Èyí ni ẹnití ó ṣe é ṣe kí Manchester United gbà rọ́pò Ten Hag

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ta ni yoo rọpo Eric Ten Hag ti ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ṣẹṣẹ gba iṣẹ lọwọ rẹ lọjọ Aje gẹgẹ bi akọnimọọgba ikọ naa bayii?
Ibeere nla to gba ẹnu awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa jakejado agbaye niyi lẹyin ti iroyin lu sita lowurọ ọjọ Aje pe iṣẹ rẹ ti dopin ni ẹgbẹ agbabọọlu naa.
Bi o tilẹ jẹ wi pe iroyin igbesẹ naa ko ya ọpọ lẹnu paapaa julọ pẹlu awọn esi ti ikọ ẹgbẹ agbabọọlu naa n mu jade lori papa lati igba ti saa ere bọọlu 2024/25 bẹrẹ ni oṣu kẹjọ.
Goolu meji si ẹyọ kan ni ikọ WestHam fi ṣ’agba wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye ni ọjọ Aiku eleyi ti o ti wa fi wọn si ipo kẹrinla lori atẹ igbelewọn liigi ilẹ Gẹẹsi to n lọ lọwọ.
Ni oṣu diẹ sẹyin ni Ten Hag tọwọ bọ iwe adehun tuntun, amọ igbesẹ awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa ti fa iwe adehun naa ya bayii lẹyin ọdun meji abọ to lo nibẹ.
Nibayii, gbọyisọyi ọrọ ti n lọ kiri nipa akọnimọọgba to ṣeeṣe ko bọ si ipo naa.
Lara awọn ti wọn n na ika si bayii niwọnyii:
Ruud van Nistelrooy

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbabọọlu Manchester United nigbakan ri ni Ruud van Nistelrooy. Ni opin saa bọọlu to kọja ni wọn si gba a gẹgẹ bi i amugbalẹgbẹ fun Ten Hag lẹyin ti awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa ṣe ayipada fun ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ ikọ agbabọọlu naa.
Oun si ni wọn yan pe ko duro ni ipo naa bayii titi di igba ti wọn yoo fi yan ẹni ti yoo di ipo naa mu ni san an.
Ki o to gba iṣẹ Manchester United yii, o ṣe akọnimọọgba fun ẹgbẹ agbabọọlu PSV Eindhoven ni saa 2022/23, ki o to kuro lẹyin to gba ife ẹyẹ Dutch Cup ni saa akọkọ to lo nibẹ.
Bakan naa lo fi igba meji ṣe amugbalẹgbẹ fun akọnimọọgba ikọ agbabọọlu orilẹede Netherlands.
Graham Potter

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea gba iṣẹ lọwọ rẹ ni oṣu kẹrin ọdun 2023, ọpọ lo wo o pe ko le pẹ pupọ ki akọnimọọgba naa to iṣẹ miran. Amọṣa, ọdun kan abọ ree lẹyin rẹ, Potter ko tii ri iṣẹ o.
Ṣaaju ki o to gba iṣẹ ni Che;sea, Graham Potter ti ṣe akọnimọọgba fun ẹgbẹ agbabọọlu Brighton.
Gareth Southgate

