Nítorí àìṣe ètùtù oyè, wọ́n ti yọ Kábíyésì kan lóyé ní ìpínlẹ̀ Ekiti

Aworan ade oba ilẹ Yoruba ati aworan kọọtu nipinlẹ Ekiti

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ileẹjọ giga kan nipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ki wọn yọ Kabiyesi Ọba Oluloro ti ilu Iloro Ekiti, Oba Femi Olugbesoye kuro lori ipo ọba ilu naa.

Ẹsun ti wọn fi kan Oriade naa ni pe o kuna lati tẹle ilana ati aṣa abinibi nipa eto Ọba jijẹ ni ilu Iloro-Ekiti.

Ni ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹwaa ọdun 2019 ni igbimọ alase ipinlẹ Ekiti fọwọsi yiyan Olugbesoye gẹgẹ bi Oluloro ti Iloro Ekiti.

Atẹjade ileẹjọ naa lori idajọ ti Onidajọ Jide Aladejana gbe kalẹ ẹsun ti Ọmọba Ọlakunle Fadare ati awọn mẹrin miiran pe Olugbesoye ati awọn mẹrin miiran lori ipo itẹ rẹ. jade l'Ọjọbọ, ọjọ kerinlelogun oṣu kẹwaa, ọdun 2024

Fadare ati awọn mẹrin miiran ti wọn jẹ olupẹjọ ninu jọ naa ṣalaye niwaju ile ẹjọ ọhun pe Olugbesoye ko ṣe ilana aṣa ti o yẹ, ṣugbọn awọn olujejọ ni ko ri bẹẹ, ti wọn si fi kun pe ileẹjọ ko ni ẹtọ lati gbo ẹjọ naa.

Ileẹjọ ni aṣiṣe nla ni fun Ọba Olugbesoye lati maṣe jọwọ ara rẹ fun igbimọ afọbajẹ

Ninu idajo ti o waye ni Ọjọ keedogbon (30th) Oṣu Kẹsan, ọdun 2024, Onidajọ Aladejana, sọ pe “Ninu ọran naa, ọrọ kan ṣoṣo ti a gbekale jẹ ipinnu ni ojurere ti awọn olupẹjọ lodi si awọn olujẹjọ naa.

"Adajo naa kede pe kikuna olujejọ akọkọ lati fi ara rẹ han fun Oloye Aoropare ati awọn igbimọ ti wọn n fi Ọba jẹ ni ilana ibamu pẹlu Ofin abinibi ati Aṣa ti wọn n fi jẹ Oluloro ti Iloro Ekiti jẹ aṣiṣe."

Adajo naa tun pa ni aṣẹ fun awọn olujejọ keji si karun lati rọ olujẹjọ akọkọ loye gẹgẹ bi Oluloro ti Iloro Ekiti ni ibamu pẹlu Ofin Aṣa ti Iloro Ekiti.

O tun paa ni aṣẹ fun olujejọ akọkọ lati maa pe ara rẹ ni Ọba Oluloro ti Iloro Ekiti

Lakootan, Adajo paa ni aṣẹ fun awọn olujejọ keji si karun pe ki wọn ma ṣe ri olujẹjọ akọkọ gẹgẹbi Oluloro ti Iloro Ekiti,”.

Saaju ni awọn olupẹjọ naa ti lọ si ile-ẹjọ ni Oṣu Kẹrin ọdun 2022 laarin awọn miiran "ni eyi ti o tun mọ si pe kikuna ati iko eti ikun olujejọ akọkọ lati fi ara rẹ silẹ fun awọn igbimọ afọba jẹ nipasẹ Aoropare ni ibamu pẹlu ofin abinibi ati aṣa Oluloro ti Iloro Ekiti jẹ aṣiṣe.

Ṣe lootọ ni pe ilu Ijero ni Ọba Olugbesoye ti lọ joye to si gba ade dipo ilu rẹ?

Ni ilẹ Yoruba, aṣa ti ọpọ mọ nipa oye jijẹ ati ade dide ni pe ọba yoo gba ade yoo si jẹ oye ni ilu rẹ, iyẹn ilu to fẹ jẹ ọba le lori.

Amọṣa ohun ti awọn olupẹjọ n sọ ninu ẹsun ti wọn ni pe kii ṣe ilu Ilọrọ ni wọn ti fi ade de ba Fẹmi Olugbesoye lori.

