Èèyàn márùn ún péré ló lè bá igbákejì ààrẹ rìnrìnàjò, Mínísítà kankan kò gbọdọ̀ lò jú ọ̀kọ̀ mẹ́tà lọ mọ́ – Tinubu kéde àdínkù owó ìṣàkóso ìjọba

Oríṣun àwòrán, X/Bayo Onanuga
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu ti kede adikun owo nina ninu iṣakoso rẹ lẹyin to fofin de awọn minista, minisita ipinlẹ ati awọn olori ẹka ijọba apapọ din iye ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn gbe jade ṣiṣẹ ijọba si mẹta.
Ninu atẹjade ti agbẹsọ aarẹ lori iroyin, Bayo Onanuga, buwọlu fun awọn akọroyin ni Tinubu ni ko ni si aye fun bibuwọlu afikun ọkọ fun awọn minisita lati ṣe iṣẹ ijọba.
Igbesẹ yii lo waye nitori igbiyanju ijọba apapọ lati din iye owo ti ijọba n na lojumọ ku.
Bẹẹ ba gbagbe, ninu oṣu kinni ọdun yii ni Aarẹ Tinubu gbe igbesẹ, to si din awọn eeyan to n ba rin irinajo lọ si oke okun si ogun eeyan lati aadọta, to si din awọn eeyan n ba rin irinajo Naijiria si eeyan mẹdọgbọn
Ki ni awọn igbesẹ yii?
- Adikun ọkọ irinjo si mẹta
Ọkan gboogi ninu igbesẹ Aarẹ Bola Tinubu ni aṣẹ to gbe sita ninu dindin iye ọkọ ti awọn minisita ati olori ẹka ijọba n gbe lọ sita.
Aarẹ ni mẹta pere ni wọn ni anfani lati gbe lọ fun irinajo to ni ṣe pẹlu ijọba apapọ, ti wọn ko si ni fikun ohun kohun.
- Adikun ba iye eeyan to n tẹlẹ Igbakeji Aarẹ
Bakaa naa ni Aarẹ gbe igbesẹ ni ọdọ igbakeji Aarẹ to si jẹ pe eeyan marun un pere lo n tele igbakeji aarẹ rin irinajo lọ si ibikibi lorilẹede Naijiria, ti wọn si jẹ mẹdọgbọn to n tẹle Igbakeji lọ si oke okun.
- Dindin awọn ẹṣọ alabo to n tẹle awọn Minisita ku
Ninu aṣẹ tuntun yii, Aarẹ Tinubu palaṣẹ fun gbogbo awọn minisita ati awọn olori ẹka ijọba apapọ lati din awọn ẹsọ alabo to n sọ si marun un.
Ikọ awọn ẹsọ alabo ni yoo jẹ ọlọpaa mẹrin ati DSS kan.
- Ko ni si aye afikun awọn ẹsọ alabo,
Aarẹ ti paṣẹ fun oludamọran fun eto abo pe ko ba ileeṣẹ ologun ati ẹṣo alabo sọrọ lati mọ ọna ti wọn yoo gba din ọkọ i wọn ko jade ku.
“Gbpgbo awọn ti ọrọ kan ti wọn bẹrẹ si ni ma gbe igbesẹ lori aṣẹ yii ni kiakia.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















