Man United gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Ten Hag

Erik Ten Hag

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti da olukọni wọn, Erik Ten Hag duro.

Man United gbe igbesẹ yii lẹyin ti Ten Hag ti tukọ ẹgbẹ agbabọolu naa fun ọdun meji abọ.

Ifẹsẹwọnsẹ ti Ten Hag ṣakoso rẹ kẹyin ni eyii ti ikọ naa gba pẹlu West Ham lana ọjọ Aiku, nibi ti wọn ti lulẹ.

Ami ayo meji si ọkan ni West Ham fi da seria fun wọn.

Ni bayii, ipo kẹrinla ni Man United wa lori tabili Premier League lẹyin ti wọn bori mẹta pere ninu ifẹwọnsẹ mẹsan an ti wọn ti kopa.

Ninu tabili Europa League, ipo ipo kọkanlelogun ni Man United wa ninu ikọ mẹrindinlogoji to n kopa ninu idije naa, iyẹn lẹyin ti wọn gba ọmi ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta akọkọ.

Awọn alaṣẹ ikọ naa ti kede Ruud van Nistelrooy, to jẹ igbakeji Ten Hag gẹgẹ bii ẹni ti yoo si maa tukọ ẹgbẹ agbabọọlu naa bayii.

Aarọ oni ọjọ ni Man United fi awọn ikede naa sita, to jẹ lẹyin wakati diẹ ti West Ham gbo ewuro soju wọn niluu London lọjọ Aiku.