Ìwádìí àwọn fijilanté tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ṣekúpa ọkùnrin kan ní Kwara bẹ̀rẹ̀

Kọmiṣanna ọlọpaa Kwara
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọwọ sinku ọlọpaa Kwara ti tẹ awọn afurasi marun-un kan lori iku gende kunrin kan, Adebayo Olanrewaju Mathew.

Awọn afurasi marun-un yii ni a gbọ pe fijilante meji wa ninu wọn.

Ọkunrin naa jẹ ẹni ọdun mẹrindinlaadọta, o si n gbe lagbegbe Ita-Elepa ni ilu Ilorin.

Iwadii tun fihan pe, oloogbe na jẹ akẹkọọ gboye imọ oṣelu nile ẹkọ fasiti Ilorin.

BBC News Yoruba gbọ pe iṣẹlẹ naa waye lalẹ ọjọ Aje, ogunjọ osu Kẹwaa ọdun 2024 ati pe olóògbé náà ni wọ́n ní àwọn ẹ̀sọ́ aláàbò fijilanté la nǹkan bò nígbà tóún padà sílé rẹ̀ láti òde.

Ohun tí ó ṣẹlẹ̀

Awọn kan ni agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye ti wọn ni ka fi orukọ bo awọn laṣiri sọ pe oloogbe naa ni awọn ẹsọ alaabo fijilante la nnkan boo nigba ti oun pada sile rẹ lati ode.

Wọn sọ pe awọn fijilante da arakunrin naa duro, wọn si fọrọ waa lẹnu wo lori ibi to ti n bọ, sugbọn rogbodiyan to jasi iku rẹ yii bẹ silẹ nigba ti ohun to sọ fun wọn ko tẹ wọn lọrun.

"Awọn fijilante da Adebayo duro ni nnkan bi ago mẹwaa alẹ ọjọ Aje, sugbọn ariyanjiyan sẹlẹ laarin wọn to si jasi iku rẹ.

"Igba ti wọn la nnkan mọ ọn tan, wọn fi kalẹ sibi iṣẹlẹ naa, wọn si ba ti wọn lọ"

Ohun tí ọlọ́pàá sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà

BBC News Yoruba kan si ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara lati fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa Kwara, DSP Ejire Adetoun Adeyemi ṣalaye pe loootọ ni ọwọ ọlọpaa ti tẹ eeyan marun-un lori iṣẹlẹ ọhun ati pe wọn ti wa ahamọ awọn.

O ni wọn ti ko wọn lọ si ẹka ọlọpaa to n ṣe iwadii, iwadii to peye si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

O fi kun pe alẹ ọjọ ọjọru ni wọn ko awọn afurasi naa wa ti iwadii sì ti bẹrẹ lọgan.