Ọlọ́pàá lu òṣìṣẹ́ NSCDC lálùbami ní Osun, ìwádìí bẹ̀rẹ̀

Osun

Oríṣun àwòrán, NSCDC Osun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ija ti waye laarin oṣiṣẹ ọlọpaa ati oṣiṣẹ ajọ NSCDC nipinlẹ Osogbo.

Lati Ọjọru ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ oṣiṣẹ ajọ NSCDC nipinlẹ Ọṣun ti wa latimọle ọlọpaa lẹyin ti wọn fi lilu da batani si i lara tan, ọsan ọjọ karunlelogun osu yii ni wọn to tu u silẹ.

Ohun to ṣẹlẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ ni pe, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Iṣẹgun, iyẹn ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹwaa yii, ni awọn kan ti wọn wọ aṣọ ankara wa mọto Sienna niwakuwa wọn inu adugbo Elizabeth Estate, niluu Oṣogbo.

Ọlọpaa kan lati ìpínlẹ mii lo fẹ wa ṣe iṣẹ ti ko bofinmu ṣugbọn ti oṣiṣẹ wa ko gba fun un -NSCDC

Wọn ba awọn oṣiṣẹ NSCDC ti wọn n ṣọ Estate naa lẹnuu geeti, wọn ni ọlọpaa lawọn, wọn si sọ pe ṣe lawọn wa lati fi pampẹ ọba gbe ọdaran kan ninu ibẹ ati pe ipinlẹ Ọyọ lawọn ti wa.

Awọn NSCDC naa beere pe ki wọn fi kaadi idanimọ wọn han pe loootọ ọlọpaa ni wọn, ṣugbọn ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun wa pe, ṣe lawọn ọlọpaa yii bẹrẹ sii gboju aagan si awọn oṣiṣẹ NSCDC yii.

Wọn ni agbara ati aṣẹ wo ni wọn ni lati beere ami idanimọ awọn.

Bayii ni wọn binu lọ lọjọ naa, ṣugbọn ipadabọ Abija ni wọn fi ọrọ naa ṣe lọjọru, awọn ọlọpaa bii mẹẹdogun ni wọn pada wa sibẹ.

A gbọ pe wọn kọkọ lu NSCDC ti wọn ba lẹnu geeti nla naa lalubami, wọn fa aṣọ rẹ ya, wọn si fi ṣekẹṣẹkẹ de e lọwọ, wọn si wọ ọ lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Ataọja, niluu Osogbo.

Lati ibẹ ni wọn ti gbe e lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa, gẹgẹ bii ohun ti a gbọ.

Atẹjade kan lat ọwọ agbẹnusọ ajọ NSCDC ipinlẹ Osun, Kehinde Adeleke, sọ wi pe, gbogbo igbiyanju awọn lọgalọga ajọ naa lati gba ọkunrin yii silẹ lagọ awọn ọlọpaa lo ja si pabo, afigba to lo ọjọ meji ni atimọle wọn.

Kehinde Adeleke ni fọnran fidio to wa nita fi han kedere bi awọn ọlọpaa yii ṣe lu ọmọ ajọ NSCDC, idi si niyẹn tawọn fi n beere fun idajọ ododo lori ọrọ naa nitori olootọ kan ko gbọdọ ku sipo ika.

Iwadii ti n lọ lọwọ - Ileeṣẹ ọlọpaa

Ṣugbọn agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Yẹmisi Ọpalọla ti fesi ninu atẹjade kan pe ọkunrin oṣiṣe NSCDC naa lo kọkọ lu ọlọpaa meji, ko too di pe awọn ọlọpaa yooku kapa rẹ.

Yatọ si pe wọn lu ọlọpaa, Opalola fi kun pe awọn oṣiṣẹ NSCDC naa tun jo taya ọkọ awọn ọlọpaa ọhun.

Wayi o, o ni iwadii ti n lọ lọwọ lori ọrọ naa.