Ariwo tún sọ l’Ogbomoso lórí ìròyìn tó ní Soun gba ilẹ̀ àwọn mùsùlùmí fún àwọn aláwo

Laipẹ yii ni fidio kan jade soju opo ayelujara, nibi ti awọn ẹlẹsin Islam niluu Ogbomoso ti n fi ẹsun kan Oba Afolabi Olaoye Ghandi, Soun Ogbomoso, pe o gba ilẹ awọn fun awọn alawo.
Alaye ti awọn to ṣe fidio naa ṣe ni pe ilẹ kan to wa ni Ojaagbo, to jẹ ti awọn Musulumi, ni Ọba Ghandi fun awọn Oniṣẹṣe lati fi kọ ṣọọbu.
Wọn fi kun un pe o ti foju han pe ki i ṣe Imaamu Ayilara nikan ni Soun n ba ja, wọn ni gbogbo musulumi Ogbomoso ni.
Ki ọrọ naa maa di wahala, wọn ni ki ẹnikan ti wọn pe ni Ọnarebu George Ogunlade, waa ko bulọọku tawọn eeyan rẹ ko si ori ilẹ naa.
Bakan naa ni wọn pe akiyesi Alaga ijọba ibilẹ Ogbomoso naa si ọrọ ọhun, wọn ni ko ma baa di wahala lawọn ṣe n sọ pe ki wọn waa ko bulọọku wọn.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Àlàyé láti ààfin Kábíyèsí Ghandi Olaoye

Oríṣun àwòrán, @Soun Ghandi
Ko pẹ ti fidio naa jade ni atẹjade kan wa lati aafin Ọba Ghandi Olaoye,nibi ti wọn ti sọ pe o ya awọn lẹnu pe ọrọ naa gba ibo mi-in yọ.
Apa kan atẹjade naa sọ pe erongba kabiyesi ni lati kọ ọja igbalode si ẹgbẹ mọṣalaaṣi Ojaagbo, ki gbogbo ibẹ le ba igba mu.
"A fẹ ki ẹ mọ pe Aafin Soun naa lo ni ilẹ to de ibi ti a mọ si gbọngan Ogunlola, ati awọn nnkan to wa lori rẹ.
"Bo ṣe jẹ pe ita gbangba ni ilẹ yii wa, ni ọkọọkan gbọngan ati lẹgbẹẹ mọṣalaaṣi, to si jẹ pe ọja ti wọn ṣi n na lo wa nibẹ, lo fa a ti wọn ṣe fẹẹ kọ ọ lọna igbalode.
"Koda, bi wọn ba kọ awọn ṣọọbu naa tan, awọn to n taja lọja yii tẹlẹ naa la o ṣi gbe e fun lati maa lo o lọ."
Aafin Soun tun sọ ninu atẹjade naa pe ki erongba yii le wa si imuṣẹ ni kabiyesi ṣe paṣẹ fun awọn eeyan pataki meji ti wọn fẹẹ joye niluu, pe ki wọn kọ ṣọọbu naa .
Wọn ni kabiesi, Soun Ghandi Olaoye, gbe igbesẹ naa dipo ko gba ẹbun tabi maa bere nnkan mii lọwọ awọn ọmọ ilu lo fi ni ṣoọbu ti yoo mu idagbasoke wa ni ki wọn kọ.
Wọn ni ilana tuntun leyi l’’Ogbomoso , to yato si ohun ti ilu n ba a bọ tẹlẹ.
"Ki idagbasoke le wa ni gbogbo eto yii da le lori, ki i ṣe fun ajẹbanu kankan bi wọn ṣe n gbe e kiri.
"O ṣe ni laanu pe wọn ki ọrọ ẹsin bọ ọ, to si dohun ti wọn n dunkooko mọni.’’
Atẹjade naa tẹsiwaju pe awọn eeyan kan wa ti wọn ti fi ọrọ ẹsin ru loju, ti wọn sọ fun pe mọṣalaaṣi lo ni ilẹ, ati pe idagbasoke kankan ko gbọdọ waye lagbegbe rẹ rara.
Kabiyesi waa ni ti wọn ko ba fẹ idagbasoke ti oun n gbero waye, oun yoo gbe e lọ si ibomiran.
O ni ṣugbọn lọjọ kan ṣaa, ilẹ naa yoo pada di ohun ti wọn kọ ni.

Oríṣun àwòrán, Others
Igba akọkọ kọ niyii ti Soun Ogbomoso, Ọba Ghandi Olaoye, ni ede aiyede pẹlu awọn ẹlẹsin Islam niluu naa.
Ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2024, ni wahala kan waye lori bi kabiesi ṣe yọ Imaamu Agba ilu Ogbomoso, Alhaji Toliat Yusuf Ayilara, nipo.
Awuyewuye to n waye laaarin Ṣọun Ogbomọṣọ ati Imaamu agba ilu naa, Sheikh Ayilara bẹrẹ nigba ti kabiesi fi iwe ifisun ranṣẹ si i pe ko wa ṣalaye ara rẹ lori bi o ṣe rinrinajo lọ si Saudi Arabia fun Hajj lai gba aṣẹ lọwọ oun.
Lẹyin naa ni imaamu pe Ṣọun ati igbimọ Ṣọun Ogbomọṣọ lẹjọ lori igbesẹ to ni pe wọn n gbe lati yọ oun nipo.
Igbimo ẹgbẹ awọn Imaamu ati Alfa ti ilu Ogbomoso lo ba wọn da si ọrọ naa, amọ wọn pada yọ Sheik Ayilara nipo.












