Ilé aṣòfin Oyo ti dá alága ìjọba ìbílẹ̀ tó bọ́rá sílẹ̀ lórí ayélujára padà sẹ́nu iṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Olusola Oluokun@Facebook
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti da Olusola Oluokun, alaga ijọba ibilẹ Ila-Oorun Oyo ti wọn da duro laipẹ yii pada sẹnu iṣẹ.
Igbesẹ ati da Oluokun pada, waye lẹyin ijokoo ile naa to waye lọjọ keje, oṣu Kọkanla ọdun 2024 yii.
Igbimọ kan ti wọn ni ko wadii iṣẹlẹ to le Oluokun lẹnu iṣẹ lo pada jabọ pe o yege.
Ọnarebu Akintunde Olajide to n ṣoju ẹkun-un Lagelu, ti i ṣe alaga igbimọ oluwadii naa, kede fun ile pe Oluokun ko mọ-ọn-mọ gbe fidio naa sita.
O ni alaga yii kabaamọ iwa to hu lẹyin ti fidio ọhun jade sita, bẹẹ lo si tọrọ aforiji.
Fun idi eyi, o rọ ile aṣofin naa lati fi ọwọ osi fa a Oluokun mọra lẹyin ti wọn ti f’ọtun ba a wi.
Ṣe ṣaaju ni wọn yọ alaga naa nipo lẹyin ti fidio kan to ti bọra silẹ lori ayelujara jade sita.
Àwọn aṣòfin f’ọwọ́ wọ́nú

Oríṣun àwòrán, Others
Nibi ijokoo naa ni awọn aṣofin bii Igbakeji abẹnugan; Muhammed Fadeyi, Gbenga Oyekola, Ọnarebu Olorunpoto Rahman ati awọn mi-in ti gboriyin fun igbimọ naa pe wọn kuuṣẹ.
Wọn ni b’awọn ṣe da Oluokun duro fun igba diẹ yẹn yoo jẹ ẹkọ fun awọn eeyan mi-in ti wọn ki i ka nnkan kun.
Ati awọn ti ko mọ pe ipo tawọn di mu lawujọ ko ṣee yẹpẹrẹ.
Lẹyin eyi ni gbogbo ile fohun ṣọkan, pe awọn ti fọwọ wọnu, awọn si ti gba pe ki Olusola Oluokun pada si ọfiisi rẹ bii alaga .
Abẹnugan ile naa, Ọnarebu Adebo Ogundoyin, paṣẹ pe ki Igbakeji alaga to n dele de e, pada si aaye tiẹ, ki Oluokun maa ṣẹ alaga lọ.
Ogundoyin waa kilọ fun awọn eeyan to wa nipo nibi iṣẹ ijọba, lati mọ iru iwa to yẹ ki wọn hu, ati eyi to le ta abuku ba ipo wọn loju araye.
Ilé aṣòfin Oyo dá alága ìjọba ìbílẹ̀ tó bọ́rá sílẹ̀ lórí ayélujára, dúró

Oríṣun àwòrán, @Olusola Oluokun Facebook
L’Ọjọbọ, ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 2024 yii, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo,da Alaga ijọba ibilẹ Ila-Oorun ilu naa, Olusola Oluokun, duro lẹnu iṣẹ fun igba diẹ na.
Igbakeji rẹ ni wọn fa iṣakoso ijọba ibilẹ naa le lọwọ lẹsẹkẹsẹ.
Ki ni Oluokun ṣe?

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Fidio kan to jade sori ayelujara, eyi ti Olusola Oluokun wa ninu rẹ lai wọ aṣọ kankan sara lo fa wahala.
Ninu fidio ọhun, ṣokoto penpe ni alaga ti wọn rọ loye naa wọ, to si n jẹun ninu yara kan.
Bo ti n jẹun ni Oluokun n sọ awọn ọrọ idupẹ fun ẹni kan to pe ni Adukẹ.
O ni obinrin naa ni ejika ti ko jẹ ki aṣọ bọ lọrun o, ati pe o ba oun wa ipo alaga kansu, o tun gbe oun wa si ilu oyinbo.
Ṣugbọn awọn ọrọ kan tun n tẹle idupẹ Oluokun, eyi to mu tawọn eeyan sọ pe ko yẹ ki ẹni to dipo ijọba mu maa sọ nita gbangba.
Yatọ si pe bii ẹni to wa ni ihoho ni ṣokoto penpe to wọ naa tun jẹ.
Awọn ọrọ ti Oluokun sọ ninu fidio naa ni:
‘’Were wo ni ko mọ Aduke, awọn were wo ni o mọ Aduke, eni ti o ba ti mọ Aduke, ko le mọ ẹnikankan mọ titi ti yoo fi ku.
‘’O fun mi ni alaga kansu, wọn gbe mi wa ilu eebo. Mo moore, gbogbo ile mi lo n dupe o.
‘’Olori buruku wo ni o mo Aduke, wọn maa too mọ. Aladuke ṣe bẹbẹ, iya alubarika.’’
Ti mo ba dà yin, Ẹlẹdaa yin aa bi mi. Awọn to da yin lanaa, wọn ti ri gbọ.
Ẹ o ni i fi aisan logba, mo moore o. Were wo ni o mọ Adukẹ. O digba kan na’’
Ìgbésẹ ilé ìgbìmọ́ aṣòfin Oyo
Ninu ijokoo awọn aṣofin ipinlẹ Oyo l’Ọjọbọ naa, aṣofin Akintunde Olajide to n ṣoju ẹkun Lagelu, pe fun idaduro Oluokun nipo alaga.
Awọn aṣofin yooku naa kin aba naa lẹyin, afi aṣofin Rahman Olorunpoto to n ṣoju Ila Oorun Oyo ati Gbenga Oyekola to n ṣoju Atiba ni wọn bẹbẹ pe ki ile wo Oluokun ṣe.
Olori ile igbimọ aṣofin Oyo, Debo Ogundoyin, fọwọ si iyọnipo naa.
Ogundoyin sọ pe o lodi fun ẹni to jẹ alaga, to yẹ ko jẹ awokọṣe, lati maa huwa to tabuku ipo to di mu.
Bakan naa lo kilọ fun awọn alaga yooku lati fi eyi kọgbọn, ki wọn si fi eyi to ṣẹlẹ yii kọgbọn.
Ṣugbọn awọn eeyan kan n sọ pe alaga ti wọn yọ nipo naa ko lu ofin rara, wọn ni ṣebi o kan n dupẹ lọwọ alaanu rẹ ni, iyẹn ko so lodi sofin nibi kankan.