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ọdun mẹjọ gẹgẹ bi akọnimọọgba ikọ agbabọọlu orilẹede England, ninu eyi to ti gbe ikọ naa de ipele aṣekagba idije ife ẹyẹ ilẹ Yuroopu, European Championship, lẹẹmeji ọtọọtọ, Gareth Southgate tun ti wa lọja lẹẹkan sii.
Ọdun mẹta to lo gẹgẹ bi akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Middlebrough laarin ọdun 2006 si 2009 nikan ni iriri to ni pẹlu iṣẹ akọnimọọgba pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu.
Iroyin kan pupọ ni opin saa ere bọọlu to kọja pe Manchester United pẹlu Southgate jọ n sọ ajọsọ ọrọ lati le gba a gẹgẹ bi akọnimọọgba nigba naa ki o to tun di pe wọn fun Ten Hag lanfani adehun tuntun.
Thomas Frank
Akọnimọọgba, ọmọ orilẹede Denmark yii jẹ ọkan lara awọn eekan akọnimọọgba ti ọpọ onwoye n gboriyin fun pe wọn to gbangba sun lọyẹ lagbo awọn akọnimọọgba ere bọọlu lagbaye.
Ohun to n mu ki ọpọ kan sara sii naa ni ipa ribiribi to ti ko ninu idagbasoke ere bọọlu ikọ Brendtford ni idije liigi Premiership ilẹ Gẹẹsi.
Gẹgẹ bi ohun ti ọpọ n sọ bayii, ara rẹ ni oju ọpọ awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United wa , amọ gẹgẹ bi ọpọ onwoye ṣe n wo o pe ọbẹ to dun owo lo pa a lọrọ rẹ yoo jẹ bi wọn ba fẹ ki ẹgbẹ agbabọọlu Brendtford jọwọ rẹ fun wọn, o ṣeeṣe ki awọn alaṣẹ Man Utd tun ero wọn pa lori rẹ.
Zinedine Zidane
Lati igba ti Zidane ti fi iṣẹ Real Madrid silẹ lọdun 2021, ko tii gba iṣẹ miiran.
Nigba ti Solskjaer fi ipo akọnimọọgba Manchester United silẹ lọdun 2021 ni wn kọkọ kọ ẹnu si i gẹgẹ bi BBC ṣe gbe sita nigba naa.
Zidane ko ṣe akọnimọọgba ik miran ju Madrid lọ, amọ ipa to fi lelẹ nibẹ ko jẹ ki gbogbo agbaye ko iyan rẹ kere rara lawujọ awọn akọnimọọgba lagbaye.
Ife ẹyẹ Champions League mẹta ọtọọtọ ni ṣisẹ-n-tẹle lo tọ Madrid gba, igba akọkọ si niyi ti akọnimọọgba kankan yoo ṣe eyi.
O fi ẹgbẹ naa silẹ ki o to tun pada wa, leyi to fi wa gba ife ẹyẹ liigi orilẹede Spain.
Kieran McKenna

