Naijiria, orílẹ̀èdè méjìlá mí-ìn darapọ̀ mọ́ BRICS, fún ìgbédìde ọrọ̀ ajé

Awon alẹnulọrọ nibi ipade BRICS ọdun 2024

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Nibi ipade BRICS ọdun 2024.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bi ipade ẹgbẹ BRICS ṣe n pari lorilẹede Russia, Naijiria atawọn orilẹede mejila mi-in ti darapọ mọ agbekalẹ naa.

Orilẹede mẹtala ni ẹgbẹ naa gba laaye lati darapọ mọ BRICS.

Wọn pinnu lati ma ṣe gba ilu kankan wọle gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ taara ni 2024.

Iṣẹ waa ku sọwọ awọn orilẹede mẹtala naa lati wa ọna ti wọn yoo fi di ọmọ ẹgbẹ gangan.

Awọn orilẹede ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ BRICS gangan ni

  • Brazil
  • Russia
  • India
  • China
  • South Africa
  • UAE
  • Iran
  • Egypt
  • Ethiopia

Àwọn tí wọn darapọ̀ láì kí í ṣe ọmọ ẹgbẹ́ tààrà ni:

  • Algeria
  • Belarus
  • Bolivia
  • Cuba
  • Indonesia
  • Kazakhstan
  • Malaysia
  • Nigeria
  • Thailand
  • Turkey
  • Uganda
  • Uzbekistan
  • Vietnam

Kí ni ìtumọ BRICS àti bí wọ́n ṣe dá a sílẹ̀?

Ni ọdun 2021, onimọ nipa ọrọ aje kan, Jim O'Neil, lati ‘ Goldman Sachs’, ṣe ẹ̀dá ọrọ kan, BRIC, eyi to duro fun Brazil, Russia, India ati China.

Awon orilẹede yii jẹ olowo nla atawọn ti ọrọ aje wọn n dagba daadaa nigba naa. Jim O’Neil waa gbe afojusun kan kalẹ nigba naa, o ni awọn orilẹede yii le di aṣiwaju ninu ọrọ aje to ṣe daadaa julọ lagbaaye nigba ti yoo ba fi di ọdun 2050.

Nigba to di 2006, awọn orilẹede mẹrin yii pinnu lati wa papọ, won si di ohun ti a mọ si ẹgbẹ BRIC. South Africa darapọ mọ wọn ni 2010, o si di BRICS.

Lapapọ, eeyan to wa ninu BRICS jẹ 3.24 billion, owo to si n wọle fun wọn lapapọ je $26trn. Eyi ti i ṣe ida mẹrindinlọgbọn (26%) owo to n wọle lagbaaye.

Ṣugbọn o, gẹgẹ bi igbimọ Atlantic ṣe wi, ida mẹẹẹdogun (15%) ni awọn orilẹede BRICS maa n ri gba ninu ẹtọ lati dibo lọdọ ajọ ayanilowo agbaye, International Monetary Fund (IMF).

Kí ni BRICS yóò mú wá lọ́dún yìí?

Yatọ si pe yoo ṣe anfaani fun Vladimir Putin lẹka oṣelu, yoo tun jẹ ki olori naa le yi awọn eeyan rẹ lọkan pada, pe ki wọn gba nnkan mi-in yẹwo, yatọ si fifi dọla sanwo lagbaaye.

"Ọpọlọpọ iṣoro ti Russia n koju lẹka ọrọ aje lo ni i ṣe pẹlu okoowo lẹnu ibode ilu ati ilana owo sisan. Pupọ rẹ lo si kan owo Dọla ilẹ America.’’ Weafer lo sọ bẹẹ.

" Ipa kekere kọ ni ilẹ America ni lori okoowo agbaye, nitori owo dọla wọn ti wọn n lo kaakiri. Ohun ti Russia fẹẹ ṣe ni lati gba agbara lọwọọ dọla.

O fẹ kawọn orilẹede BRICS wa ọna miran ti okoowo pẹlu awọn ilu mi-in yoo fi ṣee ṣe lai lo dọla, euro abi owo awọn orilẹede meje ti wọn n pe ara wọn ni G7.

Ki wọn si ma le yọ awọn orilẹede naa lẹnu.

‘Ìdí tí nǹkan kò fi lè jọ ara wọn ní BRICS’

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn awoye n ṣalaye pe awọn ibi kan wa ti nnkan ko ti jọra wọn ninu BRICS. Wọn ni ero wọn ko le jọra wọn rara.

" Ni awọn ọna kan, nnkan to daa lo jẹ fun apa Iwọ-Oorun, pe China ati India ko ni I fimọ ṣọkan laye, wọn ko ni i gba funra wọn.

Nitori bi awọn mejeeji yii ba fi le tẹra mọ ajọṣepọ wọn, BRICS yoo lapa gan-an."

Jim O'Neill, lo sọ bẹẹ.

" China ati India n sa ipa wọn pe ki ija ma de, ki wọn ma si koju ara wọn lọpọ igba. Lati ri i daju pe wọn jọ ṣiṣẹ pọ lẹka ọrọ aje yii ki i ṣe ohun to dẹrun rara."

Afojusun O’Neill ni Ibẹrẹ sẹnturi yii ni pe o yẹ ki BRIC wa lara awọn orilẹede mẹrin to yẹ ni aarin- gbungbun ọrọ aje agbaye.

Ṣugbọn BRIC pada da ọmu iya ẹ gbe, nigba ti South Africa darapọ mọ wọn to si di BRICS.

Wọn gbiyanju lati din agbara awọn orilẹede meje ti ọrọ aje wọn lagbara ju lagbaaye ku, awọn G7 ti i ṣe: Canada,France, Germany, Italy, Japan, UK ati US.

Ki i ṣe China ati India nikan ni ọrọ wọn ko jọra, bẹẹ naa ni Egypt ati Ethiopia ko gbọra wọn ye.

Bi wọn si ti n sọ asọye laaarin Iran ati Saudi Arabia to, orogun ti wọn n ba ara wọn ṣe ju ti ori ẹni lọ.

Bi Russia ṣe n koro oju si ọrọ awọn alagbara yii, bẹẹ ni india n fa oju wọn mọra lẹka ọrọ aje.

Iṣẹ ti wọn lo wa niwaaju Vladimir Putin bayii ni lati gboju kuro nibi awọn kudiẹ-kudiẹ ti ko jẹ ki ẹnu ko, ko jẹ ki iṣọkan wa, ko si jẹ ki Russia ati awujọ agbaye mọ pe mọ pe ilu oun ko dẹyẹ si wọn.