‘France ni wọ́n ti bí wa, àmọ́ à ń wá ọjọ́ ọ̀la wa ní Africa’
- Author, Nour Abida, Nathalie Jimenez & Courtney Bembridge
- Role, BBC Africa Eye
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Orilẹ-ede France ni wọn ti bi Menka Gomis, ṣugbọn Senegal nibi ti wọn ti bi awọn obi rẹ, ni ọjọ ọ̀la rẹ wa.
Ẹni ọdun mọkandinlogoji naa wa lara awọn ọmọ Africa to tun jẹ ọmọ France, to n fi orilẹ-ede naa silẹ, nitori idẹyẹsi ati ẹlẹyamẹya ti wọn n doju kọ nitori awọ wọn.
BBC Africa Eye ṣe iwadii igbesẹ yii – eyi ti wọn n pe ni ‘silent exodus’, to tumọ si bi ọgọọrọ eeyan ṣe n fi ilu silẹ lai pariwo nipa rẹ.
Ninu iwadii naa ni BBC ti mọ idi ti igbe aye ni France fi su awọn eeyan bii Ọgbẹmi Gomis.
Ọmọ ilu Paris ọhun ti da ileeọ̀ẹ kan silẹ, lati maa ba awọn eeyan ṣe eto irinna paapaa si Africa, pẹlu afojusun lati ran wọn lọwọ lori mi mọ orirun wọn.
Senegal ni ọfiisi ileeṣẹ naa wa.
Ọmọ ọwọ ni Gomis wa nigba ti iya rẹ bẹrẹ si i gbe ni France.
O ni lootọ ni oun jẹ ọmọ orilẹ-ede naa, amọ oun ni orirun.
“Africa ni ọjọ iwaju, nibi ti idagbasoke ku si.”
Ohun to kọju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomiran. Bi awọn eeyan kan ṣe n pada si Africa, ni awọn ẹlomii ṣetan lati ṣe gbogbo nnkan, koda fi ẹmi wọn wewu lori okun ki wọn le de ilẹ Yuroopu.
Pupọ ninu wọn lo n gunlẹ si France.
Ni ọdun to kja nikan, 142, 500 eeyan lo kọwe beere fun gbigbe orilẹ-ede naa, gẹgẹ bi ileeṣẹ ọrọ abẹle ṣe sọ.
Ida kan ninu mẹta ni awọn ti wọn fun ni iwe.
A ko le sọ iye awọn to ti pinnu lati pada si Africa, nitori pe ofin France tako ṣiṣe akojọpọ akọsilẹ niap ẹya, ẹsin tabi awọ.
Ṣugbọn iwadii fihan pe awọn ọmọ orilẹ-ede France, to wa lati idile musulumi, paapaa julọ awọn ọmọ awọn aṣatipo nibẹ, n pada sile ni idakọnkọ.
Awọn ti a ba sọrọ, sọ fun wa pe iha ti ilu kọ si awọn to jẹ atipo ti n lagbara si ni France, paapaa bi ẹgbẹ alatako ṣe n gbilẹ si.
Lati oṣu to kọja ti wọn ti yan wọn sipo, olootu ijọba, Michel Barnier ati minisita fun ọrọ ablẹle, Bruno Retailleau, jẹjẹẹ lati mu adinku ba awọn to n wọle si orilẹ-ede naa ni ilana to tọ ati awọn to n wọle lọna to tako ofin.
Wọn ni awọn yoo ṣe eyi nipa mimu ayipada ba ofin to rọ mọ, ni abẹle ati ni ilẹ Yuroopu.

Oríṣun àwòrán, AFP
Fanta Guirassy ti gbe ni France lati igba ti wọn ti bii, o si jẹ nọọsi niluu Villemomble. Amọ oun naa n ṣeto lati pada si Senegal, ile abinibi iya rẹ.
Ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn hun sọ fun BBC pe fun ọdun diẹ bayii lo ti di pe ipaya wa fun awọn.
Gẹgẹ bi iya, to ni ọmọ ọdun mẹẹdogun, o tumọ si pe gbogbo igba ni ẹru n ba ọ.”
Erongba lati pada sile bẹrẹ nigba ti awọn ọlọpaa deedee da ọmọ rẹ duro ni oju ọna, ti wọn si ṣe ayẹwo ara rẹ lasiko to n ba ọrẹ rẹ sọrọ.
“Ipaya nla ni eyi jẹ fun mi gẹgẹ bi abiyamọ.”