Oríṣun àwòrán, Getty Images
McKenna kii ṣe ajejei si Manchester United nitori pe o ti fi igbakan ri wa lara awọn oṣiṣẹ ikọ naa laarin ọdun 2016 si 2021.
Bakan naa lo dẹ tun ṣe bẹbẹ gẹgẹbi akọnimọọgba ikọ Ipswich, nipa gbigbe wọn kuro lati idije onipokẹta nilẹ gẹẹsi iyẹn League One wa si Premier League laarin ọdun meji abọ.
Ni opin saa to kọja yii, awọn eekan ẹgbẹ agbabọọlu bii Brighton, Manchester United ati Chelsea ni wọn dinju sii fun ipo akọnimọọgba wọn.
Amọṣa o tọwọ bọ iwe adehun ọlọdun mẹrin tuntun pẹlu Ipswich, yoo si na Manchester United lowo gọbọi ti wọn ba fẹ gba a lọwọ Ipswich bayii.
Xavi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Xavi jẹ ogbontagi agbabọọlu ki o to fẹyinti di akọnimọọgba. O jẹ ọkan pataki laarin ikọ Barcelona ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Spain to mi gbogbo agbaye titi lori papa laarin ọdun 2008 si 2012
Xavi gba ife ẹyẹ liigi ilẹ Gẹẹsi, Laliga laarin ọdun meji abọ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Barceloan ki wọn to gba iṣẹ lọwọ rẹ.
Bi o tilẹ jẹ wi pe lawọn asiko kan sẹyinlawọn iroyin kan ti n jade pe awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti n kun si Xavi leti. O daju pe yoo ṣoro fun un lati kọ ọ bi Manchester United ba pe e si iṣẹ akọnimọọgba rẹ.
Edin Terzic
Edin Terzic lo ṣe atọna ẹgbẹ agbabọọlu Borussia Dortmund lọ si ipele aṣekagba ife ẹyẹ Champions League ilẹ Yuroopu ni saa 2023/24 to kọja ki o to fi ẹgbẹ agbabaọọlu naa silẹ loṣu kẹfa.
Dortmunrd naa lo ti bẹrẹ iṣẹ akọnimọọgba rẹ laarin ọdun 2010 si 2013 ki o to di amugbalẹgbẹ fun Slaven Bilic ni ẹgbẹ agbabọọlu Bekistas lorilẹede Turkey.
Bakan naa lo tn tẹle Bilic lọ WestHam ni ọdun 2015 ki o to fi ibẹ silẹ nigba ti wọn gba iṣẹ lọwọ Bilic ni oṣu kọkọanla ọdun 2017.
Lẹyin ọdun lo pada si Dortmund gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ fun Lucien Favre.
Ruben Amorim
Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool lawọn eeyan kọkọ kẹẹfin pe o n ṣe woyiwoyi pẹlu Amorim ki wọn to yan Arne Slot.
Amorim ni akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu. Oun lo si tọ wọn lọ gba ife ẹyẹ liigi orilẹede Portugal lẹyin ọdun mọkandinlogun lọdun 2021, ki o to tun gba ife ẹyẹ naa fun igba keji ni saa to kọja.
Ni ọdun 2018 ni Amorim fẹyinti gẹgẹ bi agbabọọlu lẹyin to gba bọọlu fun ikọ Benfica ati orilẹede Portugal ki o to di akọnimọọgba lẹyin ọdun kan si asiko naa.
Adehun ṣi n bẹ laarin Amorim ati Sportin gẹgẹ bi akọnimọọgba wọn titi di ọdun 2026.
Simone Inzaghi
Ẹgbẹ agbabọọlu Inter Milan ni Inzaghi n ba ṣiṣẹ lọwọlọwọ bayii, o si ti pẹ ti wọn ti n foju si i lara pe o ṣeeṣe ko jẹ pe oun ni iṣẹ akọnimọọgba manchester United kan ni kopẹkopẹ.
Inzaghi ni igi lẹyin ọgba fun bi Inter Milan ṣe gba ife ẹyẹ liigi orilẹede Italy ni saa to kọja, ti o si tun gba ife ẹyẹ Coppa Italia lẹẹmeji ọtọọtọ.
O tun gbe ikọ naa de ipele aṣekagba idije ife ẹyẹ Champions League ilẹ Yuroopu ni saa 2022/23, nibi ti wọn ti padanu ife naa fun Manchester City.
Bakan naa lo tun gba ife ẹyẹ Coppa Italia nigba to n ṣe akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Lazio.
Amọṣa, Laipẹ yii lo tọwọ bọ iwe adehun tuntun pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Inter Milan.
Ta ni Ruud van Nistelrooy tí Man United fi rọ́pò Ten Hag?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 1976 ni wọn bi van Nistelrooij lorilẹede Netherlands.
Van Nistelrooy jẹ ọkan lara awọn agbabọọlu to dangajia julọ lasiko to n gba bọọlu.
O gba ami ẹyẹ ẹni to sọ bọọlu sawọn ju ninu idije UEFA Champions League fun saa mẹta ọtọtọ.
Oun kan naa yii ni ẹni ikẹfa to sọ bọọlu sawọn julọ ninu itan idije naa lagbaye.
Lọdun 2004, ajọ FIFA kede rẹ gẹgẹ bii ọkan lara eeyan ọgọrun un agbabọọlu to lamilaaka julọ ninu itan to ṣi wa laaye.
Ẹgbẹ agbabọọlu Den Bosch lo ti bẹrẹ bọọlu gbigba ko to lọ si Heerenveen, PSV Eindhoven atawọn ẹgbẹ agbabọọlu miran.
O gba bọọlu kaakiri ko to darapọ mọ Man United laarin ọdun 2001 si 2006 nibi to ti sọ bọọlu sawọn lọpọ igba.
Lọdun 2012 lo fẹyinti gẹgẹ bii agbagbọọlu lori papa.
Laarin ọdun 2022 si 2023, o ṣiṣẹ akọnimọọgba fun ikọ PSV ko to darapọ mọ United gẹgẹ bii igbakeji akọnimọọgba.















