Ìjọba Ogun dá olùkọ́ tí wọ́n f'ẹ̀sùn kàn pé ó lu akẹ́kọ̀ọ́ pa dúró l'ẹ́nu iṣẹ́

Olukọ ati awọn akẹkọọ nile ẹkọ wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Ogun, ti paṣẹ pe ki olukọ kan, Azamdjo Elijah, ti wọn lo lu akẹkọọ kan, Monday Ariyo, pa ni ile-ẹkọ Obada Idi-emi, nipinlẹ naa lọọ rọ ọ kun nile na.

Atẹjade ti akọwe iroyin fun gomina, Lekan Adeniran, fi sita lọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024, fidi ẹyi mulẹ.

Yatọ si olukọ ti ọrọ naa kan, ijọba tun paṣẹ pe ki ọga agba ile-ẹkọ naa, Abilekọ Tamrat Onaolapo, waa wi tẹnu rẹ lori iṣẹlẹ naa.

Ijọba Ogun ni ọga ile ekọ ọhun yoo ni lati ṣalaye ohun to fa a to fi fun tiṣa laṣẹ lati ba akẹkọọ naa wi ni ilana to tako eyi ti ijọba fi lelẹ, to fi di pe ọmọ ọhun jade laye.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ mu tiṣa yii, ti wọn si fi i si ahamọ ọlọpaa.

Báwo ló ṣe jẹ́ tí tíṣà ń lu akẹ́kọ̀ọ́ pa?

Aworana wọn akẹkọọ ti wọn kawọ soke.

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 ni iroyin jade pe ọmọdekunrin kan, Monday Ariyo to wa ni ipele keji ẹkọ (SS2) jade laye.

Iku naa ki i ṣe ti aarẹ bi a ṣe gbọ, olukọ Elijah ni wọn lo gbe ike ikolẹ wa si kilaasi awọn akẹkọọ yii, to si sọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ fọwọ kan an, ko ma baa fọ.

Eyi ni a gbọ pe Monday fi ṣe ẹfẹ, pe bi ike ọhun ba tilẹ fọ, ṣebi owo awọn akẹkọọ naa ni wọn fi ra a.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọrọ naa ni olukọ gbọ to si fi ibinu rẹ han.

Bakan naa ni a gbọ pe Ọgbẹni Elijah lọọ sọ ohun to ṣẹlẹ fun olukọ agba, Abilekọ Onaolapo, oun si fi aṣẹ si i pe ko da sẹria fun ọmọ to sọrọ ti bi olukọ rẹ ninu naa.

Lati fiya jẹ Monday, ẹgba mejilelọgọjọ (162) ati ki ọmọ naa fo soke bii ọpọlọ nigba mejilelọgọjọ (162 frog jumps) ni iroyin sọ pe Ọgbẹni Elijah paṣẹ fun un.

Nibi ti akẹkọọ yii ti n jiya ọhun lọwọ ni wọn lo ṣubu si.

Nigba ti iranlọwọ ko si tete wa, nnkan n buru si i titi ti wọn fi gbe e lọ sileewosan, to si pada jade laye.

Ileewosan Federal Medical Center, (FMC) to wa l’Abeokuta ni Monday dakẹ si bi a ṣe gbọ.

Ṣugbọn agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Omolola Odutola to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe, ki i ṣe ẹgba mejilelọgọjọ ni olukọ lu oloogbe.

O ni fifo soke bii ọpọlọ mejilelọgọjọ ati ẹgba mẹrinlelogun ni.

Odutola sọ pe ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa, 2024 gan-an ni iṣẹlẹ naa waye, ti Monday si jade laye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa ọdun 2024.

O ni wọn ti gbe oku ọmọ naa lọ si mọṣuari Ayetoro, bẹẹ ni ayẹwo oku yoo waye lati mọ ohun to pa a gan-an.