Kí ló dé tí Nkechi Blessing ń tọrọ àforíjì lọ́wọ́ TAMPAN pẹ̀lú omijé lójú?

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing/INSTAGRAM
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà nnì, Nkechi Blessing ti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹgbẹ́ òṣèré tíátà ilẹ̀ Nàìjíríà, TAMPAN láti forí ji òun lórí àwọn ìwà tí òun wù sẹ́yìn.
Nínú fídíò kan tó wà lórí ayélujára ni Nkechi Blessing ti kúnlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ méjéèjì, tó sì ń sunkún pé kí wọ́n forí ji òun.
Níbi ètò kan tó wáyé ní orílẹ̀ èdè Canada ni Nkechi Blessing ti ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn àgbààgbà òṣèré tó wà níbẹ̀ bíi Bolaji Amusan tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mr Latin pé kí wọ́n forí ji òun, tó sì ń sunkún.
Mr Latin ní kí Nkechi Blessing dìde lórí ìkúnlẹ̀ àmọ́ òṣèré náà ní ó sàn fún òun láti wà lórí ìkúnlẹ̀ láti tọrọ àforíjì náà.
Ó ní òun ṣe àfẹ́kù bí eré ṣíṣe àti pé ẹgbẹ́ náà ló sọ òun di èèyàn tí òun ń jẹ́ lónìí, tí wọ́n sì ń pọ́n òun lé káàkiri àgbàyé nítorí ipa tí ẹgbẹ́ TAMPAN ní lórí òun.
Ó sọ pé òun ti hu tí kò tọ̀nà sí ẹgbẹ́ TAMPAN, tí òun sì ń tọrọ pé kí wọ́n má bínú sí òun mọ́.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ìṣẹ̀lẹ̀ tó fà á tí Nkechi Blessing ń tọrọ àforíjì
Ní ọdún 2021 ni TAMPAN pàṣẹ pé adari eré kankan kò gbọdọ̀ pe Nkechi Blessing àti Adams Kehinde tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Lege Miami sí iṣẹ́ mọ́.
Eyi ko ṣẹyin bi awọn oṣere mejeeji ṣe n tahun sira wọn lori ayelujara.
Ẹgbẹ awọn oludari ere (director), to jẹ ẹka kan ninu ẹgbẹ Tampan Guild of Directors (TGD) ti paṣẹ pe ki oṣerebinrin, Sunday Nkechi Blessing ati oṣerekunrin, Adams Kehinde (Lege) lọ ọ rọọkun nile fun igba diẹ.
TGD jẹ ẹka kan ni abẹ agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣere tiata ni Naijiria, TAMPAN.
Ikede yii jẹyọ ninu atẹjade ti Alaga igbimọ oludari ere nigba naa, Damọla Ọlatunji fi sita ni alẹ ọjọ Aiku.
Ninu atẹjade naa, Ọlatunji sọ pe wọn ti pe akiyesi TAMPAN si iwa afojudi, sisọ ọrọ buruku si ara ẹni, ati awọn iwa mii, to n fa arinfin fun ẹgbẹ naa.
Igbesẹ ti ẹgbẹ TAMPAN gbe ko ṣẹyin bi awọn osẹre mejeeji ṣe n sọ ọrọ buruku si ara wọn lori ayelujara, nitori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan Baba Ijẹsha.
Lati igba ti iroyin ti jade pe ọwọ tẹ Omiyinka, ni awọn akẹẹgbẹ rẹ kan ti n gbena woju ara wọn.
Bi awọn kan ṣe n ṣe atilẹyin fun, ni awọn to koro oju si ẹsun ti wọn fi kan an n ba wọn wi pe ki wọn o ma ṣatilẹyin fun iwa ibajẹ.
Lara awọn ti 'ija' wọn gba ori ayelujara ni Iyabọ Ojo ati Yọmi Fabiyi.
Lẹyin ti Lege ti kọkọ tọrọ̀ aforiji fun awọn ọrọ to fi ṣatilẹyin fun Baba Ijẹsha, lo tun sọ pe Nkechi wu iwa arifin si oun lasiko naa.
Kini Nkechi gbọ ọrọ yii si, ni oun naa ba tun bọ si ori ayelujara Instagram tiẹ naa, to si sọ oko eebu si Lege Miami.
Amọ ni bayii, TAMPAN sọ pe oun kede aṣẹ idaduro naa fun awọn mejeeji "nitori pe iwa adojutini ti wọn n hu lori ayelujaran ta ẹrẹ si aṣọ apọnle ẹgbẹ naa.
"O si di dandan pe ki a ra ìyì wa to ti bajẹ pada."
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ nigba naa, Olatunji sọ pe ibawi ti wọn fun Nkechi Blessing ati Adams Kehinde 'Lege Miami', kii ṣe ojuṣaaju.
O ni ọpọlọpọ igba ni ikilọ ti jade si awọn ọmọ ẹgbẹ TAMPAN pe wọn ko gbọdọ wọ ara wọn tabi sọ ọrọ kobakungbe si ara wọn lori ayelujara.














