Àwọn ènìyàn kò ní máa san owó iná mọ̀nàmọ́ná tí wọn kò lò tí mo bá di ààrẹ Nàìjíríà – Tinubu

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter

Olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Bola Ahmed Tinubu ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé tí òun bá di ààrẹ níbi ìdìbò ọdún tó ń bọ̀, àwọn ọmọ Nàìjíríà kò ní máa san owó iná mọ̀nàmọ́ná tí wọn kò lò mọ́.

Èyí túmọ̀ sí pé òpin yóò débá lílo “estimated bill”. Estimated billing ni ìlànà tí àwọn iléeṣẹ́ tó ń pín iná ọba máa ń lò láti fi gba owí iná láì lo mítà kankan.

Nígbà tó ń bá àwọn olókoòwò sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé kan ìpínlẹ̀ Eko lọ́jọ́bọ̀, Tinubu ní kò ní sí gbogbo irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tí òun bá di ààrẹ.

“Ní gbogbo ọ̀nà, iná gbọ́dọ̀ wà, àwọn ènìyàn kò sì ní máa san owó iná tí wọn kò lò.”

“Tí mo bá di ààrẹ, sísan owó lórí nǹkan kan náà máa di ohun ìgbàgbé, ẹ lọ kọ́ sílẹ̀.” Tinubu fọwọ́ gbáyà.

Bákan náà ló fi kun pé gbogbo ìlérí tí òun ń ṣe lónìí ni yóò wá sí ìmúṣẹ̀ nígbà tí òun bá di ààrẹ.

Tinubu tún tẹ̀síwájú pé bí òun bá fi lè di ààrẹ Nàìjíríà, gbogbo àwọn tó ń ṣòwò ni ayé máa wà ní gbẹdẹmukẹ fún.

Lẹ́yìn ìpádé náà ni Tinubu fi àtẹ̀jáde sórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter rẹ̀ tó sì wí pé àwọn sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ṣe máa gbé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà dé èbúté ògo.

“Tí àwọn ènìyàn bá dìbò fún mi láti di ààrẹ Nàìjíríà, má à yan ìgbìmọ̀ lára àwọn tó ń ṣòwò káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kí wọ́n le pọkún àwọn nǹkan tí a nílò láti tẹ Nàìjíríà síwájú.”