Àwọn Kristẹni kan gbàgbọ́ pé Ọlọ́run ló rán Trump wá

Aworan Aarẹ Donald Trump ati awọn olori ẹṣin ti wọn gba adura ni White House, ni oṣu kẹsan an ọdun 2017

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Cecilia Barría
    • Role, BBC News Mundo
    • Reporting from, Oklahoma
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Iṣẹju diẹ ṣaaju isin ni Ile-ijọsin Baptisti Grace Reformed ni Elgin, ilu ti o to eeyan ẹgbẹrun meji to n gbe ninu rẹ ni guusu Oklahoma, Olusọagutan Dusty Deevers, 36, farahan, pẹlu ẹrin nla.

O kí ẹgbẹ kan to to ọgọrun-un [100] awọn ọmọ ijọ, paapaa awọn ìdíle alawọ funfun to ní ọmọ pupọ̀.

Ni ọna abawọle ṣọọṣi, awọn iwe kekere kan wa ti o ni aworan ohun tí o da bí ọmọ ti ka oní ẹmí lara.

“Bí ẹ ṣe n ka ìpínrọ yi, wọn pa awọn ọmọ mẹta lọna ti ko ba ofin mu ninu ọlẹ àwọn ìya wọn ní Orílẹ-ede Amẹrika, o n tọka si iṣẹyun gẹgẹ bí “ìpakupa” lakooko wa.

Iṣẹyun, pẹlu ọrọ-aje ati iṣiwa, jẹ ọkan ninu awọn iṣoro pataki nipa ni ibo ti n bọ ni Ọjọ karun un, Oṣu kọkanla.

Awọn iwe pẹlẹbẹ wọnyi jẹ ami ti o han gbangba ti bii iṣelu ati ẹsin ṣe darapọ lati pese awọn oludibo Protẹstant ni Amẹrika ti wọn gbaradi lati yan aarẹ tuntun.

Aworan

Deevers – Sẹnẹtọ ile-igbimọ aṣofin ti wọn bi ni Elgin ni awọn ọmọ mẹfa, oye Masters ninu awọn ẹkọ ẹsin ati iṣowo ohun-ini - waasu ni awọn ọjọ Aiku lati ori pẹpẹ; ṣugbọn ni awọn ọjọ Aje, o le rii nibi ti o ti gbe fun kalẹ ni Kapitolu Oklahoma.

O wọpọ ni Oklahoma fun awọn oloselu lati ni ipo ni awọn ile ijọsin agbegbe wọn tabi ni ajọsepọ to lagbara pẹlu wọn.

Iru aṣaaju meji yẹn ninu iṣelu ati ẹsin ni a rii ni igbagbogbo ni eyi ti a pe ni Belt Bibeli ti Amẹrika, eyiti Elgin wa ninu rẹ: agbegbe ti o tobi pupọ ti o si jẹ ọkan ninu awọn ipinlẹ Protẹstant ti Oloṣelu ijọba, Aarẹ tẹlẹ, Donald Trump ti jawe olubori nin u eto idibo to kọja

Ọlọrun ati orilẹ-ede n sisẹ papọ ninu oṣelu Oklahoma nitori wọn kristeni Konsafetifu gbagbọ pe ọna ibilẹ ati aṣa wọn wa labẹ ewu lati ọwọ osi ominira.

Aworan

Ajọṣepọ oṣelu ati ẹsin

Pasitọ Dusty Deevers
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ki ni o ro nipa isin naa?" Deevers beere lọwọ mi, ni igbiyanju akọkọ lati ṣawari igbagbọ ẹsin mi.

Lẹyin ibaraẹnisọrọ fun igbapipẹ, o sọ fun mi nipaeto oselu rẹ lati fopin si iṣẹyun, imukuro awọn aworan iwokuwo ati ki o dẹkun gbigba ti owo-ori ati owo-ori ohun-ini.

Ṣugbọn, afojusun Deevers jẹ ero lati sọ Amẹrika di orilẹ-ede onigbagbọ kristẹni.

Lati le ṣe yii, o ṣe pataki de awọn ipo nla ninu oṣelu.

"Ṣe o fẹ lati yi White House si ijọba Ọlọrun?" Mo beere lọwọ rẹ. O dahun pe: “Ohun gbogbo lori ilẹ aye ni ijọba Ọlọrun.

"A ni lati yi awọn ẹya agbara pada," Oṣiṣẹ ile-igbimọ aṣofin Republican salaye.

Deevers ko paapaa lero ni kikun ni ipoduduro nipasẹ Trump bi awọn oluso-aguntan igbanu Bibeli miiran ṣe.

“Trump n tẹ Ẹgbẹ Republican si apa osi,” o jiyan.

Ṣiṣẹ papọ pẹlu Deevers, Aaron Hoffman, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, baba awọn ọmọbirin marun - n murasilẹ lọwọlọwọ lati jẹ oluso-aguntan ti ile ijọsin Baptisti tuntun ni Oklahoma - gbagbọ pe sisọ laini laarin ile ijọsin ati ipinlẹ ko ni oye.

"Ko si ọna lati ge asopọ to wa laaarin Kristiẹniti ati iselu," o sọ fun mi pẹlu omije ni oju rẹ nitori "Awọn Amẹrika ti gbagbe Kristi".

Idari ẹlẹsin

Aworan Susie Stephenson,

Njẹ ogun aṣa yii ni ipa lori igbesi aye ojoojumọ fun awọn eniyan lasan bi? Idahun si jẹ bẹẹni.

Ni ọdun yii nikan, awọn ipinnu iṣelu ti o ni ipa ẹsin ni wọn ti ṣe ni o kere ju awọn ipinlẹ Bibeli Belt mẹta.

