Kókó mẹ́ta tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Joe Biden bá Tinubu sọ lórí fóònù

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Presidency
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ni Aarẹ Bola tinubu, gba ipe ori foonu lati ọdọ akẹẹgbẹ rẹ nilẹ America, Joe Biden.
Ipe naa lo waye ni nnkan bi aago mẹrin irọlẹ, to si gba awọn mejeeji to ọgbọn iṣẹju.
Minisita fun ọrọ ilẹ okeere, Yusuf Tuggar, lo fi ikede sita nipa ipe ọhun to waye laarin awọn olori orilẹ-ede mejeeji.
Gẹgẹ bi atẹjade lati ileeṣẹ aarẹ America to bọ si ọwọ BBC, ṣe s, Biden gboriyin fun Tinubu fun idari rẹ nilẹ Africa.
Awọn koko nnkan ti Tinubu ati Biden sọ niyii:
- Ẹkun omi to waye ni Naijiria
Aarẹ Biden ba Tinubu kẹdun lori iṣẹlẹ omiyale to waye laipẹ yii, eyi to ṣe akoba nla ni ẹkun iwọ-oorun Ariwa Naijiria.
Ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024, ni omiyale ṣẹlẹ ni ipinlẹ Borno, to si ṣekupa eeyan to le ni ọgbọn.
Koda, ajọ United Nations ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi omiyale to tii buru julọ lati bi ọgbọn ọdun sẹyin.
- Itusilẹ ọga ileeṣẹ Binance
Aarẹ Biden ti orilẹ-ede United States tun gboriyin, o si fi ẹmi imoore han si bi Aarẹ Tinubu ṣe lo ipo rẹ gẹgẹ bi adari, lati ṣeto itusilẹ ọmọ orilẹ-ede America, to tun fi igba kan jẹ agbofinro ni orilẹ-ede ọhun, Tigran Gambaryan, l’ọsẹ to kọja.
Ọsẹ to kọja ni ijọba Naijiria jawọ ninu awọn ẹsun to fi kan ọga ileeṣẹ idokowo ori ayelujara Binance, tigran Gambaryan, to ti kọkọ n jẹjọ.
Awọn ẹsun to nii sẹ pẹlu ṣiṣe fayawọ owo ni wọn fi kan Gambaryan, to si wa ni ahamọ lati oṣu Kẹrin , ọdun 2024.
Awọn alaṣẹ sọ pe ijọba jawọ ninu ẹjọ naa lẹyin ijiroro to waye laarin ijọba Naijriia ati America.
- Ajọṣepọ laarin US ati Naijiria
Awọn olori mejeeji tun sọrọ nipa pataki ajọṣepọ laarin US ati Naijiria, paapaa nipa amojuto awọn ipenija to n koju awujọ agbaye, ati idagbasoke eto aabo, to fi mọ ilọsiwaju ni oriṣiriṣi ẹka ọrọ aje.
Ni pataki julọ, Aarẹ Biden fi imoore han si ajọṣepọ to wa laarin wọn lori ọrọ ofin, to fi mọ ajọṣepọ ti wọn kede laipẹ yii lori awọn iwa ọdaran to n waye nidii karakata owo ori ayelujara ati fayawọ owo, imọ ẹrọ, ati mimu ayipada ba awọn ajọ agbaye lọna ti yoo gba ṣe igbelarugẹ ilẹ Africa.












