ́ òdòdo lórí ikú rẹ̀
- Kí ló dé tí Ooni Ile Ife fẹ́ gbẹ̀mí ara rẹ̀?
- Kò sí iṣẹ́ tó lè pa owó wọlé tó iṣẹ́ ọnà tí mo ń ṣe yìí- Femi Babalola
Diẹ lara awọn ti BBC ba sọrọ ni Alhaja Shakirat Abimbola, Arabinrin Thomas, Iya Lekan, ati Iya Waris ti wọn menuba awọn ọja ọdun ati bi wọn ṣe n ta si lasiko ọdun keresi ti 2019 yii.
Awọn ontaja yii ṣalaye pe, tọmọde tagba lo maa n ra nkan ọdun keresi bii fila, ina ọdun ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Fila ọdun Keresi, ina Ọlọrun, bata, aṣọ, gilaasi oju, aago ọwọ ọmọde, feere ati awọn nkan iṣere miran ni ọja ọdun ti kii ṣe ọja ojoojumọ.
Ìbí Jesu Kristi ni awọn onigbagbọ gba pe wọn n ranti ni asiko ọdun keresimesi.
Eyi maa n waye ni ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kejila, ni ọdọọdun ti ko yipada ri lati ẹgbẹlẹgbẹ ọdun ti wọn ti n sami ayẹyẹ ọjọ ibi Jesu naa.
- Ọlọ́pàá mú àwọn afurasí tó jí Gbenga Owolabi tó nilé ìtura Tana Suites tí wọ́n pa lẹ́yìn tí wọ́n gba owó ìtúsílẹ̀
- Ọwọ́ tẹ ọmọ ogun mẹ́rìn tó gbèrò láti gbàjọba ní Gambia, wo ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró báyìí
- Èsì ìdánwò òhun tí a ṣé síwájú là n bá fínra báyìí ní Nàìjíríà- Yemi Shodimu
- 2023- Kò ni sí àyè fún fóònù lílò nínú ojúkòó ìdìbò, ìdí rèé – INEC
- -Ẹ̀fọn àbaàdì tó ń fa ibà ní Asia ti ń yawọ ilẹ̀ Adúláwọ̀-