Èyí ni àwọn ìgbésẹ̀ àti àṣẹ tuntun tí àjọ CAF gbé lórí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Libya àti Nigeria

Aworan awọn agbabọọlu Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Super Eagles/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n risi ere boolu ni ilẹ Afirika ti kede awọn igbesẹ tuntun ti wọn gbe lori ohun to waye lasiko ifẹsẹwọnsẹ igbaradi fun ife ẹyẹ adulawọ AFCON 2025 laaarin orilẹede Libya ati Naijira.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, awọn agbabọọlu Super Eagles Najiria yọ ọwọ kilanko kuro ninu awo ifẹsẹwọnsẹ kikopa ninu ere bọọlu ati pegede fun idije Afcon 2025 to yẹ ko waye lorilẹede Libya lẹyin ihuwasi to ku diẹ kaato latọdọ awọn alakoso ajọ ere bọọlu lorilẹede Libya eyi to mu ki awọn agbabọọlu Super Eagles atawọn alakoso wọn di atipo ni papakọ ofurufu kan lorilẹede naa fun ọpọlọpọ wakati laisi ounjẹ tabi omi.

Ilu Banghazi lorilẹede Libya lo yẹ ki baalu to gbe Super Eagles ba si, amọ, ilu Al Abraq to le ni igba kilomita si ibi ti ere bọọlu naa yoo ti waye ni wọn dari baalu naa si.

Ikọ agbabọọlu Super Eagles Naijiria pada wale lẹyin ohun ti oju wọn ni papakọ ofurufu lorilẹede Libya nibi ti wọn wa lai fi omi tabi ounjẹ kan ẹnu fun bii wakati mejila.

Balogun ẹgbẹ agbabọọlu naa, William Troost-Ekong ni fun bi ọdun mẹwaa toun ti n ṣoju Naijiria bayii pe oun ko tii ni iru iriri bayii ri.

Ki awọn igbesẹ ti CAF gbe atawọn aṣẹ tuntun ti wọn pa?

Ajọ CAF ni orilẹede Libya tako ofin ori kọkanlelọgbọn ti iwe ofin ajọ, ti wọn yoo si ri ijiya ofin.

  • Najiria lo bori ifẹsẹwọnsẹ

CAF ni wọn ti fun orilẹede Naijira ni goolu mẹta, to si jẹ pe awọn ni wọn bori ifẹsẹwọnsẹ to yẹ ko waye pẹlu Libya ni Ọjọ Kẹdogun oṣu kẹwaa ọdun 2024.

  • Sisan owo itanran

CAF tun ni ki orilẹede Libya san owo itanran to ẹgbẹrun lọna aadọta owo dọla fun ohun to waye ni orilẹede wọn.

  • Wọn gbọdọ san owo naa laaarin oṣu oṣu meji.

CAF ni awọn fun Libya ni gbedeke oṣu meji lati san owo itanran ni ilana tin ofin gbe kalẹ.

  • Wọgile ipe kotẹmilọrun

CAF ni gbogbo ipe nipa pe idajọ naa ko tẹ wọn lọrun ni awọn ti wọgile, ti wọn si ni anfani lati pe ẹjọ kotẹmilọrun.