Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Arsenal, Chelsea àti Man U ní líìgì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lópin ọ̀sẹ̀

Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàárín Arsenal àti Liverpool

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Níṣe ni ara àwọn olọlùfẹ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal ń bú mọ aṣọ lónìí bí wọn kò ṣe jáwé olúborí ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Liverpool.

Gbogbo ìgbìyànjú Arsenal ni láti bórí ìdíjé náà àmọ́ ọ̀mì ni ó bá dé fún wọn.

Ní báyìí, ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester City ló wà lókè tábìlì líìgì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lẹ́yìn àwọn ìfẹwọ̀nsẹ̀ tó wáyé lópin ọ̀sẹ̀ yìí.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal àti Liverpool ṣe gba ọmi ayo méjì méjì níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn tó wáyé lọ́jọ́ Àìkú.

Arsenal ló wà ní ipò Kéta báyìí nígbà ti Aston Villa ti gba ipò Kẹrin mọ́ Chelsea lọ́wọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbo ewúro sójú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Newcastle pẹ̀lú góòlù méjì sí ẹyọ̀kan.

Ipò karùn-ún ni Chelsea wà báyìí lórí tábìlì líìgì náà.

Ipò Kẹrìnlá ni Manchester United wà báyìí lẹ́yìn tí Westham United fi góòlù méjì gbo ewúro sójú wọn.

Àwòrán tábìlì líìgì ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì

Oríṣun àwòrán, Others