Èèyàn méje ló kú níbi ilé tó dà wó l’Abuja - FEMA

Aworan ọga FEMA,Abdulrahman Muhammed ati ibudo iṣẹlẹ ile wiwo naa

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police Force

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ko si ẹni to ku ninu iṣẹlẹ yii, ọga ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri l'Abuja, Federal Emergency Management Agency (FEMA), Abdulrahmon Muhammed, sọ pe eeyan meje ku ninu ijamba naa.

Nigba to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun BBC, Abdulrahmon sọ pe ki i ṣe eeyan ogoji lo ku bi awọn kan ṣe n gbe e kiri, bi ko ṣe meje.

''Eeyan marun-un ku nibi, ẹnikan ku lọhun-un yẹn, wọn n gbe ọkan lọ sileewosan loun naa ku.

''Awọn meji wa nileewosan ninu awọn ti ile wo le lori, ti wọn n gba itọju bayii.

''Awọn eeyan ti wọn waa ji irin Iron rod ko ni ile wo mọ lori.

''Wọn ti mọ pe awọn Development control ko ni i wa ni Satide ati Sannde ni wọn fi wa lati waa ji irin, irin yẹn ni wọn n ko ti ile fi wo mọ wọn lori.''

Bakan naa ni Ọga FEMA yii fidi ẹ mulẹ, pe awọn to n kọ ile si Estate naa ko gba aṣẹ ikọle lọwọ ijọba.

O ni wọn ko kọ awọn ile naa sibi to tọ lo jẹ ki ijọba maa wo wọn lulẹ.

Lara awọn ile ti wọn ti wo tẹlẹ ni eyi ti awọn to fẹẹ ji irin tun lọ yii, ti irin ti wọn fẹẹ ji fi ran wọn sọrun gẹgẹ bo ṣe sọ.

BBC ri ọpọ ile ti wọn ti kọ si esteeti naa ti ijọba ti bẹrẹ si i wo lulẹ, ati awọn mi-in ti wọn ṣe àmì si lati wo pẹlu.

Ọ̀pọ̀ èèyàn hà sí abẹ́ ilẹ̀ lẹ́yìn tí ilé dà wó ní Abuja

Ileeṣẹ ọlọpaa olu ilu Naijiria to wa niluu Abuja ti fidi ẹ mulẹ, pe iṣẹ idoola ẹmi awọn eeyan to ha si abẹ ile nla kan to dawo l’Abuja ṣi n lọ lọwọ.

Atẹjade ti SP Josephine Adeh, Alukoro ọlọpaa Abuja, fi sita laaarọ ọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024, fidi eyi mulẹ.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe wi, ile to wo naa wa ni Vidaz Estate, lagbegbe Sabon Lugbe, Abuja.

Eeyan marun-un ni wọn ni awọn ti doola ẹmi wọn bi ile ọhun ṣe dawo.

SP Adeh sọ pe awọn ko ti i ri oku eeyan kankan gbe jade ninu ile ọhun bi iṣẹ ṣe n lọ lọwọ.

Ṣaaju ni ijọba Naijiria ti kọkọ wo ile naa lulẹ, gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ṣe sọ.

O ni wọn wo ile naa nitori pe ibi to lodi sofin ni wọn kọ ọ si.

Wiwo ẹlẹẹkeji to wo yii ko ṣẹyin awọn to n wọ ibẹ lọọ tu irin, ji irin atawọn nnkan mi-in ko nibẹ.

Eyi lo gba agbara lọwọ ile naa to si mu ko dawo bi ọlọpaa ṣe sọ.

O waa rọ awọn eeyan lati fi agbegbe naa silẹ, ki wọn wa aabo to peye fun ẹmi ara wọn.

Ile naa pelu ami ti ijọba kọkọ ṣe si i lati wo o.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police Force.

Àkọlé àwòrán, Ile naa pelu ami ti ijọba kọkọ ṣe si i lati wo o.