Kíkọ̀ tí àwọn alágbàtà kọ̀ láti ra epo lọ́wọ́ mi ló fa ọ̀wọ́ngógó - Dangote

Obinrin to n ta epo sinu ọkọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Alaga ileeṣẹ Dangote, Aliko Dangote, ti di ẹbi ọwọn epo bẹtiro ni Naijiria, ru awọn alagbata epo to ni wọn ko ra ọja lọwọ oun.

Dangote sọ eyi nibi ipade kan to ṣe pẹlu igbimọ ileeṣẹ aarẹ lori karakata eporọbi pẹlu owo Naira.

Oniṣowo naa sọ pe bi awọn alagbata epo ko ṣe maa ra epo lati ileeṣẹ epo oun, lo fa bi awọn ọmọ Naijiria tun ṣe n to ra epo bayii.

Dangote sọ pe oun n fẹ ki awọn alagbata naa fi opin si rira epo wọn lati ilẹ okeere.

“Ti wọn ba n ra epo lati ileeṣẹ epo wa, ko ni i si ọwọn epo mọ ati bi awọn eeyan ṣe n to ra epo.”

O ni oun ko mọ idi ti wọn ko fi ra lọwọ oun mọ.

Ṣaaju ni awọn alagbata epo naa ti sọ pe awọn ko fẹ ki ileeṣẹ NNPCL jẹ alarinna laarin wọn ati Dangote, pe awọn fẹ ẹ maa ra epo lọwọ rẹ taara.

Eyi lo mu ki NNPCL kede pe oun ti jawọ ninu eto naa.

Dangote sọ pe oun fi ọwọ si adehun pẹlu awọn elepo naa, pe wọn le maa ra ni iye kan naa ti oun n ta epo fun NNPCL.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe ileeṣẹ epo oun ṣetan lati pese ọgbọn miliọnu lita epo fun awọn ọmọ Naijiria.

“A woye pe ọgbọn si mejilelọgbọn miliọnu lita epo bẹtiro ni awọn ọmọ Naijiria nilo lojumọ. Eyi kii ṣe nnkan to nira rara, nitori pe 500 miliọnu lita epo la ni ninu àgbá wa lọwọlọwọ. Eyi to tumọ si pe bi a ko tiẹ fọ epo , eyi ta a ni nilẹ le to ọmọ Naijiria fun ọjọ mejila.”