Wo bí o ṣe lè mọ́ iye iṣẹ́ tí Mínístà rẹ ń ṣe àti bó ṣe lè fún ìjọba Tinubu ní máàkì....

Oríṣun àwòrán, PRESIDENCY
Ijọba apapọ Naijiria ti kede aapu kan to pe ni Citizens Delivery Tracker App, ti wọn le maa fi wo bi awọn minisita ati olori ijọba ṣe n ṣiṣẹ si.
Hadiza Bala Usman, to jẹ olubadamọran paraki si Aarẹ Bola Tinubu lo kede ọrọ naa ninu eyii to ti sọ pe ijọba be igbesẹ ọhun ki araalu le kopa ninu iṣejọba.
Ajọ Central Delivery Coordination Unit lo ṣagbekalẹ aapu naa loju opo YII nibi ti awọn araalu ti le ri aapu naa lo lori foonu wọn.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, pẹlu aapu ọhun, ibikibi ti awọn ọmọ Naijiria ba wa ni wọn ti le maa fun ijọba ni maaki iṣẹ to n ṣe faraalu.
O ni yoo tun fun araalu lanfani lati ri awọn iṣe akanṣẹ ti ijọba n ṣe.
Yato si eyii, yoo tun fun wọn lanfani lati maa ri ibi tijọba ba iṣẹ de ni yajoyajo.
Wọn yoo tun ni anfani lati tun sọ awọn kudiẹkudiẹ ti ijọba n ṣe lọna ati ṣatunṣe si.

Oríṣun àwòrán, SCREENGRAB/CDCU
Bawo ni aapu naa yoo ṣe maa ṣiṣẹ?
Lori aapu ọhun ni araalu yoo ti le maa sọ fun ijọba awọn iṣẹ ti wọn n fẹ ko ṣe lori awọn ohun mayedẹrun bii eto ilera, eto ẹkọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nibẹ naa ni wọn yoo ti ri asiko ti iṣẹ naa ba pari.

Oríṣun àwòrán, SCREENGRAB/CDCU
Ti o ba ti lọ soju opo ti aapu naa wa ni o maa ri awọn nnkan mẹjọ to ṣe pataki si ijọba to wa lode.
Lẹyin naa ni o maa tẹ ileeṣe ijọba ti o fẹ wo ibi ti wọn ba iṣe de.
Ti o ba ti ṣe eyii tan ni o maa ri ọdun ti a wa ati eto ti ileeṣẹ naa ni faraalu atawọn aṣeyọri to ti ṣe.
Lẹyin ni o maa ni anfaani lati fun ileeṣẹ naa ni maaki gẹgẹ bi wọn ṣe ṣiṣẹ si.














