Àwọn èèyàn ń kú, ọ̀pọ̀ di onígbèsè nítorí àìsí iná fún ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ọjọ́ ní Àríwá Naijiria

Aworan awọn eeyan nitosi opo agbara ina mọnamọna.

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

O ti pe ọjọ mẹsan-an bayii ti ina mọnamọna ko ti si ni ọpọ ipinlẹ lapa Ariwa Naijiria.

Awọn eeyan Kano, Katisna, Plateau, Kaduna ati awọn miran si ti bẹrẹ si i kede òfò to ti ṣe wọn lẹka ọrọ aje, latari ina ti ko si ọhun.

Awọn ti wọn n ta ẹja inu yinyin, ẹran, adiẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn n ke gbajare lori ayelujara bayii, wọn ni owo ti wọgbo.

Ọkan lara awọn eeyan naa ni Malam Abubakar Auwal, ẹni to n ta ẹran ni Kano.

Baba naa sọ fun BBC pe, ’’a pọ ti nnkan ti ṣe nitori ai si ina yii, emi gẹgẹ bii ẹnikan, niṣe lo n sẹ mi bii ki n sa lọ pẹlu gbese ti mo ti jẹ nitori ina ti ko si.

Awọn ẹran to ti bajẹ mọ mi lọwọ ti ko mi si gbese.’’

Bakan naa ni obinrin olounjẹ kan, Masrura Idris Abubkar, lati ipinlẹ Pleateau, ṣalaye pe gbogbo eelo ounjẹ ti oun ra sinu ẹrọ firiiji lo ti bajẹ tan.

O ni ko si ọna miran ju koun da gbogbo ẹ nu lọ.

Ọpọlọpọ ẹja, ẹran, adiẹ, ata, eso ati bẹẹ bẹẹ lọ ni awọn eeyan ti padanu laarin asiko ti ina mọnamọna ko si yii.

Eyi ni wọn lo ti ṣakoba fun ọrọ aje awọn eeyan naa.

Bi aisi ina ọhun ṣe kan awọn olokoowo lo kan awọn idile kaakiri pẹlu, wọn n tara pe omi ko si bi ina ko ṣe si.

Awọn idile mi-in n sọ pe gbogbo owo lawọn ti fi ra epo si jẹnẹretọ, bẹẹ lawọn ti ko ni ẹrọ amunawa naa gba kadara sinu okunkun birimu.

Kí ló fà á tí iná ọba fi lọ bẹ́ẹ̀?

Aworan awọn oṣiṣẹ mọnamọna nibi opo agbara.

Oríṣun àwòrán, TCN

Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹgbẹ kan lapa Ariwa ti n sọ pe awọn kan ti wọn fẹẹ ko ba ọrọ aje awọn lo wa nidii ọrọ yii, ajọ apinnaka TCN ṣalaye ọrọ.

Ali Abubakar to n ri si ibaṣẹpọ okoowo TCN, ṣalaye fun BBC pe ai si ina yii ko ṣẹyin awọn opo meji ti wọn ni agbara 330kV, ti wọn wa ni Ugwaji-Apir.

O ni awọn oju opo meji yii wa laaarin ilu Shiororo ati Kaduna.

Awọn opo meji naa ni wọn n pin ina de Kano, Katsina, Jigawa, Kaduna, Bauchi ati Gombe pẹlu awọn ipinlẹ mi-in lapaa Ariwa Ila-Oorun ati Aarin gbungbun Ariwa.

’’ Yatọ si eyi, a fura pe awọn agbesunmọmi ti ri ado oloro mọ apa ibi kan lara ọkan ninu awọn opo agbara to n muna wa naa.

’’Ki eyi si too ṣẹlẹ ni oju opo Benue si Jos ti bajẹ’’

Ali Abubakar lo ṣalaye bẹẹ.

Ònà àbáyọ

Gẹgẹ bi awọn akọṣẹmọṣẹ nipa iṣoro ina mọnamọna ati awọn oṣiṣẹ ọba lẹka naa ṣe sọ fun BBC, ọna kan ṣoṣo naa lo wa ti Ariwa ko fi ni i koju iṣoro yii mọ.

Onimọ-ẹrọ Sani Bala, akọṣẹmọṣẹ to tun jẹ aṣoju nile igbimọ aṣoju-ṣofin, ati Ali Abubakar lati TCN, ṣalaye pe ijọba gbọdọ pese ibudo agbara ina mọmamọna to to.

Eyi ti yoo ni agbara to pọ lati tan iṣoro awọn ileeṣẹ nla nla ti wọn nilo ina.

Yoo wulo fun awọn araalu naa ti wọn fi n ṣe okoowo, ati awọn eeyan to n lo ina ọba fun lilo ninu ile lasan.