Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lu ìyànsípò àwọn mínísítà tuntun

Aworan ijoko ile igbimọ aṣofin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Senate

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile igbimọ asọfin agba ti buwọlu iyansipo awọn minisita tuntun ti Aarẹ Tinubu fi orukọ wọn ransẹ ni ọsẹ to kọja.

Ikede yii lo waye ni Ọjọbọ, Ọgbọnjọ Oṣu kẹwaa niluu Abuja.

Bẹẹ ba gbagbe, Aarẹ Bola Tinubu jawe ẹ lọ gbele yin fun marun un ninu awọn minisita rẹ.

Igbesẹ yii lo n waye lẹyin oṣu diẹ ti awọn araalu ti n ke si Aarẹ pe ko gba iṣẹ lọwọ awọn minisita ti wọn ko ṣe dede.

Yatọ si awọn to gba iṣẹ lọwọ wọn, Aarẹ Tinubu tun gbe awọn minisita mẹwaa lati ileeṣẹ ti wọn wa tẹlẹ lọ si awọn ileeṣẹ mii.

Aarẹ gba iṣẹ lọwọ Uju-Ken Ohanenye to jẹ minisita fun ọrọ awọn obinrin; Lola Ade-John to jẹ minisita irinajo afẹ, Tahir Mamman to jẹ minisita eto ẹkọ, Abdullahi Gwarzo to jẹ minisita abẹlẹ fun ile gbigbe ati idagbasoke ilu ati Jamila Ibrahim to jẹ minisita fun idagbasoke awọn ọdọ.

Lẹyin naa lo fa Bianca Odumegu-Ojukwu kalẹ gẹgẹ bii minisita abẹle fun ọrọ ilẹ okere, Nentawe Yilwatda gẹgẹ bii minisita ọrọ ọmọniyan ati adinku oṣi, o si fi opin si asiko Better Edu, ti wọn ti ni ko lọ rọọkun nile tẹlẹ.

Lọsẹ to kọja yii ni Aarẹ Bola Tinubu ati igbimọ ijọba rẹ tun wọgilẹ ileeṣẹ to n ri si ọrọ Niger Delta ati ileeṣẹ to n ri si idagbasoke ere idaraya.