Wo ọkùnrin tó ń f'ojú àwọn tó ń mú àjẹ́ rí màbo ní Nàìjíríà

Aworan kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Jonathan Griffin àti Olaronke Alo
    • Role, BBC Trending
    • Reporting from, London & Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ọkunrin yii, Ọmọwe Leo Igwe, ko ni nnkan meji to gbe dani ju kikoju awon eeyan to n mu ọmọlakeji wọn ni ajẹ. Iṣẹ Igwe ni lati gbeja awọn eeyan ti wọn n foju ẹlẹyẹ wo lorilẹede Naijiria, o ni bi aye ṣe n fi wọn ṣẹsin le ba aye wọn jẹ, debi pe wọn tun n ju wọn loko pa.

“Mi o le mu un mọra mọ, kawọn eeyan kan dẹ maa pa eeyan ẹgbẹ wọn bo ṣe wu wọn,” Ọmọwe Igwe lo sọ bẹẹ fun BBC.

Oni kọ ni Igwe ti n ba ogun awọn to n koju ajẹ bọ, lẹyin to kẹkọọ gboye tan nipa ẹsin ni 2017, o bẹrẹ iṣẹ naa ni pẹrẹwu. O ti kọ ọpọlọpọ iwe to jinlẹ nipa awọn ajẹ.

BBC ti ri awọn pasitọ ti wọn gbe eto kalẹ lati koju awọn ti wọn pe ni ajẹ ni Naijiria, iru eyi ni ọmọwe Igwe sọ pe ko le ma ṣẹlẹ lorilẹede to gbagbọ ninu agbara aifojuri.

Ikilọ: Awọn nnkan kan wa ninu iroyin yii to le maa ba ọkan rẹ mu.

Ọmọwe Igwe tori ajẹ da ajọ kan kalẹ, eyi to wa fun dida aabo awọn eeyan ti aye mu lajẹẹ. Ilana to si n lo naa ni ibanisọrọ, imọ sayensi ati iwoye lati ṣẹgun irọ ati igbagbọ nipa ajẹ ni Naijiria.

Iṣẹ to gbe dani yii ki i ṣe fun Naijiria nikan, o ti gbe e de Ghana, Kenya, Malawi, Zimbabwe ati awọn ilu miran bẹẹ.

Aworan Ọmọwe Leo Igwe

Oríṣun àwòrán, Jonathan Griffin / BBC

Àkọlé àwòrán, Ọmọwe Leo Igwe

Ọkan lara awọn eeyan ti wọn ti ran lọwọ ni Naijiria ni ọkunrin kan, Jude, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn. Ninu oṣu kẹjọ ọdun yii ni wọn mu un lajẹẹ ni Benue, ti wọn si bẹrẹ si i lu u.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi Jude ṣe ṣalaye, o ni oun n lọ sibi iṣẹ ni laaarọ ọjọ naa, oun si pade ọmọkunrin kan to gbe kẹẹgi omi meji nla dani, loun ba si ki i pe o kare , ọkunrin to lagbara ni.

O ni inu ọmọ naa ko dun si ọrọ toun sọ nipa rẹ, ṣugbọn o ṣaa ba tiẹ lọ.

Afi bo ṣe ṣe diẹ ti ero pe le Jude lori, wọn to mẹẹẹdogun, wọn bẹrẹ si i juko lu u, ọmọkunrin to ki naa si wa lara wọn pẹlu.

“Awọn ọdọkunrin yẹn bẹrẹ si i lu mi, wọn fẹẹ dana sun mi” Jude lo ṣalaye bẹẹ.

Ki ni wọn tori ẹ fẹẹ pa Jude? Wọn ni o ti mu nnkan ọmọkunrin to ki laaaarọ lọ, wọn ni agbara ajẹ lo fi mu kinni naa. Ẹsun yii ya Jude lẹnu pupọ, nitori ki i ṣe otito rara.

Ki wọn maa sọ pe wọn mu nnkan ọmọkunrin kuro nibẹ ki i ṣe nnkan ajoji lawọn ibi kan nilẹ Africa.

Ọmọwe Igwe so pe Jude padanu iṣẹ rẹ ni banki nitori iṣẹlẹ yii, wọn si dẹyẹ si i debi to fi n gbe itiju rẹ kiri .

“Ihoho ni wọn mu Jude wa sibi, wọn ti i lu u, won ti ṣe e leṣe. Niṣẹ lakọkọ beere pe nibo ni wọn ti n ṣe iru eyi?”

Jude ree lapa osi, pẹlu Dooyum Dominic Ingye ti wọn jọ n gba ẹkọ lori ajẹ .

Oríṣun àwòrán, Advocacy For Alleged Witches

Àkọlé àwòrán, Jude ree lapa osi, pẹlu Dooyum Dominic Ingye ti wọn jọ n gba ẹkọ lori ajẹ .

Akọsilẹ sọ pe eeyan mẹjọ ni wọn ti ku ni 2024 yii nigba ti wọn mu wọn lajẹẹ

Ninu ọdun 2024 yii, akọsilẹ kan loju opo to n ri si ọrọ ẹlẹyẹ, sọ pe eeyan mẹjọ ni wọn ti ku nipasẹ bi wọn ṣe mu wọn lajẹẹ.

BBC ko ti i ṣe iwadii onka yii, ṣugbọn a ti gbe iroyin nipa awọn ti wọn ti pa latari ọrọ aje yii jade ri ni Naijiria ati lawọn ibomi-in.

