Gani Adams pé Sunday Igboho lẹ́jọ́, ó tún n béèrè fún N5b

Sunday Igboho àti Gani Adams

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ìròyìn tó n lọ káàkiri báyìí ni pé, Ààrẹ Ọ̀nà Kakaǹfò ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adams ti pe ẹjọ́ tako ajàfẹ́tọ̀ọ́, tó n pe fun ìdásílẹ̀ Yorùbá Nation, Sunday Adeyemo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Sunday Igboho.

Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Oyo ni Gani Adams pé ẹjọ́ náà lọ tó sì ń bèèrè fún bílíọ̀nù márùn-ún náírà lọ́wọ́ Sunday Igboho.

Ẹ̀sùn tí Iba Gani Adams fi kan Sunday Igboho ni pé ó ká ohun òun sílẹ̀ lásìkò tí òun ń bá èèyàn kan sọ̀rọ̀ lórí fóònù láì gba àṣẹ lọ́wọ́ òun tó sì fi fọ́nrán náà sórí ayélujára.

Ó ní ìwà náà bá òun lórúkọ jẹ́, tó sì tàbùkù orúkọ òun.

Ààrẹ Ọ̀nà Kakaǹfò náà ní òun ń bèèrè fún ẹ̀tọ́ òun lábẹ́ òfin Nàìjíríà.

Ó ní ṣíṣe àgbéjáde òun tí àti ẹlòmíràn jọ sọ lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ látọwọ́ Sunday Igboho jẹ́ ohun tó lòdì sí òfin tó sì jẹ́ ìbanilórúkọ jẹ́ fún ipò Ààrẹ Ọ̀nà Kakaǹfò tí òun dìmú.

Ó ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ náà jẹ́ títẹ ltọ́ òun lójú mọ́lẹ̀ tí òun sì nílò láti owó náà láti fi ṣe àtúnṣe orúkọ òun tó bàjẹ́.

Gani Adams ń bèèrè pé kí ilé ẹjọ́ kéde ìwà tí Sunday Igboho hù nínú oṣù Kẹrin ọdún 2024 nípa gbígbé ohùn òun sórí ayélujára láì gba àṣẹ lọ́wọ́ òun bí èyí tí kò bá òfin mú rárá.

Àtẹ̀jáde kan tí Gani Adams fi síta ní láti ìgbà tí Sunday Igboho ti fi fọ́nrán náà léde ló ti ń tàbùkù òun lórí ayélujára.

Ṣáájú ni Sunday Igboho ti kọ́kọ́ wọ́ Gani Adams lọ sílé ẹjọ́ fẹ́sùn wí pé ó pe òun ní agbanipa àti pé òun lọ́wọ́ nínú ikú Bola Ige àti Fryo.

Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Oyo ni Sunday Igboho ti pe ẹjọ́ náà nínú oṣù Kẹrin ọdún 2024.

A ṣì ń ṣe àkójọpọ̀ ìròyìn yìí lọ́wọ́ fún ìfìdímúlẹ̀ rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn.