Ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP jáwé olúborí ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìnlélógójì Kano

Oríṣun àwòrán, KANO STATE GOVT
Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Kano, KANSIEC ti kéde àwọn olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú NNPP gẹ́gẹ́ bí àwọn tó jáwé olúborí ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìnlélógójì tó wà ní ìpínlẹ̀ náà.
Bákan náà ni àwọn olìùdíje NNPP tún jáwé olúborí káhúnsílọ̀ ní wọ́ọ̀dù 484 tí ètò ìdìbò náà ti wáyé.
Alága KANSIEC, Ọ̀jọ̀gbọ́n Sani Lawan Malumfashi ló kéde èsì ìbò náà lẹ́yìn tí ètò ìdìbò ọ̀hún parí.
Ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́fà ló kópa nínú ètò ìdìbò náà tó wàyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta lẹ́yìn tí àwọn ilé ẹjọ́ ti gbé onírúurú ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ètò ìdìbò náà.
Wo àwọn nǹkan méje lórí ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Kano

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lónìí, ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n ọdún 2024 ni ètò ìdìbò sípò alága àtàwọn káhúnsílọ̀ ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ náà.
Àmọ́ lòdì sí bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò ìdìbò náà ṣe wáyé káàkiri àwọn ìpínlẹ̀, níṣe ni ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kano ní àwọn awuyewuye kan nínú.
Ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ni ètò ìdìbò ti bẹ̀rẹ̀ káàkiri ìpínlẹ̀ náà táwọn èèyàn sì jáde lọ dìbò pàápàá ní àwọn ìlú tó wà ní ààrin gbùngbùn ìlú Kano.
Àwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ jáde dìbò láwọn ìlú tó wà ní oko.
Èyí le rí bẹ́ẹ̀ bóyá nítorí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tó jẹ́ alátakò gbòógì ní ìpínlẹ̀ Kano ìyẹn APC àti PDP kò kópa nínú ètò ìdìbò náà.
Bákan náà ni àwọn èèyàn le tún máa bẹ̀rù nítorí àwọn ọlọ́pàá ní àwọn kò ní pèsè ètò ààbò látàrí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kan.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú pópó ìpínlẹ̀ Kano, Karota ni wọ́n ń ṣe àmójútó ètò ìdìbò ọ̀hún, tí wọ́n sì wà ní àwọn ìdí àpótí ìdìbò kọ̀ọ̀kan.
Kí ló fà á tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀? Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò ìdìbò tó ń lọ ní Kano náà rèé:
1) Ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́fà ló ń kópa

Oríṣun àwòrán, NURA MUDI
Alága àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Kano, KANSIEC, Ọ̀jọ̀gbọ́n Sani Lawan Malumfashi ní kò ṣíṣe tàbí àìṣe lórí ètò ìdìbò náà, pé àwọn máa tẹ̀síwájú láti ṣètò ìdìbò ọ̀hún nítorí àwọn ti gbáradì gidi fún-un.
Malunfashi ní ó ṣeni láàánú pé ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́fà péré nínú ẹgbẹ́ òṣèlú mọ́kàndínlógún tó wà ní Nàìjíríà ni yóò kópa níbi ètò ìdìbò náà.
Àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú náà ni:
- AA
- ZLP
- ACCORD
- AAC
- NRM
- NNPP
Èyí fi hàn pé àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò gòógì ní ìpínlẹ̀ Kano, APC àti PDP kò kópa níbi èò ìdìbò náà.
2). Ní ìjọba ìbílẹ̀ 44 ni ètò ìdìbò náà yóò ti wáyé

Oríṣun àwòrán, IBRAHIM ADAM
Gẹ́gẹ́ ètò ìkànìyàn ọdún 2006 ṣe fìdi rẹ̀ múlẹ̀, ìpínlẹ̀ Kano ni àwọn èèyàn pọ̀ sí jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìnlélógójì ló wà ní ìpínlẹ̀ Kano.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Sani Lawan Malumfashi ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ yìí ni KANSIEC ti ṣetán láti ṣètò tí kò ní ẹja ń bákàn nínú.
3). Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ mẹ́ta lórí ètò ìdìbò náà
Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀: Ní ọjọ́ Ẹtì ni ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Kano gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ pé kí ètò ìdìbò náà wáyé gẹ́gẹ́ bí KANSIEC ṣe ti gbáradì fún-un.
Ṣáájú ni ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ ní ètò ìdìbò náà kò gbọdọ̀ wáyé.
Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀: ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Kano ló ń wáyé lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ ti ṣe ìdádúrò ètò ìdìbò náà.
Adájọ́ Simon Amobeda ní kí wọ́n tú ìgbìmọ̀ àjọ KANSIEC ká nítorí àwọn aláṣẹ rẹ̀ jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP tó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Kano.
Agbẹjọ́rò fún àjọ KANSIEC, Muntari Garba Dandago sọ fún ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Kano pé kò sí ẹ̀rí pé olóṣèlú ni adarí àjọ KANSIEC nítorí náà kí wọ́n kí wọ́n jẹ́ kí ètò ìdìbò náà wáyé.
Ìdájọ́ kejì ilé ẹjọ́ gíga tìjọba àpapọ̀: Ní ọjọ́ Ẹtì ni adajọ́ Simon Amobeda ti ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tún gbé ìdájọ́ mìíràn kalẹ̀ tó sì pàṣẹ nǹkan mẹ́ta:
Ilé ẹjọ́ náà kò fàyè gba àjọ tó ń mójútó ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC, láti gbé àkọ́ọ́lẹ̀ orúkọ àwọn olùdìbò kalẹ̀ fún àjọ KANSIEC.
Ilé ẹjọ́ ní àwọn òṣìẹẹ́ ààbò kò gbọdọ̀ kópa nínú ètò ìdìbò náà.
4). Kí ni àwọn òṣìṣẹ́ ètò ààbò sọ lórí ètò ìdìbò náà?

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ pé ètò ìdìbò kò gbọdọ̀ wáyé, agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kano, Abdullahi Haruna Kiyawa gbé àtẹ̀jáde kan síta níbi tó ti sọ pé ilé ẹjọ́ ti pa àwọn láṣẹ láti má kópa nínú ètò ìdìbò náà.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn òṣìṣẹ́ àwọn yóò máa lọ káàkiri gbogbo ìlú àmọ́ àwọn kò ní dá sí ètò ìdìbò náà.
Àmọ́ lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ lánàá, Kiyawa ní Kọmíṣánnà ọlọ́pàá Kano ti fún àwọn láṣẹ láti máa lọ káàkiri ìpínlẹ̀ Kano láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dákìá àwọn èèyàn lásìkò ètò ìdìbò náà.
Ṣáájú ni àjọ KANSIEC ní àwọn máa ṣàmúlò àwọn ẹ̀ṣọ́ HISBAH lásìkò ètò ìdìbò náà.
5). APC ṣèkìlọ̀ fún ìjọba Kano

Oríṣun àwòrán, ALFINDIKI/FACEBOOK
Alága ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ní ìpínlẹ̀ Kano, Alhaji Abdullahi Abbas ti ṣèkìlọ̀ fún Gómìnà Abba Kabir Yusuf láti má tẹ̀síwájú pẹ̀lú ètò ìdìbò náà, pé kí wọ́n tẹ̀lé àṣẹ ilé ẹjọ́.
Àtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC fi síta lọ́jọ́ Ẹtì nílùú Abuja, Abdullahi Abbas ní tí gómìnà Abdullahi Abbas bá tẹ̀síwájú pẹ̀lú ètò ìdìbò náà, ó ṣeéṣe kí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ fa wàhálà ní ìpínlẹ̀ Kano.
6). Gbèdéke ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lórí ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀
Oṣù Kẹwàá ni ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà, ìyẹn Supreme Court fún gbogbo ìpínlẹ̀ káàkiri Nàìjíríà dà láti ṣètò ìdìbò sáwọn ìjọba ìbílẹ̀ tàbí kí wọ́n fojú winá òfin.
Wọ́n ní àwọn yóò ṣe ìdádúró owó tí ìjọba àpapọ̀ máa ń fún àwọn ìpínlẹ̀ fún ìpínlẹ̀ tó bá kọ̀ láti ṣètò ìdìbò náà tí gbèdéke náà bá fi lọ lórí wọn.
Nínú oṣù Keje ni ilé ẹjọ́ náà ni ìjọba àpapọ̀ kò gbọdọ̀ fún àwọn ìpínlẹ̀ ní owó ìjọba ìbílẹ̀ mọ́ àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà tọrọ lọ́wọ́ ilé ẹjọ́ láti fún àwọn di oṣù Kẹwàá.
7). Ètò ìdìbò Kano fara pẹ́ ti ìpínlẹ̀ Rivers
Àwọn olùwòye ní ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ìpínlẹ̀ Kano fara jọ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ níbi ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ Rivers níbi tí ẹgbẹ́ òṣèlú gómìnà ìpínlẹ̀ náà, PDP kò ríbi kópa nínú ètò ìdìbò náà.
Lásìkò ìdìbò ọ̀hún, àwọn ọlọ́pàá kò kópa níbi ètò ìdìbò náà bíi ti Kano yìí látàrí àṣẹ ilé ẹjọ́ tí àwọn ọlọ́pàá ní àwọn tẹ̀lé.
Èyí kò ṣẹ̀yìn lẹ́yìn wàhálà tó ń wáyé láàárín gómìnà Siminalayi Fubara àti gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike ní èyí tó farapẹ́ nǹkan tó ń wáyé láàárín àwọn gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní Kano, Rabiu Kwankwaso àti Abdullahi Umar Ganduje.
Lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí ètò ìdìbò ti ń parí ní àwọn apá ibìkan ní Kano, tí kíka èsì ìbò sì ti bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ìdí àpótí kan.