Loju opo WhatsApp, olugbani-nimoran ni Omọwe Igwe jẹ

Ọpọlopọ ipinlẹ Naijiria lo ti ṣeto ẹka WhatsApp to si fi n polongo pe kaye fi awọn eeyan ti wọn n pe lajẹẹ lọrun silẹ .

Iru awọn eeyan wo lo wa loju opo ọhun? Awọn eeyan ti wọn setan lati la awọn eeyan mi-in lọyẹ ni. Wọn aa maa ṣafihan awon fidio ibi ti wọn ti n mu eeyan lajẹẹ, wọn aa si maa pese ọna abayọ fun wọn.

“A kan si Jude, a fowo ranṣẹ si i, a ba a wo egbo rẹ, a si mu un pada saarin awujọ” Igwe lo sọ bẹẹ.

Bakan naa ni wọn tun ni awọn yoo maa sanwo ileewe giga yunifasiti ti Jude n lọ, eyi ti igbagbọ wa pe yoo jẹ ko pada ṣoriire to ba kawe ọhun tan.

Ibẹru ajẹ pọ lọkan awon mi-in nile Africa, wọn gbagbo pe aye n bẹ, eeyan wa, wọn si le ṣe awọn ni ibi.

Bakan naa ni wọn gbagbọ pe aye lo n ṣeni ta a o ba lowo lọwọ, ta o ba bimọ, tabi ti aarẹ ara ba n bani ja.

Bẹẹ, ọpọ igba lo jẹ pe awọn ti wọn n foju aye ati ajẹ wo yii ko ni agbara okunkun kankan. Koda, ọmọde ni wọn maa n jẹ nigba mi-in tabi arugbo. O le jẹ ẹni toun funra rẹ n ko ni kọbọ lọwọ, to n gbele aye rẹ ninu aini ni wọn yoo maa pe ni ẹlẹyẹ.

Ikọ to n gbogun ti awọn to n mu ajẹ kiri yii gbe ipade kan kalẹ loṣu kẹjọ ọdun yii, to wa fun ọjọ ti won ya sọtọ fun ọrọ ajẹ.

Omowe Olaleye Kayode, olukọ agba lẹka ẹsin ibilẹ ni Yunifasiti Ibadan, ṣalaye pe, igbagbọ awọ eeyan ni pe awọn ajẹ jẹ okan lara iṣẹda Eledumare, lati ri si ohun to ba n ṣẹlẹ laye. O ni aimọkan lo n ṣe awọn ti won n dọdẹ ajẹ kiri.

Olaleye sọ pe ẹsin ajeji lo n jẹ kawọn eeyan maa sọrọ tako ajẹ, awọn bii ẹsin Islam ati Kristẹniti, ṣugbọn o ni awọn oniṣẹṣe naa maa n gbogun ti ajẹ nigba mi-in.

Ṣọọṣi kan ree to n kede pe ajẹ gbọdọ ku

Aworan eto ṣọọṣi ati pasitọ to n kede pe ajẹ gbọdọ ku.

Oríṣun àwòrán, Advocacy for Alleged Witches

Àkọlé àwòrán, Eto ṣọọṣi to ni ajẹ gbọdọ ku yii pada waye.

Nigba ti Ọmọwe Igwe ri patako yii, o kọ ọpọlọpọ iwe ifisun ranṣẹ si awọn alaṣẹ ibẹ, o si kọ awọn mi-in sori ẹka ayelujara atawọn ẹká iroyin adugbo, o fẹ ki won fagi le e Ṣugbọn wọn pada ṣe eto naa, ikọ Igwe si ran awọn eeyan lọ sibẹ lati wo ohun ti wọn fẹẹ ṣe gan-an.

BBC naa gbiyanju lati ba ṣọọṣi yii sọrọ, ṣugbọn wọn ko ti i dahun.

Ko sẹnikan to ku nibi eto naa ti wọn ṣe nipinlẹ Imo, ṣugbọn ajẹ gbọdọ ku ti won kede yẹn le di wahala, Igwe lo sọ bẹẹ.

“ Ohun ti a mo Jesu fun ni pe yoo yọ ẹmi Eṣu jade lara eeyan, ṣugbon ko ni i pa ẹni ti ẹmi naa wa lara rẹ. Ẹni to ba n pa ajẹ n lodi si ẹkọ Bibeli ni,” Pasitọ kan, Julius Osimen, lo sọ bẹẹ nipinlẹ Eko.

Ọmọwe Igwe to gbe iṣẹ yii dani naa ṣalaye ohun ti oju rẹ ti ri. O ni wọn ti lu oun nigba mẹta ri nitori oun n da si ọrọ awọn eeyan ti won mu lajẹẹ, iyawo atawọn ọmọ oun si maa n kaya soke pelu ibẹru pe ki nnkan ma ṣe oun ni.

Ni 2021, ajọ UN Human Rights Council, da aba kan to n gbogun ti bi wọn ṣe n da awọn kan laamu, ti wọn n pe wọn lajẹẹ, ṣugbọn sibẹ naa, iwa yii ko dawọ duro titi de India ati agbegbe Papua New Guinea.

“Ko dẹrun lati ṣẹgun awọn to n gbogun ti eeyan ẹgbẹ won yii, ṣugbọn a ko tun gbọdọ ri i bii ara aṣa wa.

“Aṣa wa kọ ni pe ka pa awon obi wa, aṣa wa si kọ ni pe ka maa pa awọn alaiṣẹ.”

Bẹẹ ni Leo Igwe wi.