Ọwọ́ tẹ ọlọ́pàá tó yìnbọn pa gbajúmọ̀ olórín, Igbo-Jah lójú agbo

Oríṣun àwòrán, Enugu Police Command
Ọlọpaa tí wọn gba aṣọ lara rẹ, Joseph Ozonwanji ni ile ẹjọ ti ni ki o maa gba atẹgun lọgba ẹwọn fun isekupani gbajumọ olorin Ogene, Okezie Nwamba, ẹni ti ọpọ mọ si Igbo -Jah.
Ozonwanji foju ba ile ẹjọ ni ọjọ Aje, Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 2024 niwaju Onidajọ Ngozi Edeani.
Saaju ni ileeṣẹ Ọlọpaa igbakeji Ọga Ọlọpaa, Godwin Aghalor buwọlu iyọnisẹ Ozonwanji lẹyin iṣẹlẹ naa.
Ileeṣẹ Ọlọpaa fẹsun kan Ozonwanji pe ṣekupa Nwamba pẹlu AK47 ni ọna ti ko ba ofin mu.
Ile ẹjọ sọ pe Ozonwanji Joseph, ni ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa, nipinlẹ Enugu ṣekúpa ọkùnrin kan Okezie Chikezie Nwamba pẹlu ìbọn AK 47
Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Enugu, Daniel Ndukwe ni bi awọn ṣe gbe afurasi naa wa si ile ẹjọ da lori ileri ileeṣẹ Ọlọpaa ati ijọba ipinlẹ Enugu lati ri pe idajọ òdodo waye lori iṣẹlẹ naa.
"O ṣe koko pe ki a fi to awọn eeyan leti pe ile ẹjọ ti gbọ ẹjọ ti a gbe wa si iwaju rẹ lori ọlọpaa ti a ti gba aṣọ lọrun rẹ, ti ile ẹjọ si ni ka a gbe e lọ sí iwaju agbẹjọro agba fun ipinlẹ Enugu.
"Eyi ni igbẹjọ kan ti a fẹ ko waye nitori ẹmi eeyan ni a n sọrọ nipa rẹ. Ojúṣe Ọlọpaa ni lati da abo bo awọn araalu sugbọn ti Ọlọpaa ba si agbara lo, gẹgẹ bii nnkan to waye nípinlẹ Enugu.
"Ẹ yoo ri pe ileeṣẹ Ọlọpaa ati Ìjọba ìpinlẹ Enugu n sisẹ papọ lati ri pe idajọ ododo waye
Ki lo sẹlẹ saaju?
Ni ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa, ni Ozonwanji to jẹ oṣiṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Enugu yinbọn lu gbajumọ olorin Ogene Okezie Chikezie Nwamba, ẹni ti ọpọ mọ si 'Igbo Jah.
Ọpọ awọn araalu lo tu sita lati ṣe ifehonuhan lori iṣẹlẹ naa ti wọn si n pe idajọ ododo.
Osojumikoro to gbe aworan oku Igbo Jah si ori ayelujara salaye pe ọlọpaa naa ṣekupa nigba to n kọrin lọwọ nibi ayẹyẹ kan, ti o si ni oun ko mọọmọ.















