'Owó oṣù mi gẹ́gẹ́ bí sọ́jà kò tó iṣẹ́ tí mò n ṣe, 59,500 ni mò n gbà lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá'

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọkan ninu awọn iṣẹ to lagbara ju lati yan laayo ni iṣẹ ologun, iṣẹ ṣọja ki i ṣe fun awọn ọlẹ tabi ọmọ ojo rara.
Idi ni pe iṣẹ ti ẹmi le bọ nibẹ nigbakugba ni, ẹni to ba gba iṣẹ ṣọja ti mọ pe ẹru ko gbọdọ ba oun nibikibi. Bi ogun ba ya, ogun ya ni.
Bi wọn ko ba si fi oju kan mọlẹbi wọn fun ọpọlọpọ oṣu, iyẹn ko di iṣẹ wọn lọwọ, iṣẹ akinkanju ati tawọn alagbara eeyan ni.
Ni Naijiria yii ti eto aabo ko fi gbogbo ara duro ire, awọn ṣọja naa ni akọkọ ninu awọn eleto aabo ti araalu gboju le.
Awọn ni wọn n koju ogun Boko Haram ati tawọn ajinigbe.
Ṣugbọn bi iṣẹ ologun ṣe le to yii, ti ẹmi le bọ lojiji, ti iyawo yoo di opo, ti awọn ọmọ yoo di alaini baba, ti obi ṣọja yoo padanu alẹ, ti sọja funra rẹ ko si ni i ri ere ara rẹ jẹ, njẹ bẹẹ ni ijọba Naijiria n sanwo to to fun awọn ṣọja yii bi?
" 59,500 naira ni mò ń gbà lóṣù ní ipò Corporal tí mo wà, tipátipá ni mo fi ń bọ́ mọ̀lẹ́bí mi’’
Ṣọja kan, Ibrahim,(ki i ṣe orukọ rẹ gan-an), to wa ni ipo Corporal, ṣalaye fun BBC pe tipatipa ni oun fi n bọ mọlẹbi oun.
"Ki n ma parọ fun yin, igbeaye ko dẹrun bayii rara pẹlu ọrọ aje to ti dẹnukọlẹ.
O si yẹ ki awa ṣoja naa ni ọna ta o maa fi ṣe aye wa ba a ṣe n da aabo bo orilẹede wa.
"Ninu nnkan ti a n la kọja yii, owo oṣu ti wọn n san fun wa ko le to eeyan kan lati fi tọju mọlẹbi rẹ."
Ṣọja to n ṣiṣẹ ologun ni Ariwa Iwọ-Oorun Naijiria naa sọ pe, afi ki eeyan wa nnkan mii maa ṣe lẹgbẹẹ, kun iṣẹ to gbe dani gan-an.
Nigba to n ṣalaye owo oṣu to n gba, Corporal Ibrahim sọ pe, "nisinyi ti mo ti wa ni ipo corporal, okun meji ni mo ti gba yẹn. Mo n gba ẹgbẹrun mọkandinlọgọta aati ẹẹdẹgbẹta naira (59,500 naira) loṣu.
"Owo oṣu corporal ni Naijiria wa laaarin 59,300 naira si 60,000 naira," Bẹẹ ni sọja to ti n ṣiṣẹ ologun fọdun mẹwaa naa wi.
O fi kun un pe bi ṣoja ba ṣe n gba okun si lẹnu iṣẹ ni owo oṣu rẹ yoo maa pọ si, bẹẹ ọdun marun lẹyin to wọ iṣẹ ni ṣọja tuntun yoo gba aleekun okun.
Yoo tun gba igbega miran lẹyin ọdun marun-un.
Ki eeyan too le gba corporal, yoo ti ṣisẹ ọdun mẹwaa!
Ṣé ààyè owó àjẹmọ́nú míràn wà fún ṣọ́jà?
Ṣọja Ibrahim ṣalaye pe owo ajẹmọnu kan wa ti wọn maa n fun awọn gẹgẹ bii ṣọja to wa loju ogun.
‘’Ration Cash Allowance abi RCA’’ lo pe orukọ owo naa.
" Iye ọjọ to ba wa ninu oṣu kan ni yoo sọ iye ti wọn maa san fun wa.
To ba jẹ ọgbọnjọ ni, ẹgbẹrun marundinlogoji aabọ (35, 500) ni wọn yoo san.
To ba si jẹ oṣu to de mọkanlelọgbọn, wọn yoo san ẹgbẹrun mẹrindinlogoji aabọ naira (36,500)."
Ṣugbọn bi owo naa ko ba ṣe di ibi kan to, Ibrahim sọ pe ki i ṣe oṣooṣu ni wọn n san an fawọn.
O ni ajẹsilẹ gbese naa maa n wa nilẹ fun ọpọ oṣu, ti wọn ko ni i san an fawọn.
‘’Mi o niyawo, ṣugbọn mo ni awọn obi ati awọn ẹgbọn pẹlu aburo.
Ọpẹlọpẹ pe wọn n fun wa lounjẹ ọfẹ jẹ ni mo fi n le fi owo diẹ diẹ pamọ.
Ẹ ko le fi owo oṣu ṣọja we ti awọn ti wọn wa nile ti wọn n ṣisẹ lọfiisi, igbesi aye ṣọja gba suuru gan-an’’
Àwíjàre iléeṣẹ́ ológun: A máa ṣe àfikún owó oṣù
Agbẹnusọ olu ileeṣẹ ologun Naijiria, Ọgagun Tukur Gusau, ṣalaye fun BBC pe o fẹrẹ ma si ọmọ Naijiria ti ko mọ ohun to n ṣẹlẹ nipa owo oṣu awọn ṣọja orilẹede yii.
Gẹgẹ bo ṣe wi, "otitọ to wa nibẹ ni pe ki i ṣe awọn ṣọja nikan ni ọrọ yii kan, o fẹrẹ jẹ pe ẹnikẹni to ba n gba owo oṣu lasiko yii lo mọ pe igbesi aye ko rọrun rara, owo ko to lati gbọ bukata.
"Ohun ti mo le sọ ni pe ijọba n ṣeto afikun owo oṣu awọn ṣọja ati awọn ẹṣo alaabo yooku," Gusau lo ṣalaye bẹẹ.
O fi kun un pe ki i ṣe ajọ ologun lo n sanwo oṣu awọn ṣọja. O ni ọfiisi apapọ ni.
Fun idi eyi, Gusau sọ pe ireti awọn naa ni pe wọn yoo sẹ afikun owo oṣu naa.
Nipa ti ajẹmọnu RCA ti a gbọ pe gbese rẹ ti pọ nilẹ, Ọgagun Gusau ni oun ko mọ nnkan kan nipa rẹ.
O ni oun mọ pe aarẹ awọn, Ọgagun Christopher Gwabin Musa, n sa ipa rẹ lati ri i pe gbogbo ṣoja to wa loju ogun ri owo yii gba nigba to yẹ.
‘’Bi a ba ṣewadii ti a si ri i pe bẹẹ lo ri, mo fi da yin loju pe a maa yanju rẹ, ko si ni i ṣẹlẹ mọ."
Bẹẹ ni Ọgagun Tukur Gusau, wi.














