Wo bí ìgbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Ramon Adedoyin pè tako ìdájọ́ ikú rẹ̀ ṣe n lọ

Oríṣun àwòrán, Others
Ile-ẹjọ kotemilorun to wa niluu Akure to jẹ olu ilu Ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ igbẹjọ idajọ loni lori ẹjọ kotẹmilọrun ti ẹni to ni ile itura Hilton Hotels ni Ile-Ife nipinlẹ Osun, Dokita Ramon Adedoyin pe, lori idajọ iku ti adajọ fun lori iṣekupani akẹkọọ fasiti OAU, Timothy Adegoke.
Ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2023, ni ile-ẹjọ giga nipinlẹ Osun lo da ẹjọ pe ki wọn yegi fun nitori o lọwọ ninu iku arakunrin naa to sun si ile itura rẹ.
Ṣugbọn Ramon Adedoyin ti ni oun ko faramọ idajọ iku naa, to si ti gba ile-ẹjọ naa.
O n fẹ ki ile ẹjọ wọgile idajọ iku naa.
Amọ, a ko tii le sọ boya ẹjọ kotẹmilọrun naa yoo kan awọn oṣiṣẹ rẹ ti wọn jọ gba idajọ akọkọ.


Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?
Ti a ko ba gbagbe, Onidajọ Adepele Ojo lo dajọ pe ki wọn yẹ igi fun Ọgbẹni Adedoyin ati oṣiṣẹ rẹ meji, Adeniyi Aderogba ati Oyetunde Kazeem lẹyin ti iwadii fihan pe wọn jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Bakan naa ni adajọ ni ijọba ti gbẹsẹ le ile itura naa, ti o si ti di ti ijọba. Adajọ tun ni ohun ini Adedoyin ni wọn yoo fi ran awọn ọmọ oloogbe Timothy Adegoke lọ si ile-ẹkọ titi wọn yoo fi jade fasiti.
Amọ adajọ naa fi awọn oṣiṣẹ mẹta silẹ, Magdalene Chiefuna, Oluwole Lawrence ati Adebayo Kunle ki wọn maa lọ ni alaafia, ti akọwe to wa ni ibi isẹ naa si gba idajọ ẹwọn ọdun meji.
Ramon Adedoyin ti ni oun ko faramọ idajọ iku naa, eyi to mu ko gba ileẹjọ kotemilọrun lọ ti awọn adajọ yoo si sagbekale idajọ loni
A ṣi n ṣe afikun iroyin yii bi igbẹjọ ṣe n waye nile ẹjọ. Ẹ tẹti l'eko












