Ìgbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ̀rùn tí Ramon Adedoyin pè tako ìdájọ́ ikú rẹ̀ gbọ̀nà míì yọ

Oríṣun àwòrán, Others
Ọna ọtọ ni igbẹjọ kotẹmilọrun ti Ramon Adedoyin pe gba waye niluu Akure lonii.
Adajọ Olufemi Akeju ẹni to lewaju awọn adajọ naa sọ pe ni ibamu pelu ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ naa lati ọwọ awọn agbejọro, awọn dawọ duro lori ẹjọ kotẹmilọrun ọhun fun igba diẹ naa, ti awọn yoo si kede ọjọ ti wọn yoo sẹ idajọ.
Agbejọro fun Dokita Ramon Adedoyin ati awọn agbejọro Adeniyi Aderogba ati Oyetunde Kazeem, awọn oṣiṣẹ rẹ ti wọn jọ dajọ iku fun, rawọ-ẹbẹ si ile-ẹjọ lati fagile idajọ to waye ni ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2023, ni ile-ẹjọ giga nipinlẹ Osun to da ẹjọ pe ki wọn yẹgi fun wọn nitori wọn lọwọ ninu iku arakunrin Timothy Adegoke, akẹkọọ Fasiti OAU to ku si ile itura Hilton to jẹ ti Ramon Adedoyin.
kí ló wáyé ní ilé-ẹjọ́?
Amofin Kehinde Kolawole Eleja agbejọro Ramon Adedoyin sọ pe onibara rẹ ko mọ ohunkohun nipa iku oloogbe naa to si rawọ-ẹbẹ si ile-ẹjọ kotemilọrun lati fagile idajọ iku ti wọn da fun onibaara rẹ.
Kolawole Eleja sọ pe awọn to fẹsun kan Adedoyin pe ẹlẹri mẹjọ nile ẹjọ giga, to si jẹ pe ko si ọkan ninu wọn to darukọ Adedoyin pe o lọwọ ninu iku oloogbe Timothy Adegoke.
O sọ pe Adedoyin yan lati ma pe ẹlẹri lasiko idajọ naa nitori pe awọn ẹlẹri ko darukọ rẹ pe o wa lara awọn to sekupa oloogbe.
Agbajẹro Eleja sọ pe ile-ẹjọ giga samulo ẹri ẹnu afurasi keje to wa lẹnu isẹ lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, ẹni to sọ pe o n ri Ọgbẹni Ramon Adedoyin layika ile itura naa ni asalẹ ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye. ]
Ṣugbọn ẹni afurasi karun-un sọ pe irọ to jina si ootọ ni pe Oloye Adedoyin wa layika ile itura ọhun ni asalẹ ọjọ naa.
Eleja sọpe eyi ṣafihan rẹ pe ko si ẹri to fi idi rẹ mulẹ pe Oloye Adedoyin wa ni ayika ile itura naa ni alẹ ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla ọdun 2021.
Agbejọro naa sọ siwaju si pe, ko si ẹri to ṣafihan rẹ pe Ọgbẹni Adedoyin fi oju ri oloogbe naa tabi foju ri oku rẹ.
O wa rọ ile-ẹjọ Kotẹmilọrun lati fagile gbogbo ẹsun ti wọn fi kan Ramon Adedoyin ati idajọ ile-ẹjọ giga.
Agbejọro ijọba, Femi Falana SAN, ẹni to tako ọrọ agbejọro fun Adedoyin sọ pe bi o ti lẹ jẹ pe Eleja sọ pe Adedoyin nikan lo le sọrọ lootọ boya o wa ni ile itura naa tabi ko si nibẹ lọjọ gan ti iṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn o kuna lati fidi ọrọ naa mulẹ bi ko se ni ẹlẹrii.
Falana sọ pẹ ẹri fi idi rẹ mulẹ pe wọn ri ọkọ ti wọn fi gbe oku Timothy Adegoke lati lọ ju sinu igbo ni ile Ramon Adedoyin n'ilu Abuja, eyi to to tọka si pe o gbiyanju lati bo iku okunrin naa mọlẹ.
