Ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn oníbárà sí àtìmọ́lé ní Abuja

Beggers

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn to n tọrọ bara niluu Abuja ti bẹrẹ igbesẹ lati dena ileri ti minisita fun FCT, Nyesom Wike ṣe pe ijọba yoo maa fi ṣikun ofin mu wọn bẹrẹ lati ọla ọjọ Aje.

Ṣaaju ni Wike ti kọkọ sọ pe oun ko fẹ ri awọn to n tọrọ baara niluu naa mọ, o si ṣeleri pe ijọba yoo ma ti eyikeyi ti ọwọ ba tẹ ninu wọn mọle.

Wike sọ pe ilu Abuja kii ṣe ibi to yẹ ki awọn to n ṣe ‘bambiala’ maa lo lati tọrọ owo, ati pe ẹni ti ilu naa ko ba san fun ki wọn gba abule wọn lọ.

Awọn onibara n bẹbẹ

Ẹwẹ, ni bayii to ku wakati diẹ ki igbesẹ ijọba naa bẹrẹ, awọn onibara ọhun ti bẹrẹ si n ke si awọn alẹnulọrọ lawujọ lati ba awọn da si ọrọ ọhun ki Wike ma ba gba ounjẹ lẹnu wọn.

Ẹgbẹ awọn onibara, Special Needs Association, ti ke si awọn onibara lati wọ inu awẹ ati adura lọ ki Wike ma ba le mu ileri rẹ naa ṣẹ.

Ẹgbẹ naa tun ke si awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin, ile aṣojuṣofin, awọn lọbalọba atawọn mii lawujọ lati ba awọn da si ọrọ naa.

Aarẹ ẹgbẹ ọhun ni ariwa, Ọmọba Sulaiman Ibrahim, sọ fun BBC pe minisita fun FCT gbọdọ tun ero rẹ pa lori lile awọn onibara kuro niluu Abuja.

O ni botilẹ jẹ pe ohun ti Wike sọ ba ofin mu ti awọn ko si ni ṣẹ si ofin, o gbọdọ boju aanu wo awọn alaini to n tọrọ bara.

Ṣaaju ni Wike ti kọkọ ni awọn kan wa lara awọn onibara naa ti kii ṣe alaabọ ara amọ to n fi iṣẹ naa boju lati ṣiṣẹ ibi.

Sulaiman sọ pe “ogi yẹ ki wọn pe wa si ipade lati mọ ohun ti a n dojukọ ati eredi ti a fi n tọrọ bara, ki ijọba si le wo bo ṣe le ran wa lọwọ.”

O wa rọ awọn onibara lati maṣe gbe igbesẹ kankan bayii titi di igba ti abajade ipade ẹgbẹ naa pẹlu awọn ti ọrọ kan lati yanju ọrọ ọhun yoo pari.

O tun rọ awọn asọfin, awọn gomina atawọn lọbalọba lati maṣe kọ awọn silẹ lasiko iṣoro yii.