Ṣé lóòótọ́ ni Sanwo-Olu pe EFCC l'ẹ́jọ́ pé kí wọ́n ó má gbé e tó bá parí sáà rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/Facebook
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá ni ìròyìn gbòde pé gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu wọ àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, EFCC lọ sílé ẹjọ́.
Ìròyìn náà ní ẹ̀sùn pé EFCC ń gbèrò láti fi òfin gbé Sanwo-Olu lẹ́yìn tó bá parí sáà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà Eko ló pe àjọ nàá lẹ́jọ́ fún.
Wọ́n ní agbejọ́rò fún Sanwo-Olu, Darlington Ozurumba ló pe ẹjọ́ náà lórúkọ gómìnà ọ̀hún ní ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja.
Sanwo-Olu, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ, sọ fún ilé ẹjọ́ pé òun ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ ìwé òfin Nàìjíríà ọdún 1999 láti ní àwọn dúkìá tó jẹ́ ti oun ṣáájú, lásìkò àti lẹ́yìn tí òun bá di ipò òṣèlú mú léyìí tó kún níní akoto owó pẹ̀lú ilé ìfowópamọ́.
Ó ní kí ilé ẹjọ́ dájọ́ pé ìdúnkokò EFCC láti fi òfin gbé òun, ṣèwádìí òun lásìkò tí òun ń ṣe ìjọba lọ́wọ́ lòdì sí abala Karùndínlógójì àti ìkọkànlélógójì ìwé òfin Nàìjíríà.
Ìròyìn náà fi kun pé ó ní èròńgbà EFCC láti nawọ́ gán òun lórí ipò òun gẹ́gẹ́ bí gómìnà Eko jẹ́ òun tí kò bá òfin mu.
Ó ní kí ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí EFCC má ṣe ìwádìí òun lórí nǹkan tí òun gbéṣe nígbà tí òun wà nípò gómìnà.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fèsì
Àmọ́ ní òwúrọ̀ Ọjọ́rú, ọgbọ̀njọ́, oṣù Kẹwàá, ni iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìdájọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko jiyàn ìròyìn náà.
Kọmíṣọ́nà fún ètò ìdájọ́, tó tún jẹ́ agbejọ́rò àgbà ìpínlẹ̀ Eko, Lawal Pedro nínú àtẹ̀jáde tó fi síta ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà.
Pedro nínú àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé gómìnà Sanwo-Olu kò fi ìgbà kankan gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí bá agbejọ́rò kankan sọ̀rọ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lórúkọ òun.
Ó ní lábẹ́ òfin, gómìnà ní àǹfàní táwọn olóyìnbó ń pè ní "immunity" àti pé ẹni tó ní àǹfàní, tó sì ní bíi ọdún mẹ́ta láti lò si lórí ipò kò ní máa ronú irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lásìkò yìí.
Pedro fi kun pé ìwádìí òun fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé EFCC kò máa ṣe ìwádìí Sanwo-Olu tàbí fìgbà kan ránṣẹ́ pè é rí àtàwọn tó ń bá ṣiṣẹ́ rí.
Ó ní àwọn ti ń ṣe ìwádìí ìròyìn náà.
Bákan náà ló fi kun pé gómìnà Sanwo-Olu ti ṣe àfihàn ara rẹ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ tó ń ṣe, pàápàá ṣíṣe àmójútó ọrọ̀ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko.
Ó ní Sanwo-Olu ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti túbọ̀ mú ìgbé-ayé rọrùn fáwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Eko títí di oṣù Karùn-ún ọdún 2027 àti pé kò ní ẹbọ lẹ́rù tí yóò fi máa bẹ̀rù ìgbà tí yóò kúrò ní ọ́fíìsì láti àsìkò yìí.
Pedro rọ àwọn ènìyàn pàápàá àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn láti máa ṣe ìwádìí wọn dáadáa kí wọ́n tó máa gbé ìròyìn.