Wọn ni kabiyesi Ajero ti ilu Ijero Ekiti lo fi ade de e lori ni ilu Ijero dipo awọn afọbajẹ ilu Ilọrọ ni ilu Ilọrọ ti o fẹ jẹ ọba le lori.

Awọn olupejọ naa tun wa sọ pe Ajero ti Ijero Ekiti ko ni aṣẹ lati a fun enikeni ni oye Oluloro ati pe Ajero ti Ijero Ekiti ko ni aṣẹ tabi ẹtọ ibile labẹ ofin lati jawe oye tabi fi ẹnikẹni je Ọba Oluloro ti Iloro Ekiti.

Ọba Fẹmi Olugbesoye

Oríṣun àwòrán, ekitistandardnews.com

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu idahun rẹ, olujẹjọ akọkọ, ti o rọ ile-ẹjọ lati kọ eti ikun si olupẹjọ lori gbogbo ti o gbe wa si ile-ejo, lori ilana ati aṣa jijẹ Ọba Iloro Ekiti.

Awọn olujejọ keji si karun, tun rọ ile-ẹjọ lati da ẹjọ naa nu ṣapejuwe ọrọ naa bi nkan ti ko le ati ilokulo ilana ile-ẹjọ

Asiwaju Eko Oluwaseunfunmi ti o je Ọmọ bibi ilu Iloro fidi rẹ mulẹ nigbati o ba akọroyin BBC News Yoruba sọrọ pe wọn kii je ọba ilu Iloro ni Ijero Ekiti ati wipe Kabiyesi Ajero ko ni ẹtọ kankan lati fi Ọba ilu Iloro je.

O tesiwaju pe ti wọn ba fẹ jẹ Ajero ilu Ijero Ekiti ni Eyedofin (Olori Obinrin) ni ijemu lo lọ ma fi Ajero je ni ilu Ijero Ekiti ti kii sise Ọba Ajero lo ma n fi Oluloro je.

Ogbeni Asiwaju Eko OluwaSeunfunmi ni leyin ti Ọba Ijero gbe ade le ọba Femi Olugbesoye lori lo wa fe pada si ilu Iloro Ekiti lati ṣe gbogbo etutu ati asa ibile ti wọn ma n ṣe fun ọba tuntun to ba fẹ je ti gbogbo ilu si ni awọn ko fẹ gẹgẹ bi Ọba lo fa awuyewuye to fi de ile ẹjọ. Ti wọn si tu fi ọpọlọpọ esun kan Ọba naa.

Wọn ni tipatipa ni Ọba Femi Olugbesoye fi ń ṣe akoso ati adari ilu Iloro ki idajọ to waye.

Èmi Ọba Femi Olugbesoye ṣì ni Oluloro ti Iloro Ekiti títí ìgbẹ́jọ́ yóò fi parí nílé-ẹjọ́

Ola Olugbesoye

Oríṣun àwòrán, Oluloro youth forum/facebook

Ọba Femi Olugbesoye, Oluloro ti Iloro Ekiti naa tun ba akọroyin BBC News Yoruba sọrọ salaye pe, oun si ni ọba ilu Iloro Ekiti lọwọ lọwọ bayi. Nitori wi pe, oun ti gbe ẹjọ naa lọ ile ẹjọ kotemilorun.

Ọba Femi salaye pe akọsilẹ esi ẹda idajọ ti ko tete jade lati ile ejo leyin ọṣe mẹta ni ko je ki agbejoro ohun tete tesiwaju lọ ile ẹjọ kotemilorun ni eyi ti o tumo si pe ẹnikẹni ni anfaani labẹ ofin lati tun ẹjọ náà pe.

Ọbalaye naa ni lootọ ni awọn kan kora wọn jọ ti wọn si di tẹ mo lori Oye babanla ohun, o tun ro wọn wipe ki wọn gba ofin laaye lẹyin ti gbogbo ẹjọ naa ti ni ile ẹjọ.

O si fi di rẹ mule pe titi awọn yoo fi pari igbejo ni ile ejo, ohun si Ọba ati adari ilu Iloro Ekiti. Ìjọba ipinle Ekiti naa ko si ti kede pe ohun ko ni Ọba.

Lẹyin naa ni agbejoro fun olujejo akoko, Owoseni Ajayi, so pe wọn ti tesiwaju ni ile-ejo (kotemilorun) ti o ga julọ lori idajo naa, sugbon wọn ko tii fun wọn ni ojo kan bayii.