Báǹkì àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN sọ̀rọ̀ tuntun lórí awuyewuye gbèǹdéke fún owó àtijọ́ tó tún gbòde

Oríṣun àwòrán, CBN
Ọpọ iroyin nipa fifofin de owo naira tẹlẹ lo ti gba ori ayelujara kan, ti ibẹruboju si ti n ba ọpọ lasiko yii.
Iroyin ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 2024 yii ni ofin naa yoo bẹrẹ ti awọn ọmọ Naijiria ko si ni ni anfani lati na owo naira N200, N500 ati N1000 atijọ mọ fun karakata.
Bẹẹ ba gbagbe, ni ọdun 2023 ni ọpọ rogbodiyan bẹ silẹ nigba ti Banki apapọ kede owo naira tuntun.
Ọpọ awọn ileeṣẹ, ile epo ati bẹbẹ lọ ni wọn kọ lati gba owo naira naa ni ọdun to kọja.
Ṣugbọn bayii, CBN ti jẹ ko di mimọ pe iroyin ofege ni iroyin naa, to rọ awọn araalu lati ma kọ ibi ara si.
Ninu atẹjade to wa loju opo CBN lori ayelujara, wọn ni igbẹjọ ile ẹjọ to ga ju ni Naijiria ni ọjọ kọkandinlọgbọn ni ọdun 2023 ti paṣẹ pe ki wọn ma na owo naira tuntun ati atijọ lọ.
Agbẹnusọ CBN, Sisi Ali, Hakama ni CBN ti paṣẹ fun gbogbo awọn ẹka rẹ lorilẹede Naijiria lati tẹsiwaju ninu gbigba owo naira tuntun ati ti atijọ.
“Ẹ ma gbagbe pe ile ẹjọ to ga ju lorilẹede Naijiria ti paṣẹ pe ki owo naira N200, N500 ati N1000 ni owo naira , ti os i jẹ owo ti Banki apapọ yoo ma gbe sita fun lilo awọn araalu.
“A n rọ awọn araalu lati yago fun awọn iroyin ofege to ni ki a ko ni gba owo naira atijọ mọ ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila.
“A tun n rọ awọn araalu pe ki awọn ma gba owo naira atijọ lọ ninu karakata ojumọ wọn.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Igbẹjọ ile ẹjọ lori owo naira tuntun
Awọn gomina mẹwaa lorilẹede Naijiria lo pe ijọba apapọ lẹjọ lati tako ilana siṣe eto pasipaarọ owo naira tuntun.
Ninu idajọ ti igbimọ onidajọ ẹlẹni meje naa, ti adajọ Emmanuel Agim ko sodi gbe kalẹ, wọn kede pe ki awọn ọmọ Naijiria maa na Naira atijọ ati tuntun lọ.
Idajọ naa si lo n lodi si asẹ ijọba apapọ pe Naira tuntun nikan ni ka maa na nilẹ yii.
Ọjọ kọkanlelọ̀ọgbọn oṣu kini ọdun 2023 ni banki apapọ CBN kọkọ fi ṣe gbedeke paṣipaarọ owo beba olodindi igba naira (N200), ẹẹdẹgbẹta naira (N500) ati ẹgbẹrun kan naira (N1000) ki wọn to sun un siwaju si ọjọ kẹwaa oṣu keji ọdun 2023 lẹyin ti ọpọ ọmọ Naijiria bẹrẹ si ni ke irora lori ilana eto naa.















