Ká má tan ara wa jẹ, àwọn tó ń pè fún Yoruba Nation kò lè ṣàṣeyọrí – Akeredolu

Rotimi Akeredolu Aketi

Oríṣun àwòrán, @RotimiAkeredolu

Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu ti sọ pe ki awọn to n funrere Yoruba Yoruba lọ sinmi agbaja, nitori wọn ko le ṣaṣeyọri ninu ohunn ti wọn n bere fun.

O ni idi ti irufẹ ijijagbara bẹẹ ko fi ni ṣaṣeyọri ni pe yoo mu ki igbiyanju awọn to ti fi ẹmi wọn lelọ fun iṣọkan Naijiria ja si ofo.

Akẹredolu, to jẹ alaga ẹgbẹ awọn gomina iha Guusu lo sọ ọrọ naa nibi ayẹyẹ iranti awọn ologun kan to waye nilu Akure.

O ni “Awọn to n pe fun Yoruba Nation ko ni ṣaṣeyọri, awọn kan ko le fi ẹmi wọn lelọ fun orilẹ-ede yii ki awọn kọlọrọsi ẹda kan wa da gbogbo iṣẹ ti wọn ti ṣe ru.”

“Orilẹ-ede yii ṣe pataki si awa kan, a si mọ ẹtọ awọn eeyan lati jijagbara tabi ṣe ifẹhonuhan, amọ ti awọn ọlọpaa ba ri pe ohun ti o n ṣe lodi si ofin, wọn yoo ko ṣẹkẹṣẹkẹ si ọ lọwọ lọ sile ẹjọ.”

A ko ni ṣatilẹyin Yoruba Nation

Akeredolu tẹsiaju pe “A ni anfani nla bayii a ko si gbọdọ sọ anfaani naa nu, ni ṣe lo yẹ ki a ṣiṣẹ lati ri daju pe agbara pada si akata wa.”

“Awa ko ni ṣatilẹyi fun ẹnikẹni to ba n pe fun Yoruba Nation kankan... Naijiria ṣi maa dara.”

Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn agbofinro ko ni gba ki ẹnikẹni da ilu ru nitori awọn araalu gbọdọ ro ti awọn to ti fi ẹmi wọn lelẹ fun iṣọkan ati ilọsiwaju Naijiria.

Gomina ọhun sọ pe ko yẹ ki araalu kankan ṣatilẹyin fun ohun ti yoo fi ẹmi awọn ologun sinu ewu nitori wọn n gbiyanjuu lati daabo bo awọn araalu.

Ẹwẹ, adari ẹgbẹ Ilana Omo Oodu to n lewaju ijijagbara Yoruba Nation, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti kọwe fi ipo silẹ gẹgẹ bii adari ẹgbẹ ọhun.

Amọ, ninu atẹjade kan, ẹgbẹ naa ni tori ọjọ ori ni baba Akintoye ṣe kọwe fi ipo silẹ, kii ṣe pe o ti yọ ọwọ rẹ lawo ijijagbara naa.