O ni Adedoyin ṣe ipade pẹlu awọn osisẹ rẹ lati ma ṣe jẹ ki idajọ ododo o waye bẹẹni o lẹdi apo pọ pẹlu awọn osisẹ rẹ meji lati ṣe iku ọkunrin naa ni bonkẹlẹ.
Falana sọ pe gbogbo ẹri yii ṣafihan rẹ pe Adedoyin jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Amofin agba naa rọ ile-ẹjọ lati ṣamuduro idajọ ile-ẹjọ giga eyi to dajọ iku fun un.
Amofin Oladapo Yusuf, Agbejọro Adeniyi Aderogba to jẹ ọkan lara awọn osisẹ ile itura naa eyi ti wọn dajọ pe ki wọn yẹgi fun oun naa, rawọ ẹbẹ si awon adajọ lati fagile idajọ ọhun.
Ninu ọrọ rẹ agbejọro naa sọ pe ohun to mu ki ile-ẹjọ giga to joko nipinlẹ Osun fi tu awọn afẹsun kan ikejì, ikẹta ati ikeje silẹ - iyẹn Magdalene Chiefuna, Oluwole Lawrence ati Adebayo Kunle; ni pe wọn ko jẹbi ẹsun igbimọ pọ lati ṣ iebi, ko yẹ ki ile-ẹjọ naa dajọ yi yẹgi fun Ọgbeni Adeniyi Aderogba nitori pe ẹṣẹ kan naa ni wọn jọ ṣẹ.
Yusuf sọ siwaju si pe gbogbo wọn ni wọn fi ẹsun kan to si jẹ pe ẹni afẹsun kan keje ti ile-ẹjọ tu silẹ pe ko ma lọ ni alaafia, lo wa ni ẹnu isẹ lọjọ gan-an ti iṣẹlẹ naa waye, to si jẹ pe ẹsẹ kan ati ẹri kan naa lo wa niwaju ile-ẹjọ tako gbogbo wọn, idi rẹ niyii ti ile-ẹjọ kotemilọrun fi gbọdọ fagile idajọ ile-ẹjọ giga.
O sọpe pe adajọ to da ẹjọ naa ko tẹle awọn ilana to tọ to si ra ọwọ ẹbẹ si awọn adajọ lati fagile idajọ naa.
Ninu ọrọ rẹ agbejọro fun ijọba, Femi Falana sọ pe gbogbo ọrọ ti akẹgbẹ rẹ sọ ni ko fẹsẹmule rara lori ẹjọ naa.
O sọpe awọn ti ile-ẹjọ tu silẹ ni wọn ko kopa ninu iditẹ lati ṣekupa oloogbe naa sugbọn Adeniyi Aderogba to jẹ ọkan lara awọn osisẹ ile itura naa ko ipa pataki ninu iku oloogbe naa.
Falana sọ pe Adeniyi Aderogba fi ẹnu ara rẹ jẹwọ pe ohun kopa ninu igbiyanju lati bo ẹjọ naa mọlẹ ni ibamu pẹlu ẹri to kọ nileeṣẹ ọlọpaa.
O sọ pe Adeniyi lo fi ẹnu ara rẹ jẹwọ pe ohun lo ko awọn aṣọ to wa lori ibusun ti oloogbe naa sun si ti o si dana sun-un, bẹẹni o kopa lati ju oku ọkunrin naa sinu igbo.
Femi Falana sọ pe pẹlu awọn ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ, Ọgbẹni Adeniyi Aderogba jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan.
O wa a rọ ile-ẹjọ lati ma yi i idajọ ile-ẹjọ giga to ni ki wọn yẹgi fun un, pada.
Onidajọ ti wa a sọ pe oun yoo kede ọjọ ti idajọ yoo waye fun awọn agbẹjọro.












