Mo ti ṣetán láti kó wá sílẹ̀ Áfíríkà - Idris Elba

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Thomas Naadi
- Role, BBC News, Accra
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Gbajúmọ̀ òṣèré ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Idris Elba ti kéde èròńgbà rẹ̀ láti kó wá sí ilẹ̀ Áfíríkà láàárín ọdún mẹ́wàá sí àsìkò yìí.
Elba lásìkò tó ń bá BBC sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé èròńgbà òun yìí wáyé lójúnà àti ṣe ìrànwọ́ sí ẹ̀ka eré ilẹ̀ Áfíríkà.
Òṣèré, ẹni ọdún méjìléláàádọ́ta náà ní òun ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti kọ́ ilé sinimá sí erékùṣù Zanzibar ní orílẹ̀ èdè Tanzania àti òmíràn sí Accra, olú ìlú orílẹ̀ èdè Ghana.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú London ni wọ́n bí Elba sí, ó ní àsopọ̀ mọ́ ilẹ̀ Áfíríkà nítorí ọmọ orílẹ̀ èdè Ghana ni ìyá rẹ̀, tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ Sierra Leone.
Ó ní ó ṣe pàtàkì kí ìran Áfíríkà le máa sọ ìtàn ara wọn fúnra wọn látara sinimá àti pé èyí wà lára ohun tó ń fún òun ní ìwúrí láti gbé ìgbésẹ̀ náà.
“Mo máa rò ó láti wá máa gbé ibí, kìí ṣe ìrònú gan, ó máa ṣẹlẹ̀ ni,” Elba sọ lásìkò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe lórí ìdásílẹ̀ àwọn ilé sinimá ọ̀hún.
“Mò ń rò ó láti kó wá láàárín ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá sí àsìkò yìí. Mo fẹ́ ṣe ìrànwọ́ sí ẹ̀ka eré sinimá ní Áfíríkà, mi ò sì le ṣe é láti ilẹ̀ òkèrè. Mo nílò láti wà ní ilẹ̀ Áfíríkà ni.”
Ó ní àmọ́ ohun kò ní yan orílẹ̀ èdè kan pàtó láti máa gbé.
Ó sọ pé òun yóò máa gbé ní Ghana, Sierra Leone, Tanzania àti gbogbo ibikíbi tí wọ́n bá ti ń fi eré sinimá kọ ìtàn.
Ohun kan tó jẹ ẹ́ lógún báyìí ni láti ni ilé eré ní Accra lọ́jọ́ kan.
Elba, tó kó ipa Nelson Mandela nínú fíìmù Long Walk to Freedom lọ́dún 2013, gbàgbọ́ pé ilẹ̀ Áfíríkà yẹ kó wà ní ojútáyé káàkiri àgbáyé nípa eré fíìmù ṣíṣe àti gbogbo nǹkan tó rọ̀ mọ́ ṣíṣe àfihàn rẹ̀ fún aráyé.
Ó ní àfojúsùn ni pé bí àwọn èèyàn tó máa ń wo fíìmù káàkiri àgbáyé ṣe mọ ìyàtọ̀ láàárín ìlú New York àti Los Angeles láì dé àwọn ìlú náà rí ni àwọn èèyàn yóò mọ̀ nípa ilẹ̀ Áfíríkà.
“Ẹ̀ka tó lágbára ni ẹ̀ka eré fíìmù, kìí ṣe ní Ghana nìkan bíkòṣe gbogbo ilẹ̀ Áfíríkà.
“Tí ẹ bá wo àwọn eré tó ní ṣe pẹ̀lú Áfíríkà, àwọn nǹkan tó ní ṣe pẹ̀lú bí wọ́n ṣe kó wa lẹ́rú, ogun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n máa ń ṣàfihàn àmọ́ tí a bá de Áfíríkà, ẹ máa ri pé àwọn ìtàn yìí kìí ṣe òótọ́.”
“Nítorí náà ló ṣe pọn dandan láti sọ ìtàn nípa àwọn àṣà wa, ìṣe wa, èdè wa, àtàwọn nnkan tó yà sọ́tọ̀ fúnra wa nítorí àgbáyé kò mọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí.”
Pẹ̀lú bí ẹ̀ka eré fíìmù Nàìjíríà, Nollywood ṣe ń gbé ọ̀pọ̀ fíìmù jáde lọ́dún kan, fíìmù wà lára nǹkan tí Nàìjíríà ń kó lọ sílẹ̀ òkèrè.
Bákan náà ni ìgbàgbọ́ wà pé àwọn òṣèré ilẹ̀ Áfíríkà máa ń ṣe fíìmù tó múná dóko.
Elba ti sọ nígbà kan rí pé àwọn òṣèré tó dáńtọ́ wà lẹ́ka fíìmù ilẹ̀ Áfíríkà àmọ́ kò sí ohun èlò tó pójú owó fún wọn.
Ìjábọ̀ àjọ UNESCO ọdún 2022 fìdí ọ̀rọ̀ Elba yìí múlẹ̀.
UNESCO ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbéga bá ìpèsè fíìmù ní Áfíríkà, síbẹ̀, àìsí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó péye fáwọn òṣèré, àìsí ilé ẹ̀kọ́ tó pójú owó fáwọn òṣèré àti jíjí iṣẹ́ oníṣẹ́ wà lára nǹkan tó ń kó á ẹ̀ka náà.
Elba gbàgbọ́ pé pẹ̀lú àtìlẹyìn tó péye àti ìdásí ìjọba, nǹkan máa yàtọ̀ lẹ́ka fíìmù ilẹ̀ Áfíríkà.
“A ní láti dókoòwò sí sísọ ìtàn wa ìdí ni pé bí ẹ bá ti rí mi, ẹ ti rí kékeré ara yín, ìyẹn sì jẹ́ ìwúrí fún wa.”












