Ìjọba Osun gbé orúkọ àwọn tí ọkọ̀ ìjọba tí iyé rẹ̀ tó #2.9bn wà lọ́wọ́ wọn jade

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun ti darí gómìnà àná ní ìpínlẹ̀, Gboyega Oyetola, ìyàwó rẹ̀, Hajia Kafayat Oyetola àti àwọn tí wọ́n jọ ṣe ìjọba láti dá àwọn ọkọ̀ ìjọba tó wà lọ́wọ́ wọn tí owó rẹ̀ tó bílíọ̀nù #2.9bn padà.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ gómìnà Ademola Adeleke, Rasheed Olawale fi léde lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kejìlá ọdún 2022 ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọkọ̀ bọ̀gìnì tó jẹ́ ti ìjọba ní àwọn ènìyàn náà kó nígbà tí wọ́n parí sáà wọn.
Olawale ní bẹ́ẹ̀ kò sí òfin tó fi àyè gbà olóṣèlú kankan ní ìpínlẹ̀ Osun láti kó dúkìá ìjọba nígbà tí sáà wọn bá ti parí.
Ó ní alága ìgbìmọ̀ tí gómìnà Adeleke gbé kalẹ̀ láti ṣe ìwádìí àwọn ohun ìní ìjọba, Dókítà BT Salami fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ènìyàn náà kò ní àǹfàní láti sọ dúkìá ìjọba di tara wọn.
Agbẹnusọ gómìnà ní Dókítà Salami ní àwọn ti ṣe ìwádìí àwọn dáradára tí àwọn sì ti ri pé ó pọn dandan fún gbogbo àwọn tó kó ọkọ̀ náà láti da padà fún ìjọba.
Ó fi kun pé ìpele àkọ́kọ́ àwọn ọkọ̀ tí àwọn fẹ́ gbà padà ni ìwọ̀nyí àti pé àwọn mìíràn ṣì ń bọ̀ tí àwọn máa tó kéde orúkọ ti wọn náà tí àwọn máa gba ọkọ̀ ìjọba tó wà lọ́wọ́ wọn.
“Nínú àtẹ̀jáde orúkọ àti iye ọkọ̀ tó wà ní ọwọ́ wọn, ọkọ̀ bọ̀gìnì tó fi mọ́ Lexus Jeep, Toyota Prado àtàwọn míì tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ méjìlá ni Oyetola nìkan kó.”
“Ìyàwó rẹ̀ náà kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjọba ní èyí tí òfin kò fi àyè gbà.”

Oríṣun àwòrán, OSUN GOVT

Oríṣun àwòrán, OSUN GOVT

Oríṣun àwòrán, OSUN GOVT

Oríṣun àwòrán, OSUN GOVT
Olawale fi kun nínú àtẹ̀jáde náà pé igbákejì gómìnà àná, akọ̀wé ìjọba àná àtàwọn olùbádámọ̀ràn Oyetola ló kó ọkọ̀ olówó iyebíye tó jẹ́ ti ìjọba nígbà tí wọ́n ń fi ìjọba sílẹ̀.
Ó ní ọkọ̀ bọ̀gìnì méje ni igbákejì Oyetola nìkan kó lọ èyí tó lòdì sí òfin.
Bákan náà ló ní kí sénẹ́tọ̀ Oriolowo dá àwọn ọkọ̀ katakata, àtàwọn ọkọ̀ ìgbàlódé tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ tó jẹ́ ti ìjọba padà ní kíákíá.
Àtẹ̀jáde náà wá ṣe ìkìlọ̀ pé tí àwọn ènìyàn náà kò bá tètè dá àwọn ọkọ̀ náà padà, àwọn máa fi póró òfin gbé wọn.












