Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Àkójọpọ̀ ìròyìn káàkiri Nàìjíríà
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Ija agba meji nilẹ Yoruba ree o

Ṣe ti Aarẹ Ọna Kakanfo, Iba Gani Adams to wọ ajafẹtọọ idasilẹ Yoruba Nation, Sunday Igboho lọ sile ẹjọ

Bẹẹ ni o, lori ẹsun pe o gbe fọnran ohun oun jade lai gbaṣẹ to si n beere fun biliọnu marun-un naira lọwọ Sunday Igboho

Ṣe wọn n ja tẹlẹ ni?

Ṣaaju ni Sunday Igboho ti gbe Gani Adams lọ sile ẹjọ ninu oṣu kẹrin fẹsun ibanilorukọ jẹ

Ijọba ipinlẹ Ogun ti ni ki olukọ to na akẹkọọ ti ẹmi fi bọ lọrun rẹ, Azamdjo Elijah lọ rọkun nile

Agbẹnusọ gomina ipinlẹ Ogun, Lekan Adeniran ni ijọba ti ranṣẹ pe ọga ile ẹkọ girama ti iṣẹlẹ naa ti waye lati wa wi tẹnu rẹ

Lori bi wọn ṣe huwa lodi si ofin ti ijọba fi lelẹ lori biba akẹkọọ wi

Lọjọ Ẹti ni iroyin jade pe Monday Ariyo jade laye lẹyin ti olukọ rẹ na an lẹgba lori ọrọ ike ikolẹ

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti fọwọ osi juwe ile fun akọnimọọgba wọn, Erik Ten Hag

Ti wọn si ni ki Ruud Van Nistelrooy ba dele ti wọn yoo fi yan akọnimọọgba mii

Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́