Ni Louisiana, gbogbo awọn yara ikawe ni awọn ile-ẹkọ ni wọn palaṣẹ lati fi awọn ofin mẹwa si ara ojiri wọn.

Ni Oklahoma, oṣiṣẹ giga ti eto-ẹkọ, Ryan Walters, di akọle fun ọpọ ileeṣẹ iroyin nigba to kede pe ẹkọ nipa bibeli jẹ ọranyan fun awọn akẹkọọ ni awọn ile ẹkọ ijọba, ti o si fa ariyanjiyan kaakiri.

Pẹlu Oklahoma, to jẹ ọkan ninu awọn ipinlẹ pẹlu aito awọn olukọ ni orilẹ-ede naa, iroyin naa ni awọn olukọ kan to tẹwọgba nipasẹ pe ọpọlọpọ awọn olukọ sọ pe itọsọna naa lodi si ominira ẹsin.

Susie Stephenson, ẹni ọdún mẹrinlelogoji: “A gbọdọ ya ṣọọṣì sọtọ kuro ninu ìjọba.

O bu ẹnu atẹlu Walters, Onigbagbọ Republican kan ti o pe awọn olukọ Oklahoma ni “ẹgbẹ apanilaya”.

Walters, ti o di ipo mu bayii, kọ ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC.

Ọpọ awọn obi lo binu si ipinnu naa. Ọkan ninu wọn, Erika Wright, oludasile Oklahoma Rural Schools Coalition.

"Dipo ti gbigbe Bibeli le wa lori, o yẹ ki o fi ye si osi to wa ni awọn ile-ẹkọ."

Wright, Kristiani kan ati ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican Oklahoman, sọ fun mi pe awọn ile-ẹkọ ni ipinlẹ naa ijọba ko na owo si ile ẹkọ ati pe ọpọ awọn ọmọde agbegbe igberiko ko jẹ ounjẹ to aṣaraloore ni ile.

Ni aarin ogun aṣa yii, Samuel Perry, olukọ ọjọgbọn ni Yunifasiti ti Oklahoma ti kọ ọpọ iwe nipa iṣelu ati ẹsin, gbagbọ pe itọsọna naa jẹ apakan ti ero nla.

‘Ọlọrun lo ran Trump’

Pasitọ Jackson Lahmeyer

Oríṣun àwòrán, Jackson Lahmeyer

Nipa didasilẹ awọn ile ijọsin kekere ni agbegbe awọn talaka, awọn oluso-aguntan ni Belt Bibeli ni ipa pupọ lori awọn onigbagbọ, ati pe ọpọlọpọ ninu wọn ni itọsọna si apakan fun ẹgbẹ oloṣelu Republican.

Ati pe Trump ti di ọkọ ti o dara ọpọ ẹgbẹ yii lati ni ilọsiwaju ni ọdun diẹ sẹyin.

Olusọ aguntan Oklahoman, Jackson Lahmeyer jẹ to fẹran Trump.

Lahmeyer, ẹniti o jẹ oludasile ẹgbẹ Pastors4Trump (Pastors for Trump) sọ pé: “Ọlọrun ran Trump lati ṣe akoso orilẹ-ede yii.

Ero rẹ ni lati “ṣe apejọ ibo ihinrere” lati ṣe atilẹyin Trump ninu eto idibo.

Lahmeyer pe ni “iṣẹyanu atọrunwa kan” pe aarẹ tẹlẹri naa yege igbiyanju ipaniyan to waye ninu ni aarin Oṣu Keje.

“A wa ni igbesẹ kan kuro ni ogun abẹle ni orilẹ-ede wa,” ni oludije fun Igbimọ aṣofin agba tẹlẹ, ninu ibaraẹnisọrọ foonu kan, lati Tulsa, Oklahoma.

Pasitọ Protestant àti oloselu kọ lati ṣapejuwe ararẹ gẹgẹ bii Kristẹni.

"Iyẹn jẹ aami kan ti awọn oniroyin ti fi si wa lati ṣe afihan wa bi irokeke ewu si ijọba tiwantiwa," o sọ. "Kii ṣe otitọ."

Pasitọ Paul Blair

Trump ati iṣẹyun

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn alatilẹyin Trump dupẹ lọwọ rẹ, laarin awọn ohun miiran, fun ipinnu lati yan awọn adajọ ilẹ ẹjọ agba mẹta lasiko ijọba rẹ,ni idaniloju to poju Konsafetifu ninu ẹgbẹ idajọ ti o ga julọ ti orilẹ-ede fun ọpọlọpọ ọdun.

Iṣẹyun jẹ ọkan ninu awọn ọran nla ninu idibo yii, nitori apakan Konsafetifu julọ ti Ẹgbẹ Oloṣelu ijọba Republican fẹ ki wọn fopin si oyun sisẹ, nnkan ti ọpọ n ro pr o le wa si imusẹ ti Trump ba pada si ijọba.

Ajinrere ninu White House?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lakoko iṣakoso rẹ, Trump fowo si aṣẹ alaṣẹ lati ṣẹda ọfiisi ijọba tuntun ti a pe ni Igbagbọ ati Anfani.

“Ìgbagbọ lagbara ju ìjọba lọ, ko si ohun to lagbara ju Ọlọrun lọ,” o sọ nigba to n fọwọ si iwe naa.

Nigba ti Trump padanu idibo ni ọdun 2020, awọn ti a pe ni “awọn oluso-aguntan Patriot” tabi “Maga [Ṣe Amẹrika Nla Lẹẹkansi] pastors” jade lati kede pe wọn ti ji ipo aarẹ lọwọ rẹ. Pupọ darapọ mọ egbe ReAwaken America tuntun ti oniṣowo Oklahoma Clay Clark da silẹ.