Ninu oṣu Kẹfa, ọdun to kọja, iwọde ati ifẹhonu han waye ni France lẹyin ti awọn ọlọpaa yinbọn pa ọmọkunrin ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan, Nahel Merzouk - ọmọ orilẹ-ede France ati Algeria.
Iwadii ṣi n lọ lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn awọn iwọde ọhun jẹ afihan ibinu ati ikanra to ti wa fun ọdun pupọ nipa idẹyẹsi awọn ẹya kekeeke n koju ni France.
Iwadii kan laipẹ yii laarin awọn alawọdudu ni France fihan pe 91% awọn to kopa, lo ti ni iriri ẹlẹyamẹya.
Lasiko iwọde naa, ajọ UN ke si France lati wa nnkan ṣe si iwa ẹlẹyamẹya laarin awọn oṣiṣẹ alaabo rẹ, amọ ileeṣẹ ilẹ okeere orilẹ-ede naa sọ pe ko si nnkan to jọ eyi.
Amọ ṣa, gẹgẹ bi akọsilẹ ileeọ̀ẹ naa, o le ni 15,000 iṣẹlẹ idẹyẹsi nipa ẹsin, ẹya ati awọ, to waye lọdun to kọja.
Ni ti Audrey Monzemba, to jẹ olukọ, to si wa lati Congo, o ni ipaya ni iru awọn ayipada to n waye yii jẹ.
Ninu irinajo wa pẹlu rẹ, a kiyesi pe bo ṣe ku diẹ ko wọ ile ẹkọ to ti n ṣiṣẹ, o rra fi ọgbọn yọ hijab to fi bo ori.
Ni France, awuyewuye ni hijab lilo n fa, ogun ọdun sẹyin si ni wọn ti fi ofin de lilo rẹ ni awọn ile ẹkọ to jẹ ti ijọba – eyi si jẹ ara idi ti Arabinrin Monzemba ṣe fẹ kuro ni France, to si n wa ọna lati pada si Senegal nibi to mọ eeyan si.
Ẹni ọdun marundinlọgbọn naa sọ pe “kii ṣe pe France ko dara fun mi, amọ mo n fẹ awujọ to bọwọ fun ẹsin ati igbeaye mi”.
Iwadii kan laipẹ laarin awọn Musulumi to le ni 1,000 ni Frnace fihan pe tuntun kọ ni eyi.
O si n waye lẹyin ti idẹyẹsi awọn musulumi bẹrẹ ni ọdun 2015 ti awọn agbebọn kan to jẹ ẹlẹsin Islam yinbọn pa 130 eeyan kaakiri ilu Paris.

Ni ti Fatoumata Sylla, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, ti awọn obi rẹ wa lati Senegal, o ni oun n pada si Senegal loṣu to n bọ.
Erongba rẹ ni lati da okoowo silẹ ni Iwọ oorun Africa, ‘lati fihan pe ko gbagbe orirun rẹ’.
Amọ ọrọ ko ri bẹẹ fun aburo rẹ kunrin, Abdoul.
“Emi o ni erongba lati pada si orirun kankan. Ibi ni ẹbi ati igbeaye mi wa.
“Lootọ ni Africa jẹ orirun awọn baba nla wa, amọ kii ṣe ti wa nitori pe ao si nibẹ.”
Ẹlomiran, Salamata Konte, ẹni ọdun marundinlọgbọn to fi iṣẹ silẹ ni banki, to si pada si Senegal, sọpe awọn eeyan kọkọ dẹyẹ si oun nigba ti oun pada sile lọdun mẹta sẹyin.
“Amọ mo ba ara mi sọrọ pe, ti o ba fẹ wa sibi, o gbọdọ ni irẹlẹ. Nnkan ti mo si ṣe niyẹn.”
O ni gẹgẹ bi oniṣowo l’obinrin, awọn ọkunrin Senegal ko tete tẹwọ gbaa nitori igbagbọ pe obinrin ko le jẹ Ọga Agba ileeṣẹ - pe obinrin le paṣẹ fun awọn eeyan kan . Fun apẹẹrẹ, pe boya mo ba awakọ mi wi pe o pẹ de ibi iṣẹ.
Oun ati Ọgbẹni Gomsi lo jọ da ileeṣẹ abani ṣeto irinajo naa silẹ.
Gomsi sọ pe ileeṣẹ naa n sẹ daadaa, ti oun si tun ti n ‘se eto lati sẹ ‘app’ kan fun awọn to n wa ololufẹ.













